Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 31:1-13

31  Wàyí o, àwọn Filísínì ń bá Ísírẹ́lì jà,+ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì fẹsẹ̀ fẹ kúrò níwájú àwọn Filísínì, wọ́n sì ń ṣubú sílẹ̀ ní òkú+ ní Òkè Ńlá Gíbóà.+  Àwọn Filísínì sì sún mọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí; níkẹyìn, àwọn Filísínì sì ṣá Jónátánì+ àti Ábínádábù+ àti Maliki-ṣúà,+ àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù balẹ̀.  Ìjà náà sì le kú fún Sọ́ọ̀lù, níkẹyìn, ọwọ́ àwọn ọ̀tafà, àwọn olùlo ọrun, sì bà á, ó sì gbọgbẹ́ yánnayànna láti ọwọ́ àwọn ọ̀tafà.+  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù sọ fún arùhámọ́ra rẹ̀ pé: “Fa idà rẹ yọ,+ kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́+ wọ̀nyí má bàa wá, kí wọ́n sì gún mi ní àgúnyọ dájúdájú, kí wọ́n sì hùwà ìkà sí mi.” Arùhámọ́ra rẹ̀ kò sì fẹ́+ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí tí àyà fò ó gidigidi. Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà náà, ó sì ṣubú lé e.+  Nígbà tí arùhámọ́ra rẹ̀ rí i pé Sọ́ọ̀lù ti kú,+ nígbà náà ni òun pẹ̀lú ṣubú lé idà tirẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀.+  Bí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta àti arùhámọ́ra rẹ̀, àní gbogbo ọkùnrin rẹ̀, ti ṣe kú pa pọ̀ ní ọjọ́ yẹn nìyẹn.+  Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ àti àwọn tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì rí i pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti sá lọ, àti pé Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìlú ńlá sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ,+ lẹ́yìn èyí tí àwọn Filísínì wọlé wá, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú wọn.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì pé, nígbà tí àwọn Filísínì wá bọ́ àwọn nǹkan tí ó wà lára àwọn tí a pa,+ wọ́n rí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta tí ó ṣubú sórí Òkè Ńlá Gíbóà.+  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti gé orí+ rẹ̀ kúrò, wọ́n sì bọ́ ìhámọ́ra rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ sí ilẹ̀ àwọn Filísínì tí ó wà ní gbogbo ayíká pé kí wọ́n sọ+ fún àwọn ilé òrìṣà+ wọn àti àwọn ènìyàn náà. 10  Níkẹyìn, wọ́n fi ìhámọ́ra+ rẹ̀ sínú ilé àwọn ère Áṣítórétì,+ òkú rẹ̀ ni wọ́n sì dè mọ́ ògiri Bẹti-ṣánì.+ 11  Ní ti òun, àwọn olùgbé Jabẹṣi-gílíádì+ sì wá gbọ́ ohun tí àwọn Filísínì ṣe sí Sọ́ọ̀lù. 12  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin dìde, wọ́n sì lọ láti òru mọ́jú, wọ́n sì gbé òkú Sọ́ọ̀lù àti òkú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kúrò lára ògiri Bẹti-ṣánì, wọ́n sì wá sí Jábẹ́ṣì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.+ 13  Nígbà náà ni wọ́n kó egungun wọn,+ wọ́n sì sin+ wọ́n sábẹ́ igi támáríkì+ ní Jábẹ́ṣì, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé