Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 27:1-12

27  Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “Wàyí o, a ó ti ọwọ́ Sọ́ọ̀lù gbá mi lọ lọ́jọ́ kan. Kò sí nǹkan tí ó sàn fún mi ju pé kí n sá lọ+ sí ilẹ̀ àwọn Filísínì+ láìkùnà; Sọ́ọ̀lù yóò sì sọ̀rètí nù nípa mi láti tún máa wá mi mọ́ ní gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì,+ dájúdájú, èmi yóò sì sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.”  Nítorí náà, Dáfídì dìde, òun àti ẹgbẹ̀ta ọkùnrin+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ré kọjá lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì+ ọmọkùnrin Máókì, ọba Gátì.  Dáfídì sì ń bá a lọ ní gbígbé pẹ̀lú Ákíṣì ní Gátì, òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀,+ Dáfídì àti àwọn aya rẹ̀ méjèèjì , Áhínóámù+ ará Jésíréélì àti Ábígẹ́lì,+ aya Nábálì, ará Kámẹ́lì.  Nígbà tí ó ṣe, a ròyìn fún Sọ́ọ̀lù pé Dáfídì ti fẹsẹ̀ fẹ lọ sí Gátì, nítorí náà, kò sì tún wá a lọ mọ́ ní ìgbà mìíràn.+  Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún Ákíṣì pé: “Wàyí o, bí mo bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí wọ́n fún mi ní ibì kan nínú ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá tí ó wà ní eréko, kí n lè máa gbé níbẹ̀; nítorí èé ṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò fi máa bá ọ gbé nínú ìlú ńlá ti ọba?”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ákíṣì fún un ní Síkílágì+ ní ọjọ́ yẹn. Ìdí nìyẹn tí Síkílágì fi wá di ti àwọn ọba Júdà títí di òní yìí.  Iye ọjọ́ tí Dáfídì sì fi gbé ní eréko àwọn Filísínì wá jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin.+  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀ kí wọ́n lè gbé sùnmọ̀mí lọ bá àwọn ará Géṣúrì+ àti àwọn Gísì àti àwọn ọmọ Ámálékì;+ nítorí wọ́n ń gbé ilẹ̀ tí ó nasẹ̀ láti Télámù+ títí dé Ṣúrì+ àti títí dé ilẹ̀ Íjíbítì.  Dáfídì sì kọlu ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kò pa ọkùnrin tàbí obìnrin mọ́ láàyè;+ ó sì kó agbo ẹran àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ràkúnmí àti àwọn ẹ̀wù, lẹ́yìn èyí tí ó padà, ó sì wá sọ́dọ̀ Ákíṣì. 10  Nígbà náà ni Ákíṣì sọ pé: “Ibo ni ẹ gbé sùnmọ̀mí lọ lónìí?” Dáfídì fèsì pé:+ “Sí gúúsù Júdà+ àti sí gúúsù àwọn ọmọ Jéráméélì+ àti sí gúúsù àwọn Kénì.”+ 11  Ní ti ọkùnrin àti obìnrin, Dáfídì kò pa ẹnikẹ́ni mọ́ láàyè láti mú wọn wá sí Gátì, ó wí pé: “Kí wọ́n má bàa tú wa fó, pé, ‘Bí Dáfídì ti ṣe nìyí.’”+ (Èyí sì ni ọ̀nà tí ó ń gbà ṣe nǹkan rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tí ó fi gbé ní eréko àwọn Filísínì.) 12  Nítorí náà, Ákíṣì gba Dáfídì gbọ́,+ ó sọ fún ara rẹ̀ pé: “Láìsí àní-àní, ó ti di òórùn burúkú láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì;+ yóò sì ní láti di ìránṣẹ́ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé