Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 30:1-31

30  Ó sì ṣẹlẹ̀, nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ń bọ̀ ní Síkílágì+ ní ọjọ́ kẹta, pé àwọn ọmọ Ámálékì+ gbé sùnmọ̀mí wá sí gúúsù àti sí Síkílágì; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu Síkílágì, wọ́n sì fi iná sun ún,  wọ́n sì kó àwọn obìnrin+ àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ lọ ní òǹdè, láti ẹni tí ó kéré jù lọ dórí ẹni tí ó tóbi jù lọ. Wọn kò fi ikú pa ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n wọ́n kó wọn dání lọ, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ.  Nígbà tí Dáfídì dé inú ìlú ńlá náà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀, họ́wù, a ti fi iná sun ún, àti pé, ní ti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn, a ti kó wọn lọ ní òǹdè.  Dáfídì àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún,+ títí agbára kò fi sí nínú wọn láti sunkún mọ́ rárá.  Àwọn aya Dáfídì méjèèjì sì ni a ti kó lọ ní òǹdè, Áhínóámù+ ọmọbìnrin ará Jésíréélì àti Ábígẹ́lì+ aya Nábálì ará Kámẹ́lì.  Ó sì mú wàhálà-ọkàn bá Dáfídì gidigidi,+ nítorí pé àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀ sísọ ọ́ lókùúta;+ nítorí ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn náà ti di kíkorò,+ olúkúlùkù nítorí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. Nítorí náà, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí fún ara rẹ̀ lókún nípasẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+  Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Ábíátárì+ àlùfáà, ọmọkùnrin Áhímélékì pé: “Jọ̀wọ́, mú éfódì+ tọ̀ mí wá.” Ábíátárì sì mú éfódì tọ Dáfídì wá.  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ pé: “Ṣé kí n lépa ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí yìí? Ṣé èmi yóò lé wọn bá?” Látàrí èyí, ó sọ+ fún un pé: “Lépa wọn, nítorí ìwọ yóò lé wọn bá láìkùnà, ìwọ yóò sì ṣe ìdáǹdè láìkùnà.”+  Ní kánmọ́kánmọ́, Dáfídì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, òun àti ẹgbẹ̀ta ọkùnrin+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì lọ títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Bésórì, àwọn ọkùnrin tí a ó fi sílẹ̀ sẹ́yìn sì dúró jẹ́ẹ́. 10  Dáfídì sì ń lépa wọn nìṣó,+ òun àti irínwó ọkùnrin, ṣùgbọ́n igba ọkùnrin tí ó ti rẹ̀ jù láti ré kọjá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Bésórì+ dúró jẹ́ẹ́. 11  Wọ́n sì wá rí ọkùnrin kan, ará Íjíbítì,+ nínú pápá. Nítorí náà, wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Dáfídì, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ jẹ, wọ́n sì fún un ní omi mu. 12  Síwájú sí i, wọ́n fún un ní ègé ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́ àti ìṣù èso àjàrà gbígbẹ méjì .+ Nígbà náà ni ó jẹun, ẹ̀mí+ rẹ̀ sì padà sínú rẹ̀; nítorí kò tíì jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò tíì mu omi fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta. 13  Wàyí o, Dáfídì sọ fún un pé: “Ti ta ni ìwọ jẹ́, ibo ni o sì ti wá?” ó dáhùn pé: “Ẹmẹ̀wà ará Íjíbítì ni mí, ẹrú ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ Ámálékì, ṣùgbọ́n ọ̀gá mi fi mí sílẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn ní ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn.+ 14  Àwa ni ó gbé sùnmọ̀mí lọ sí gúúsù àwọn Kérétì+ àti sí èyí tí ó jẹ́ ti Júdà àti sí gúúsù Kálébù;+ Síkílágì ni a sì fi iná sun.” 15  Látàrí èyí, Dáfídì sọ fún un pé: “Ìwọ yóò ha mú mi sọ̀ kalẹ̀ lọ bá ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí yìí bí?” Ó fèsì pé: “Fi Ọlọ́run búra+ fún mi pé ìwọ kì yóò fi ikú pa mí, àti pé ìwọ kì yóò fi mi lé ọ̀gá mi lọ́wọ́,+ èmi yóò sì mú ọ sọ̀ kalẹ̀ lọ bá ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí yìí.” 16  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó mú un sọ̀ kalẹ̀ lọ,+ wọ́n sì tàn kálẹ̀ níbẹ̀ lọ́nà rúdurùdu sí ojú gbogbo ilẹ̀ náà, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jẹ àsè+ ní tìtorí gbogbo ohun ìfiṣèjẹ púpọ̀ tí wọ́n ti kó ní ilẹ̀ àwọn Filísínì àti ní ilẹ̀ Júdà.+ 17  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá wọn balẹ̀ láti ìdájí títí di ìrọ̀lẹ́, kí ó lè yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun; kò sì sí ọkùnrin kan lára wọn tí ó sá àsálà+ bí kò ṣe irínwó ọ̀dọ́kùnrin tí ó gun ràkúnmí tí ó sì fẹsẹ̀ fẹ. 18  Dáfídì sì dá gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Ámálékì ti kó nídè,+ Dáfídì sì dá àwọn aya rẹ̀ méjèèjì nídè. 19  Kò sì sí nǹkan kan tí ó jẹ́ tiwọn tí ó kù, láti orí èyí tí ó kéré jù lọ dórí èyí tí ó tóbi jù lọ àti dórí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti láti orí ohun ìfiṣèjẹ, àní dórí ohunkóhun tí wọ́n mú fún ara wọn pàápàá.+ Gbogbo rẹ̀ ni Dáfídì gbà padà. 20  Nítorí náà, Dáfídì kó gbogbo agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran náà, èyí tí wọ́n dà ṣáájú àwọn ohun ọ̀sìn yòókù. Nígbà náà ni wọ́n wí pé: “Èyí ni ohun ìfiṣèjẹ Dáfídì.”+ 21  Níkẹyìn, Dáfídì dé ọ̀dọ̀ igba ọkùnrin+ tí ó ti rẹ̀ jù láti bá Dáfídì lọ, àwọn tí wọ́n sì ti mú kí ó jókòó lẹ́bàá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Bésórì; wọ́n sì jáde wá láti pàdé Dáfídì àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí Dáfídì sún mọ́ àwọn ènìyàn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àlàáfíà wọn. 22  Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo ọkùnrin búburú àti aláìdára fún ohunkóhun+ lára àwọn ọkùnrin tí ó bá Dáfídì lọ dáhùn, wọ́n sì ń sọ ṣáá pé: “Nítorí ìdí náà pé wọn kò bá wa lọ, a kì yóò fún wọn ní nǹkan kan nínú ohun ìfiṣèjẹ tí a ti dá nídè, bí kò ṣe aya olúkúlùkù àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n mú wọn, kí wọ́n sì máa lọ.” 23  Ṣùgbọ́n Dáfídì sọ pé: “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin arákùnrin mi, pẹ̀lú ohun tí Jèhófà fi fún wa,+ ní ti pé ó fi ìṣọ́ ṣọ́ wá,+ tí ó sì fi ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí tí ó wá gbéjà kò wá lé wa lọ́wọ́.+ 24  Ta ni yóò sì fetí sí yín ní ti àsọjáde yìí? Nítorí bí ìpín ẹni tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìjà ogun ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni ìpín ẹni tí ó jókòó nídìí ẹrù àjò+ yóò rí. Gbogbo wọn ni yóò ṣe àjọpín.”+ 25  Ó sì ṣẹlẹ̀ láti ọjọ́ náà lọ pé, ó fi í lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti ìpinnu ìdájọ́+ fún Ísírẹ́lì títí di òní yìí. 26  Nígbà tí Dáfídì wá sí Síkílágì, ó bẹ̀rẹ̀ sí mú lára ohun ìfiṣèjẹ náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbà ọkùnrin Júdà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀,+ pé: “Ẹ̀bùn+ ìbùkún nìyí fún yín láti inú ohun ìfiṣèjẹ àwọn ọ̀tá Jèhófà.” 27  Sí àwọn tí ó wà ní Bẹ́tẹ́lì,+ àti sí àwọn tí ó wà ní Rámótì+ ti gúúsù, àti sí àwọn tí ó wà ní Játírì,+ 28  àti sí àwọn tí ó wà ní Áróérì, àti sí àwọn tí ó wà ní Sífúmótì, àti sí àwọn tí ó wà ní Éṣítémóà,+ 29  àti sí àwọn tí ó wà ní Rákálì, àti sí àwọn tí ó wà nínú ìlú ńlá àwọn ọmọ Jéráméélì,+ àti sí àwọn tí ó wà nínú ìlú ńlá àwọn Kénì,+ 30  àti sí àwọn tí ó wà ní Hóómà,+ àti sí àwọn tí ó wà ní Bóráṣánì,+ àti sí àwọn tí ó wà ní Átákì, 31  àti sí àwọn tí ó wà ní Hébúrónì,+ àti sí gbogbo ibi tí Dáfídì ti rìn káàkiri, òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé