Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 5:1-12

5  Ní ti àwọn Filísínì, wọ́n gbé àpótí+ Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n sì wá gbé e láti Ẹbinísà lọ sí Áṣídódì.+  Àwọn Filísínì sì tẹ̀ síwájú láti gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n sì gbé e wá sínú ilé Dágónì, wọ́n sì gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́ Dágónì.+  Nígbà náà ni àwọn ará Áṣídódì dìde ní kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì gan-an, sì kíyè sí i, Dágónì ti ṣubú ní ìdojúbolẹ̀ níwájú àpótí Jèhófà.+ Nítorí náà, wọ́n gbé Dágónì, wọ́n sì dá a padà sí ipò rẹ̀.+  Nígbà tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e gan-an, sì kíyè sí i, Dágónì ti ṣubú ní ìdojúbolẹ̀ níwájú àpótí Jèhófà, pẹ̀lú orí Dágónì àti àwọn àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó ti ké kúrò, sí ibi àbáwọlé.+ Ibi ẹ̀yà ẹja nìkan ni ó ṣẹ́ kù sára rẹ̀.  Ìdí nìyẹn tí àwọn àlùfáà Dágónì àti gbogbo àwọn tí ń lọ sí ilé Dágónì kì í fi í tẹ ibi àbáwọlé Dágónì ní Áṣídódì títí di òní yìí.  Ọwọ́ Jèhófà+ sì wá wúwo lára àwọn ará Áṣídódì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fa ẹ̀rù jì nnìjì nnì, ó sì ń fi jẹ̀díjẹ̀dí+ kọlù wọ́n, èyíinì ni, Áṣídódì àti àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀.  Àwọn ènìyàn Áṣídódì sì wá rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí, wọ́n sì wí pé: “Má ṣe jẹ́ kí àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì máa gbé pẹ̀lú wa, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ti le lára wa àti lára Dágónì ọlọ́run wa.”+  Nítorí náà, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì kó gbogbo olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ àwọn Filísínì jọ sọ́dọ̀ ara wọn, wọ́n sì wí pé: “Kí ni kí a ṣe sí àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì?” Níkẹyìn, wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì lọ sí tòsí Gátì.”+ Nítorí náà, wọ́n gbé àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá sí tòsí ibẹ̀.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé e wá sí tòsí ibẹ̀, ọwọ́ Jèhófà+ wá wà lórí ìlú ńlá náà pẹ̀lú ìdàrúdàpọ̀ ńláǹlà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu àwọn ènìyàn ìlú ńlá náà, láti ẹni kékeré títí dé ńlá, jẹ̀díjẹ̀dí+ sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n. 10  Nítorí náà, wọ́n fi àpótí Ọlọ́run tòótọ́ ránṣẹ́ sí Ékírónì.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àpótí Ọlọ́run tòótọ́ dé Ékírónì, àwọn ará Ékírónì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde, pé: “Wọ́n ti gbé àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá sí tòsí mi láti fi ikú pa èmi àti àwọn ènìyàn mi!”+ 11  Nítorí náà, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì kó gbogbo olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ àwọn Filísínì jọ, wọ́n sì wí pé: “Ẹ fi àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì ránṣẹ́, kí ó lè padà sí ipò rẹ̀, kí ó má bàa fi ikú pa èmi àti àwọn ènìyàn mi.” Nítorí ìdàrúdàpọ̀ tí ń ṣekú pani ti ṣẹlẹ̀ nínú gbogbo ìlú ńlá náà;+ ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ti wúwo gidigidi níbẹ̀,+ 12  àwọn ènìyàn tí kò kú ni a sì ti fi jẹ̀díjẹ̀dí+ kọlù. Igbe+ ìlú ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ sì ń bá a nìṣó ní gígòkè re ọ̀run.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé