Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 28:1-25

28  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé, àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ibùdó wọn jọ kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun lè bá Ísírẹ́lì jagun.+ Nítorí náà, Ákíṣì sọ fún Dáfídì pé: “Láìsí iyèméjì , ìwọ mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí o bá jáde lọ sínú ibùdó, ìwọ àti àwọn ọkùnrin rẹ.”+  Látàrí ìyẹn, Dáfídì sọ fún Ákíṣì pé: “Ìdí nìyẹn tí ìwọ fúnra rẹ fi mọ ohun tí ó yẹ kí ìránṣẹ́ rẹ ṣe.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ákíṣì sọ fún Dáfídì pé: “Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi yàn ọ́ ṣe olùṣọ́ orí mi nígbà gbogbo.”+  Wàyí o, Sámúẹ́lì alára ti kú, gbogbo Ísírẹ́lì sì ti pohùn réré ẹkún fún un, wọ́n sì sin ín sí Rámà ní ìlú ńlá rẹ̀.+ Ní ti Sọ́ọ̀lù, ó ti mú àwọn abẹ́mìílò àti àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.+  Nítorí náà, àwọn Filísínì kóra jọpọ̀, wọ́n sì wá, wọ́n sì pabùdó sí Ṣúnẹ́mù.+ Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù kó gbogbo Ísírẹ́lì jọpọ̀, wọ́n sì pabùdó sí Gíbóà.+  Nígbà tí Sọ́ọ̀lù wá rí ibùdó àwọn Filísínì, àyà fò ó, ọkàn-àyà rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì gidigidi.+  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ń wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ Jèhófà kò dá a lóhùn rárá,+ yálà nípasẹ̀ àwọn àlá+ tàbí nípasẹ̀ Úrímù+ tàbí nípasẹ̀ àwọn wòlíì.+  Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó jẹ́ ìyálóde lẹ́nu ìbẹ́mìílò,+ dájúdájú, èmi yóò sì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Wò ó! Obìnrin kan tí ó jẹ́ ìyálóde lẹ́nu ìbẹ́mìílò wà ní Ẹ́ń-dórì.”+  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù para dà,+ ó sì fi ẹ̀wù mìíràn wọ ara rẹ̀, ó sì lọ, òun àti ọkùnrin méjì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì wá sọ́dọ̀ obìnrin náà ní òru.+ Ó sọ wàyí pé: “Jọ̀wọ́, woṣẹ́+ fún mi nípasẹ̀ ìbẹ́mìílò, kí o sì mú ẹni tí èmi yóò dárúkọ fún ọ gòkè wá fún mi.”  Bí ó ti wù kí ó rí, obìnrin náà sọ fún un pé: “Kíyè sí i, ìwọ fúnra rẹ mọ ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe dáadáa, bí ó ti ké àwọn abẹ́mìílò àti àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ yìí.+ Kí wá ni ìdí tí o fi ń ṣe bí olùkẹ́kùn fún ọkàn mi láti mú kí a fi ikú pa mí?”+ 10  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Sọ́ọ̀lù fi Jèhófà búra fún un, pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè,+ ẹ̀bi ìṣìnà kì yóò wá sórí rẹ nínú ọ̀ràn yìí!” 11  Látàrí èyí, obìnrin náà wí pé: “Ta ni èmi yóò mú gòkè wá fún ọ?” Ó fèsì pé: “Mú Sámúẹ́lì gòkè wá fún mi.”+ 12  Nígbà tí obìnrin náà rí “Sámúẹ́lì,”+ ó bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde ní bí ohùn rẹ̀ ṣe lè ròkè tó; obìnrin náà sì ń bá a lọ láti sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Èé ṣe tí ó fi ṣe àgálámàṣà sí mi, nígbà tí ó jẹ́ pé ìwọ alára ni Sọ́ọ̀lù?” 13  Ṣùgbọ́n ọba sọ fún un pé: “Má fòyà, ṣùgbọ́n kí ni o rí?” Obìnrin náà sì ń bá a lọ láti sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Mo rí ọlọ́run+ kan tí ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.” 14  Ní kíá, ó sọ fún un pé: “Báwo ni ìrísí rẹ̀ ti rí?” ó sì fèsì pé: “Ọkùnrin arúgbó kan ní ń jáde bọ̀, ó sì fi aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá bo ara rẹ̀.”+ Látàrí ìyẹn, Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé “Sámúẹ́lì”+ ni, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìdojúbolẹ̀, ó sì wólẹ̀. 15  “Sámúẹ́lì” sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Èé ṣe tí o fi yọ mí lẹ́nu nípa jíjẹ́ kí a mú mi gòkè wá?”+ Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Mo wà nínú hílàhílo gidigidi,+ níwọ̀n bí àwọn Filísínì ti ń bá mi jà, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sì ti lọ+ kúrò lọ́dọ̀ mi, kò sì dá mi lóhùn mọ́, yálà nípasẹ̀ àwọn wòlíì tàbí nípasẹ̀ àwọn àlá;+ tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi ń pè ọ́ láti jẹ́ kí n mọ ohun tí èmi yóò ṣe.”+ 16  “Sámúẹ́lì” sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kí wá ni ìdí tí o fi ń wádìí lọ́dọ̀ mi, nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ+ tí ó sì wá jẹ́ elénìní rẹ?+ 17  Jèhófà yóò sì ṣe fún ara rẹ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípasẹ̀ mi, Jèhófà yóò sì fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ rẹ,+ yóò sì fi í fún Dáfídì ọmọnìkejì rẹ.+ 18  Níwọ̀n bí ìwọ kò ti ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà,+ ìwọ kò sì mú ìbínú rẹ̀ jíjófòfò ṣẹ ní kíkún lòdì sí Ámálékì,+ ìdí nìyẹn tí èyí fi jẹ́ nǹkan tí Jèhófà yóò ṣe sí ọ dájúdájú ní òní yìí. 19  Jèhófà yóò sì tún fi Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Filísínì lọ́wọ́,+ àti lọ́la, ìwọ+ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ+ yóò wà pẹ̀lú mi. Àní ibùdó Ísírẹ́lì pàápàá ni Jèhófà yóò fi lé àwọn Filísínì lọ́wọ́.”+ 20  Látàrí ìyẹn, kíákíá ni Sọ́ọ̀lù ṣubú gbalaja sórí ilẹ̀, ó sì fòyà gidigidi nítorí àwọn ọ̀rọ̀ “Sámúẹ́lì.” Bákan náà, ó ṣẹlẹ̀ pé kò wá sí agbára kankan nínú rẹ̀, nítorí pé kò tíì jẹun ní gbogbo ọjọ́ àti ní gbogbo òru náà. 21  Obìnrin náà tọ Sọ́ọ̀lù wá wàyí, ó sì rí i pé ìyọlẹ́nu ńláǹlà ti dé bá a. Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Kíyè sí i, ìránṣẹ́bìnrin rẹ ti ṣègbọràn sí ohùn rẹ, mo sì tẹ̀ síwájú láti fi ọkàn mi sí àtẹ́lẹwọ́ mi,+ mo sì ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ tí o sọ fún mi. 22  Wàyí o, ìwọ, ẹ̀wẹ̀, jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn ìránṣẹ́bìnrin rẹ; sì jẹ́ kí n gbé oúnjẹ díẹ̀ kalẹ̀ níwájú rẹ, kí o sì jẹun, kí agbára lè wà nínú rẹ, nítorí pé ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ.” 23  Ṣùgbọ́n ó kọ̀, ó sì wí pé: “Èmi kì yóò jẹun.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti obìnrin náà pẹ̀lú ń rọ̀ ọ́ ṣáá. Níkẹyìn, ó ṣègbọràn sí ohùn wọn, ó sì dìde lórí ilẹ̀, ó sì jókòó sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú. 24  Wàyí o, obìnrin náà ní ọmọ màlúù àbọ́sanra+ kan ní ilé. Nítorí náà, ó fi rúbọ ní kíá,+ ó sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó ní àpòrọ́, ó sì fi yan àwọn àkàrà aláìwú. 25  Nígbà náà ni ó gbé wọn kalẹ̀ fún Sọ́ọ̀lù àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì jẹun. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n dìde, wọ́n sì lọ ní òru yẹn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé