Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 3:1-21

3  Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń ṣe ìránṣẹ́+ fún Jèhófà níwájú Élì, ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà+ sì ṣọ̀wọ́n ní ọjọ́ wọnnì;+ kò sí ìran+ tí a ń tàn káàkiri.  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé, Élì dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀, ojú rẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí di bàìbàì;+ òun kò lè ríran.  A kò sì tíì fẹ́ fì tílà Ọlọ́run pa, Sámúẹ́lì sì dùbúlẹ̀ sínú tẹ́ńpìlì+ Jèhófà, níbi tí àpótí Ọlọ́run wà.  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pe Sámúẹ́lì. Látàrí èyí, ó wí pé: “Èmi nìyí.”+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sì wí pé: “Èmi nìyí, nítorí tí ìwọ pè mí.” Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Èmi kò pè ọ́. Tún lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà, ó lọ dùbúlẹ̀.  Jèhófà sì ń bá a lọ láti pè lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Sámúẹ́lì!”+ Látàrí èyí, Sámúẹ́lì dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sì wí pé: “Èmi nìyí, nítorí tí ìwọ pè mí ní ti tòótọ́.” Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Èmi kò pè ọ́, ọmọkùnrin mi.+ Tún lọ dùbúlẹ̀.”  (Ní ti Sámúẹ́lì, kò tíì mọ Jèhófà, a kò sì tíì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí ọ̀rọ̀ Jèhófà payá fún un.)+  Nítorí náà, Jèhófà tún pè ní ìgbà kẹta pé: “Sámúẹ́lì!” Látàrí ìyẹn, ó dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sì wí pé: “Èmi nìyí, nítorí tí ìwọ ti ní láti pè mí.” Élì sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òye mọ̀ pé Jèhófà ni ó ń pe ọmọdékùnrin náà.  Nítorí náà, Élì wí fún Sámúẹ́lì pé: “Lọ, dùbúlẹ̀, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ó bá pè ọ́, kí o wí pé, ‘Sọ̀rọ̀, Jèhófà, nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń fetí sílẹ̀.’” Nítorí náà, Sámúẹ́lì lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀. 10  Nígbà náà ni Jèhófà wá, ó sì mú ìdúró rẹ̀, ó sì pè bí ti àtẹ̀yìnwá pé: “Sámúẹ́lì, Sámúẹ́lì!” Látàrí èyí, Sámúẹ́lì sọ pé: “Sọ̀rọ̀, nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń fetí sílẹ̀.”+ 11  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Wò ó! Èmi yóò ṣe+ ohun kan ní Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ pé bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ nípa rẹ̀, etí rẹ̀ méjèèjì yóò hó yee.+ 12  Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò mú gbogbo ohun tí mo ti sọ sí Élì nípa ilé rẹ̀ ṣẹ, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.+ 13  Kí o sì sọ fún un pé èmi yóò ṣe ìdájọ́ ilé rẹ̀+ fún àkókò tí ó lọ kánrin nítorí ìṣìnà tí ó mọ̀,+ nítorí pé àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ń pe ibi wá sórí Ọlọ́run,+ òun kò sì bá wọn wí lọ́nà mímúná.+ 14  Ìdí sì nìyẹn tí mo fi búra fún ilé Élì pé ìṣìnà ilé Élì ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ ẹbọ yọ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ 15  Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní dídùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀. Nígbà náà ni ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà.+ Sámúẹ́lì sì fòyà láti sọ fún Élì nípa àfihàn náà.+ 16  Ṣùgbọ́n Élì pe Sámúẹ́lì, ó sì wí pé: “Sámúẹ́lì, ọmọkùnrin mi!” Látàrí èyí, ó sọ pé: “Èmi nìyí.” 17  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún ọ? Jọ̀wọ́, má fi í pa mọ́ fún mi.+ Kí Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì fi kún un,+ bí ìwọ bá fi ọ̀rọ̀ kan pa mọ́ fún mi nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún ọ.” 18  Nítorí náà, Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un, kò sì fi ohunkóhun pa mọ́ fún un. Látàrí ìyẹn, ó wí pé: “Jèhófà ni. Kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”+ 19  Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní dídàgbà, Jèhófà fúnra rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,+ kò sì mú kí èyíkéyìí nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́ sí ilẹ̀.+ 20  Gbogbo Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà+ sì wá mọ̀ pé Sámúẹ́lì ni ẹni tí a fà kalẹ̀ fún ipò wòlíì fún Jèhófà.+ 21  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti fara hàn ní Ṣílò lẹ́ẹ̀kan sí i,+ nítorí pé Jèhófà ṣí ara rẹ̀ payá fún Sámúẹ́lì ní Ṣílò nípa ọ̀rọ̀ Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé