Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 6:1-21

6  Àpótí+ Jèhófà sì wà ní pápá àwọn Filísínì fún oṣù méje.  Àwọn Filísínì sì bẹ̀rẹ̀ sí pe àwọn àlùfáà àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́+ pé: “Kí ni kí a ṣe sí àpótí Jèhófà? Ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí àwa yóò fi rán an lọ sí àyè rẹ̀.”  Wọ́n fèsì pé: “Bí ẹ bá máa fi àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì ránṣẹ́, ẹ má fi í ránṣẹ́ láìsí ọrẹ ẹbọ, nítorí ẹ gbọ́dọ̀ dá ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ padà fún un lọ́nàkọnà. Lẹ́yìn náà ni a óò mú yín lára dá, ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi yí padà kúrò lọ́dọ̀ yín yóò sì di mímọ̀ fún yín.”  Látàrí èyí, wọ́n wí pé: “Kí ni ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi tí ó yẹ kí a dá padà fún un?” Nígbà náà ni wọ́n wí pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú iye àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀+ àwọn Filísínì, jẹ̀díjẹ̀dí wúrà márùn-ún, àti eku àgó wúrà márùn-ún, nítorí olúkúlùkù yín àti àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ yín ní òjòjò àrànkálẹ̀ kan náà.  Kí ẹ sì ṣe àwọn ère jẹ̀díjẹ̀dí yín àti àwọn ère eku àgó+ yín tí ń run ilẹ̀ náà, kí ẹ sì fi ògo+ fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Bóyá òun yóò mú ọwọ́ rẹ̀ fúyẹ́ lára ẹ̀yin àti ọlọ́run yín àti ilẹ̀ yín.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, èé ṣe tí ẹ̀yin yóò ṣe mú ọkàn-àyà yín gíràn-án gan-an gẹ́gẹ́ bí Íjíbítì àti Fáráò ṣe mú ọkàn-àyà wọn gíràn-án?+ Kì í ha ṣe gbàrà tí Ó bá wọn lò lọ́nà mímúná+ ni wọ́n tẹ̀ síwájú láti rán wọn lọ, tí wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ?+  Wàyí o, ẹ mú, kí ẹ sì ṣe kẹ̀kẹ́ tuntun,+ àti abo màlúù méjì tí ń fọ́mọ lọ́mú, èyí tí a kò tíì ti àjàgà+ bọ̀ lọ́rùn rí, kí ẹ sì di àwọn abo màlúù náà mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú kí àwọn ọmọ wọn padà lẹ́yìn wọn lọ sílé.  Kí ẹ sì gbé àpótí Jèhófà, kí ẹ sì gbé é sórí kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì fi àwọn ohun èlò wúrà+ tí ẹ óò dá padà fún un gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ sínú àpótí kan ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Kí ẹ sì fi í ránṣẹ́, kí ó sì lọ.  Kí ẹ sì wò ó: Bí ó bá jẹ́ ojú ọ̀nà sí ìpínlẹ̀ rẹ̀ ni ó gbà gòkè lọ, sí Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ òun ni ó ṣe ibi ńláǹlà yìí sí wa; ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa yóò mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kàn wá; jàǹbá+ kan ni ó ṣẹlẹ̀ sí wa.” 10  Àwọn ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Nítorí náà, wọ́n mú abo màlúù méjì tí ń fọ́mọ lọ́mú, wọ́n sì dì wọ́n mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì sé àwọn ọmọ wọn mọ́ ilé. 11  Nígbà náà ni wọ́n gbé àpótí Jèhófà sórí kẹ̀kẹ́ náà,+ àti àpótí àti àwọn eku àgó wúrà àti ère jẹ̀díjẹ̀dí wọn pẹ̀lú. 12  Àwọn abo màlúù náà sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ tààrà ní ojú ọ̀nà sí Bẹti-ṣémẹ́ṣì.+ Òpópó kan náà ni wọ́n ń bá lọ, ní kíké mùúù bí wọ́n ṣe ń lọ, wọn kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Ní gbogbo àkókò náà, àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀+ àwọn Filísínì ń rìn tẹ̀ lé wọn títí dé ààlà Bẹti-ṣémẹ́ṣì. 13  Àwọn ènìyàn Bẹti-ṣémẹ́ṣì sì ń kárúgbìn ìkórè àlìkámà+ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì rí Àpótí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ ní rírí i. 14  Kẹ̀kẹ́ náà sì wá sínú pápá Jóṣúà ará Bẹti-ṣémẹ́ṣì, ó sì dúró pa síbẹ̀, síbi tí òkúta títóbi kan wà. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí la igi kẹ̀kẹ́ náà sí wẹ́wẹ́, àwọn abo màlúù+ náà ni wọ́n sì fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà.+ 15  Àwọn ọmọ Léfì + tìkára wọn sì gbé àpótí Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ àti àpótí tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, inú èyí tí ohun èlò wúrà náà wà, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti fi í sórí òkúta títobi náà. Àwọn ọkùnrin Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ ní tiwọn, sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun, wọ́n sì ń bá a lọ ní rírú àwọn ẹbọ sí Jèhófà ní ọjọ́ yẹn. 16  Àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀+ márùn-ún ti àwọn Filísínì alára sì rí i, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n padà sí Ékírónì ní ọjọ́ yẹn. 17  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni jẹ̀díjẹ̀dí wúrà tí àwọn Filísínì dá padà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi fún Jèhófà:+ ọ̀kan fún Áṣídódì,+ ọ̀kan fún Gásà,+ ọ̀kan fún Áṣíkẹ́lónì,+ ọ̀kan fún Gátì,+ ọ̀kan fún Ékírónì.+ 18  Àwọn eku àgó wúrà náà sì jẹ́ ní iye gbogbo ìlú ńlá àwọn Filísínì tí ó jẹ́ ti àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ márùn-ún, láti ìlú ńlá olódi sí abúlé ìgbèríko gbayawu. Òkúta títóbi náà lórí èyí tí wọ́n mú àpótí Jèhófà sinmi lé sì jẹ́ ẹ̀rí títí di òní yìí nínú pápá Jóṣúà ará Bẹti-ṣémẹ́ṣì. 19  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ọkùnrin Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ balẹ̀, nítorí pé wọ́n bojú wo àpótí Jèhófà. Nítorí náà, ó ṣá àádọ́rin ọkùnrin balẹ̀ lára àwọn ènìyàn náà—ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin—àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀ nítorí pé Jèhófà ti fi ìpakúpa rẹpẹtẹ ṣá àwọn ènìyàn náà balẹ̀.+ 20  Síwájú sí i, àwọn ọkùnrin Bẹti-ṣémẹ́ṣì wí pé: “Ta ni yóò lè dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run mímọ́ yìí,+ ọ̀dọ̀ ta ni yóò sì fi wá sílẹ̀ lọ?”+ 21  Níkẹyìn, wọ́n rán àwọn ońṣẹ́ sí àwọn olùgbé Kiriati-jéárímù+ pé: “Àwọn Filísínì ti dá àpótí Jèhófà padà. Ẹ sọ̀ kalẹ̀ wá. Ẹ gbé e gòkè sọ́dọ̀ ara yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé