Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 26:1-25

26  Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọkùnrin Sífù+ wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà,+ wọ́n wí pé: “Dáfídì kò ha fi ara rẹ̀ pa mọ́ lórí òkè kékeré Hákílà,+ tí ó dojú kọ Jéṣímónì?”+  Sọ́ọ̀lù sì dìde,+ ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí aginjù Sífù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkùnrin,+ àṣàyàn ní Ísírẹ́lì sì wà pẹ̀lú rẹ̀, láti wá Dáfídì nínú aginjù Sífù.  Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí dó sórí òkè kékeré Hákílà, èyí tí ó dojú kọ Jéṣímónì, lẹ́bàá ojú ọ̀nà, nígbà tí Dáfídì ń gbé ní aginjù. Ó sì wá rí i pé Sọ́ọ̀lù ti tẹ̀ lé òun wá sí aginjù náà.  Nítorí náà, Dáfídì rán àwọn amí+ kí ó lè mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù ti dé ní tòótọ́.  Lẹ́yìn náà, Dáfídì dìde, ó sì lọ sí ibi tí Sọ́ọ̀lù dó sí, Dáfídì sì wá rí ibi tí Sọ́ọ̀lù dùbúlẹ̀ sí, àti Ábínérì+ ọmọkùnrin Nérì olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú; Sọ́ọ̀lù sì dùbúlẹ̀ sí gbàgede+ ibùdó, tí àwọn ènìyàn náà sì dó yí i ká.  Nígbà náà ni Dáfídì dáhùn, ó sì sọ fún Áhímélékì ọmọ Hétì+ àti Ábíṣáì+ ọmọkùnrin Seruáyà,+ arákùnrin Jóábù pé: “Ta ni yóò bá mi sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní ibùdó?” Ábíṣáì fèsì pé: “Èmi ni yóò bá ọ sọ̀ kalẹ̀ lọ.”+  Dáfídì sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú Ábíṣáì lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn náà ní òru; sì wò ó! Sọ́ọ̀lù dùbúlẹ̀, ó ń sùn ní gbàgede ibùdó pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ tí ó kì bọ ilẹ̀ ní ibi orí rẹ̀, Ábínérì àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká.  Wàyí o, Ábíṣáì sọ fún Dáfídì pé: “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí.+ Nísinsìnyí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré, èmi kì yóò sì ṣe é sí i lẹ́ẹ̀mejì .”  Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì sọ fún Ábíṣáì pé: “Má ṣe run ún, nítorí ta ni ó na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró Jèhófà+ tí ó sì wà ní aláìmọwọ́-mẹsẹ̀?”+ 10  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò mú ìyọnu àgbálù bá a;+ tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò dé+ tí yóò sì ní láti kú, tàbí yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìjà ogun,+ a ó sì gbá a lọ+ dájúdájú. 11  Kò ṣeé ronú kàn,+ níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà,+ láti na ọwọ́ mi+ sí ẹni àmì òróró Jèhófà!+ Ǹjẹ́ nísinsìnyí, jọ̀wọ́, mú ọ̀kọ̀ tí ó wà ní ibi orí rẹ̀ àti ìdẹ̀ omi, kí o sì jẹ́ kí a mú ọ̀nà wa pọ̀n.” 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì mú ọ̀kọ̀ àti ìdẹ̀ omi ní ibi orí Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn náà, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n; kò sì sí ẹnì kankan tí ó rí i,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ṣàkíyèsí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò jí, nítorí gbogbo wọ́n sùn, nítorí oorun àsùnwọra+ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ó ti ṣubú lù wọ́n. 13  Nígbà náà ni Dáfídì kọjá lọ sí ìhà kejì , ó sì dúró sí orí òkè ńlá náà ní òkèèrè, àyè tí ó wà láàárín wọn pọ̀ jaburata. 14  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí nahùn pe àwọn ènìyàn náà àti sí Ábínérì ọmọkùnrin Nérì, pé: “Ábínérì, ìwọ kì yóò ha dáhùn bí?” Ábínérì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé: “Ta ni ìwọ tí ó nahùn pe ọba?” 15  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún Ábínérì pé: “Ìwọ kì í ha ṣe ọkùnrin bí? Ta sì ni ó dà bí rẹ ní Ísírẹ́lì? Kí wá ni ìdí tí ìwọ kò fi ṣọ́ olúwa rẹ ọba? Nítorí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn náà wọlé wá láti run ọba olúwa rẹ.+ 16  Ohun tí ìwọ ṣe yìí kò dára. Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ ikú tọ́ sí yín,+ nítorí pé ẹ kò ṣọ́+ olúwa yín, ẹni àmì òróró Jèhófà.+ Wàyí o, ẹ wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba àti ìdẹ̀+ omi tí ó wà ní ibi orí rẹ̀ wà.” 17  Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ohùn Dáfídì mọ̀, ó sì wí pé: “Ṣé ohùn rẹ nìyí, Dáfídì ọmọkùnrin mi?”+ Dáfídì fèsì pé: “Ohùn mi ni, olúwa mi ọba.” 18  Ó sì fi kún un pé: “Kí ló fa èyí tí olúwa mi fi ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀,+ kí ni mo ṣe, ìwà búburú wo ni ó sì wà ní ọwọ́ mi?+ 19  Wàyí o, jọ̀wọ́, kí olúwa mi ọba fetí sí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀: Bí ó bá jẹ́ Jèhófà ni ó ru ọ́ lọ́kàn sókè sí mi, kí ó gbóòórùn ọrẹ ẹbọ ọkà.+ Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ àwọn ọmọ ènìyàn ni,+ ègún ni fún wọn níwájú Jèhófà,+ nítorí pé wọ́n ti lé mi jáde lónìí, kí n má bàa nímọ̀lára pé a so mí pọ̀ mọ́ ogún Jèhófà,+ pé, ‘Lọ, sin àwọn ọlọ́run mìíràn!’+ 20  Wàyí o, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi kán sórí ilẹ̀ níwájú Jèhófà;+ nítorí ọba Ísírẹ́lì ti jáde lọ wá ẹyọ eégbọn kan ṣoṣo,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ti ń lépa àparò ọhẹhẹ lórí àwọn òkè ńlá.”+ 21  Ẹ̀wẹ̀, Sọ́ọ̀lù wí pé: “Èmi ti dẹ́ṣẹ̀.+ Padà wá, Dáfídì ọmọkùnrin mi, nítorí èmi kì yóò ṣe ọ́ ní èṣe mọ́, nítorí òtítọ́ náà pé ọkàn mi ṣe iyebíye+ ní ojú rẹ lónìí yìí. Wò ó! Mo ti hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣàṣìṣe gidigidi.” 22  Nígbà náà ni Dáfídì dáhùn, ó sì wí pé: “Ọ̀kọ̀ ọba rèé, sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́kùnrin ré kọjá wá mú un. 23  Jèhófà sì ni ẹni tí yóò san òdodo+ àti ìṣòtítọ́ olúkúlùkù padà fún un, ní ti pé Jèhófà fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ lónìí, èmi kò sì fẹ́ na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Jèhófà.+ 24  Sì wò ó! gan-an gẹ́gẹ́ bí ọkàn rẹ ti tóbi ní ojú mi lónìí, bẹ́ẹ̀ ni kí ọkàn mi tóbi ní ojú Jèhófà,+ kí ó lè dá mi nídè kúrò nínú gbogbo wàhálà.”+ 25  Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé: “Alábùkún ni ìwọ, Dáfídì ọmọkùnrin mi. Kì í ṣe kìkì pé ìwọ yóò gbé ìgbésẹ̀ láìkùnà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò mókè pẹ̀lú láìkùnà.”+ Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀nà rẹ̀ lọ; àti ní ti Sọ́ọ̀lù, ó padà sí ipò rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé