Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 4:1-22

4  Ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní títọ gbogbo Ísírẹ́lì wá. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì jáde lọ láti pàdé àwọn Filísínì nínú ìjà ogun; wọ́n sì dó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹbinísà,+ àwọn Filísínì alára sì dó sí Áfékì.+  Àwọn Filísínì sì tẹ̀ síwájú láti tẹ́ ìtẹ́gun+ láti pàdé Ísírẹ́lì, ìjà ogun náà sì yíwọ́, tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ṣẹ́gun Ísírẹ́lì níwájú àwọn Filísínì,+ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣá nǹkan bí ẹgbàajì ọkùnrin balẹ̀ ní ìlà ogun pẹ́kípẹ́kí ní pápá.  Nígbà tí àwọn ènìyàn náà dé ibùdó, àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Èé ṣe tí Jèhófà fi ṣẹ́gun wa lónìí níwájú àwọn Filísínì?+ Ẹ jẹ́ kí a lọ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà+ láti Ṣílò wá sọ́dọ̀ ara wa, kí ó lè wá sí àárín wa, kí ó sì lè gbà wá là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọ̀tá wa.”  Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà ránṣẹ́ sí Ṣílò, láti ibẹ̀ wá, wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ẹni tí ń jókòó lórí àwọn kérúbù.+ Àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́, èyíinì ni, Hófínì àti Fíníhásì.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àpótí májẹ̀mú Jèhófà dé sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hó yèè,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ fi wà nínú ìmìtìtì.  Àwọn Filísínì pẹ̀lú wá gbọ́ ìró híhó náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Kí ni ohun tí ìró híhó yèè+ yìí ní ibùdó àwọn Hébérù túmọ̀ sí?” Níkẹyìn, wọ́n wá mọ̀ pé àpótí Jèhófà ti dé sí ibùdó.  Àyà sì fo àwọn Filísínì, nítorí, wọ́n wí pé: “Ọlọ́run ti dé sí ibùdó!”+ Nítorí náà, wọ́n wí pé: “A gbé, nítorí irú nǹkan bí èyí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí!  A gbé! Ta ni yóò gbà wá là kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run ọlọ́lá ńlá yìí? Èyí ni Ọlọ́run tí ó jẹ́ olùfi gbogbo onírúurú ìpakúpa kọlù Íjíbítì ní aginjù.+  Ẹ fi ara yín hàn ní onígboyà, kí ẹ sì fi hàn pé ọkùnrin ni yín, ẹ̀yin Filísínì, kí ẹ má bàa sin àwọn Hébérù gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti sìn yín;+ kí ẹ sì fi hàn pé ọkùnrin ni yín, kí ẹ sì jà!” 10  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Filísínì jà, a sì ṣẹ́gun Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, olúkúlùkù sínú àgọ́ rẹ̀;+ ìpakúpa náà sì wá pọ̀ gidigidi,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ àwọn ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn fi ṣubú láti inú Ísírẹ́lì.+ 11  Àpótí Ọlọ́run pàápàá ni a sì gbà,+ ọmọkùnrin Élì méjèèjì , Hófínì àti Fíníhásì sì kú.+ 12  Ọkùnrin ará Bẹ́ńjámínì kan sì ń sáré lọ láti ojú ìlà ogun tí ó fi dé Ṣílò ní ọjọ́ yẹn pẹ̀lú ẹ̀wù rẹ̀ gbígbọ̀nya+ àti ìdọ̀tí ní orí rẹ̀.+ 13  Nígbà tí ó dé, sì kíyè sí i, Élì jókòó sórí ìjókòó ní ẹ̀gbẹ́ ojú ọ̀nà, ó ń ṣọ́nà, nítorí tí ọkàn-àyà rẹ̀ ti wárìrì nítorí àpótí Ọlọ́run tòótọ́.+ Ọkùnrin náà fúnra rẹ̀ sì wọlé lọ láti ròyìn nínú ìlú ńlá náà, gbogbo ìlú ńlá náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ké. 14  Élì sì wá gbọ́ ìró igbe ẹkún náà. Nítorí náà, ó wí pé: “Kí ni ohun tí ìró yánpọnyánrin yìí túmọ̀ sí?”+ Ọkùnrin náà sì ṣe wéré, kí ó lè wọlé lọ láti ròyìn fún Élì. 15  (Wàyí o, Élì jẹ́ ẹni ọdún méjì -dín-lọ́gọ́rùn-ún, ojú rẹ̀ sì ti là sílẹ̀ rangandan tí kò sì lè ríran.)+ 16  Ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Élì pé: “Èmi ni ẹni tí ń bọ̀ láti ojú ìlà ogun, èmi—ojú ìlà ogun ni mo sì ti sá lónìí.” Látàrí èyí, ó wí pé: “Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ọmọkùnrin mi?” 17  Nítorí náà, amúhìnwá náà dáhùn, ó sì wí pé: “Ísírẹ́lì ti sá níwájú àwọn Filísínì, a sì ti ṣẹ́gun àwọn ènìyàn wa lọ́nà kíkàmàmà pẹ̀lú;+ ọmọkùnrin rẹ méjèèjì —Hófínì àti Fíníhásì+—pẹ̀lú sì ti kú, àní àpótí Ọlọ́run tòótọ́ ni wọ́n sì ti gbà.”+ 18  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní ìṣẹ́jú tí ó mẹ́nu kan àpótí Ọlọ́run tòótọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣubú sẹ́yìn láti orí ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè, ọrùn rẹ̀ sì ṣẹ́, tí ó fi jẹ́ pé ó kú, nítorí pé ọkùnrin náà ti darúgbó, ó sì tẹ̀wọ̀n; òun fúnra rẹ̀ sì ti ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún. 19  Aya ọmọ rẹ̀, aya Fíníhásì, sì lóyún, ó ń sún mọ́ àtibímọ, ó sì wá gbọ́ ìròyìn náà pé wọ́n ti gba àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àti pé baba ọkọ òun àti ọkọ òun ti kú. Látàrí ìyẹn, ó tẹ̀ ba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bímọ, nítorí tí ìroragógó rẹ̀ dé bá a ní àìròtẹ́lẹ̀.+ 20  Ní àkókò ikú rẹ̀, àwọn obìnrin tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Má fòyà, nítorí pé ọmọkùnrin ni ìwọ bí.”+ Kò sì dáhùn, kò sì fi ọkàn-àyà rẹ̀ sí i. 21  Ṣùgbọ́n ó pe ọmọdékùnrin náà ní Íkábódì,+ ó wí pé: “Ògo ti fi Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,”+ èyí jẹ́ ní títọ́ka sí àpótí Ọlọ́run tòótọ́ tí wọ́n gbà àti ní títọ́ka sí baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀.+ 22  Nítorí náà, ó wí pé: “Ògo ti fi Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,+ nítorí tí a ti gba àpótí Ọlọ́run tòótọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé