Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 29:1-11

29  Àwọn Filísínì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo ibùdó wọn jọpọ̀ sí Áfékì, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó sẹ́bàá ìsun tí ó wà ní Jésíréélì.+  Àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀+ àwọn Filísínì sì ń kọjá lọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì ń kọjá lọ lẹ́yìn ìgbà náà pẹ̀lú Ákíṣì.+  Àwọn ọmọ aládé Filísínì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Kí ni ohun tí àwọn Hébérù+ wọ̀nyí ní lọ́kàn?” Látàrí èyí, Ákíṣì sọ fún àwọn ọmọ aládé Filísínì pé: “Ṣé Dáfídì ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì kọ́ yìí, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi níhìn-ín fún ọdún kan tàbí méjì ,+ èmi kò sì rí+ ẹyọ ohun kan nínú rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti sá wá sọ́dọ̀ mi títí di òní yìí?”  Ìkannú àwọn ọmọ aládé Filísínì sì ru sí i; àwọn ọmọ aládé Filísínì sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Mú kí ọkùnrin náà padà,+ kí ó sì padà lọ sí àyè rẹ̀ níbi tí o yàn fún un; má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìjà ogun, kí ó má bàa di alátakò+ wa nínú ìjà ogun. Kí sì ni ohun tí ẹni yìí yóò fi fi ara rẹ̀ sí ipò ojú rere lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀? Kì í ha ṣe orí àwọn ọkùnrin wa wọ̀nyí?  Èyí kì í ha ṣe Dáfídì ẹni tí wọ́n ń fi ijó dáhùn sí, pé, ‘Sọ́ọ̀lù ti ṣá ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀ balẹ̀, àti Dáfídì ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá tirẹ̀’?”+  Nítorí náà, Ákíṣì+ pe Dáfídì, ó sì wí fún un pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ ìwọ jẹ́ adúróṣánṣán, jíjáde rẹ àti wíwọlé rẹ+ pẹ̀lú mi ní ibùdó sì dára ní ojú mi;+ nítorí èmi kò rí ìwà búburú nínú rẹ láti ọjọ́ tí o ti wá sọ́dọ̀ mi títí di òní yìí.+ Ṣùgbọ́n o kò dára ní ojú àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀.+  Wàyí o, padà, kí o sì lọ ní àlàáfíà, kí o má bàa ṣe ohunkóhun tí ó burú ní ojú àwọn olúwa alájùmọ̀ṣepọ̀ Filísínì.”  Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì sọ fún Ákíṣì pé: “Họ́wù, kí ni mo ṣe,+ kí sì ni o rí nínú ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ tí mo ti wà níwájú rẹ títí di òní yìí,+ tí èmi kì yóò fi wá, kí n sì bá àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba jà ní ti tòótọ́?”  Látàrí èyí, Ákíṣì dáhùn, ó sì sọ fún Dáfídì pé: “Mo mọ̀ dáadáa pé o dára ní ojú tèmi, gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì Ọlọ́run.+ Kì kì pé àwọn ọmọ aládé Filísínì ni ó sọ pé, ‘Kí ó má ṣe bá wa gòkè lọ sínú ìjà ogun.’ 10  Wàyí o, dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ tí ó bá ọ wá; kí ẹ sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá ti mọ́ tó fún yín. Nígbà náà ni kí o lọ.”+ 11  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì dìde ní kùtùkùtù, òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, láti lọ ní òwúrọ̀,+ láti padà sí ilẹ̀ àwọn Filísínì; àwọn Filísínì pàápàá sì gòkè lọ sí Jésíréélì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé