Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 25:1-44

25  Nígbà tí ó ṣe, Sámúẹ́lì+ kú; gbogbo Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí kóra jọpọ̀, wọ́n sì pohùn réré ẹkún+ fún un, wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀ ní Rámà.+ Nígbà náà ni Dáfídì dìde, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí aginjù Páránì.+  Wàyí o, ọkùnrin kan wà ní Máónì,+ iṣẹ́ rẹ̀ sì ń bẹ ní Kámẹ́lì.+ Ènìyàn ńlá gidigidi sì ni ọkùnrin náà, ó sì ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn àti ẹgbẹ̀rún ewúrẹ́; ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́+ irun àgùntàn rẹ̀ ní Kámẹ́lì.  Orúkọ ọkùnrin náà sì ni Nábálì,+ orúkọ aya rẹ̀ sì ni Ábígẹ́lì.+ Aya náà sì ní ọgbọ́n inú+ dáadáa, ó sì lẹ́wà ní ìrísí, ṣùgbọ́n ọkọ le koko, ó sì burú ní àwọn ìṣe rẹ̀,+ ó sì jẹ́ ọmọ Kálébù.+  Dáfídì sì wá gbọ́ ní aginjù pé Nábálì ń rẹ́+ irun àgùntàn rẹ̀.  Nítorí náà, Dáfídì rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́wàá, Dáfídì sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé: “Ẹ gòkè lọ sí Kámẹ́lì, kí ẹ sì dé ọ̀dọ̀ Nábálì, kí ẹ sì béèrè nípa àlàáfíà+ rẹ̀ ní orúkọ mi.  Èyí sì ni ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún arákùnrin mi, ‘Àlàáfíà fún ọ,+ àlàáfíà sì ni fún agbo ilé rẹ pẹ̀lú, àlàáfíà sì ni fún gbogbo ohun tí o ní.  Wàyí o, mo ti gbọ́ pé o ní àwọn olùrẹ́run. Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ó jẹ́ tìrẹ wà pẹ̀lú wa.+ A kò fì tínà wọn,+ kò sì sí nǹkan kan rárá tí ó jẹ́ tiwọn tí ó hàn pé ó sọnù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n fi wà ní Kámẹ́lì.  Béèrè lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ, wọn yóò sì sọ fún ọ, kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi lè rí ojú rere ní ojú rẹ, nítorí pé ọjọ́ rere ni a wá. Jọ̀wọ́, sáà fi ohun yòówù tí ọwọ́ rẹ bá rí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti fún Dáfídì ọmọkùnrin rẹ.’”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọ̀dọ́kùnrin Dáfídì wá, wọ́n sì bá Nábálì sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dáfídì, wọ́n sì dúró. 10  Látàrí èyí, Nábálì dá àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì lóhùn, ó sì wí pé: “Ta ni Dáfídì,+ ta sì ni ọmọkùnrin Jésè? Ní òde ìwòyí, àwọn ìránṣẹ́ tí ń sá kúrò, olúkúlùkù kúrò níwájú ọ̀gá rẹ̀, ti di púpọ̀.+ 11  Mo ha sì ní láti mú oúnjẹ mi+ àti omi mi àti ẹran mi tí mo pa, tí mo ti kun fún àwọn olùrẹ́run mi, kí n sì fi í fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò tilẹ̀ mọ ibi tí wọ́n ti wá?”+ 12  Látàrí ìyẹn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin Dáfídì yíjú padà ní ọ̀nà wọn, wọ́n sì padà, wọ́n sì wá, wọ́n sì ròyìn fún un ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 13  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì wí fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Kí olúkúlùkù sán idà rẹ̀!”+ Nítorí náà, olúkúlùkù wọn sán idà rẹ̀, Dáfídì pẹ̀lú sì sán idà tirẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè tọ Dáfídì lẹ́yìn, nǹkan bí irínwó ọkùnrin, nígbà tí igba jókòó ti ẹrù àjò.+ 14  Láàárín àkókò yìí, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà ròyìn fún Ábígẹ́lì, aya Nábálì, pé: “Wò ó! Dáfídì rán àwọn ońṣẹ́ láti aginjù láti wá wo àlàáfíà ọ̀gá wa, ṣùgbọ́n ó fi ìkanra sọ̀rọ̀+ sí wọn. 15  Àwọn ọkùnrin náà sì ṣoore fún wa gidigidi, wọn kò sì fì tínà wa, a kò sì pàdánù ẹyọ ohun kan ní gbogbo ọjọ́ tí a fi bá wọn rìn káàkiri nígbà tí a wà ní pápá.+ 16  Ògiri+ ni wọ́n jẹ́ yí wa ká ní òru àti ní ọ̀sán, ní gbogbo ọjọ́ tí a wà pẹ̀lú wọn, tí a ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran. 17  Wàyí o, mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí pé ìyọnu àjálù ni a ti pinnu+ sí ọ̀gá wa àti sí gbogbo ilé rẹ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ àwé tí kò dára fún ohunkóhun+ rárá láti bá sọ̀rọ̀.” 18  Ní kíá, Ábígẹ́lì+ ṣe kánkán, ó sì mú igba ìṣù búrẹ́dì àti ìṣà wáìnì+ títóbi méjì àti àgùntàn márùn-ún tí a ti ṣètò+ àti òṣùwọ̀n séà márùn-ún àyangbẹ+ ọkà àti ọgọ́rùn-ún ìṣù èso àjàrà gbígbẹ+ àti igba ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́,+ ó sì kó wọn sórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 19  Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ máa lọ ṣíwájú mi.+ Wò ó! Èmi ń bọ̀ lẹ́yìn yín.” Ṣùgbọ́n kò sọ nǹkan kan fún Nábálì ọkọ rẹ̀. 20  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé bí ó ti ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ lọ, tí ó sì ń sọ̀ kalẹ̀ ní òkè ńlá náà ní bòókẹ́lẹ́, họ́wù, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ rèé tí wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti wá pàdé rẹ̀. Nítorí náà, ó bá wọn pàdé. 21  Ní ti Dáfídì, ó ti wí pé: “Ìjákulẹ̀ gbáà ni ó já sí pé mo ṣọ́ ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti àwé yìí ní aginjù, kò sì sí ẹyọ ohun kan nínú gbogbo ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ tí ó hàn pé ó sọnù,+ síbẹ̀ ó sì fi ibi san rere padà fún mi.+ 22  Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ṣe sí àwọn ọ̀tá Dáfídì, bẹ́ẹ̀ sì ni kí ó fi kún un+ bí èmi yóò bá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ń tọ̀ sára ògiri+ nínú gbogbo àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀ ṣẹ́ kù títí di òwúrọ̀.”+ 23  Nígbà tí Ábígẹ́lì tajú kán rí Dáfídì, ní kíá, ó ṣe kánkán, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú Dáfídì, ó sì tẹrí ba+ mọ́lẹ̀. 24  Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀,+ ó sì wí pé: “Ìwọ olúwa mi, kí ìṣìnà náà wà lórí èmi gan-an;+ jọ̀wọ́, sì jẹ́ kí ẹrúbìnrin rẹ sọ̀rọ̀ ní etí rẹ,+ sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹrúbìnrin rẹ. 25  Jọ̀wọ́, kí olúwa mi má fi ọkàn-àyà rẹ̀ sí Nábálì ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun+ yìí, nítorí, bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni òun jẹ́. Nábálì ni orúkọ rẹ̀, ìwà òpònú sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ Ní ti èmi ẹrúbìnrin rẹ, èmi kò rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin olúwa mi tí ìwọ rán. 26  Wàyí o, olúwa mi, bí Jèhófà ti ń bẹ+ àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ,+ Jèhófà ti dá ọ dúró+ ní wíwọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀+ àti ní mímú kí ọwọ́ ara rẹ wá ṣe ìgbàlà rẹ.+ Wàyí o, kí àwọn ọtá rẹ àti àwọn tí ń wá ìṣeléṣe fún olúwa mi dà bí Nábálì.+ 27  Wàyí o, ní ti ẹ̀bùn ìbùkún+ yìí tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ti mú wá fún olúwa mi, kí a fi fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ń rìn káàkiri ní ìṣísẹ̀+ olúwa mi. 28  Jọ̀wọ́, dárí ìrélànàkọjá ẹrúbìnrin+ rẹ jì , nítorí pé, láìsí àní-àní, Jèhófà yóò ṣe ilé wíwà pẹ́ títí+ fún olúwa mi, nítorí pé àwọn ogun Jèhófà ni olúwa mi ń jà;+ àti pé ní ti ìwà búburú, a kì yóò rí i nínú rẹ ní gbogbo ọjọ́ rẹ.+ 29  Nígbà tí ènìyàn bá dìde láti lépa rẹ, tí ó sì ń wá ọkàn rẹ, dájúdájú, ọkàn olúwa mi yóò jẹ́ èyí tí a dì sínú àpò ìwàláàyè+ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ;+ ṣùgbọ́n, ní ti ọkàn àwọn ọ̀tá rẹ, òun yóò gbọ̀n ọ́n jáde bí láti inú ìtẹkòtò kànnàkànnà.+ 30  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí tí Jèhófà yóò ṣe ire fún olúwa mi ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ti sọ, dájúdájú, òun yóò fàṣẹ yàn ọ́ ṣe aṣáájú lórí Ísírẹ́lì.+ 31  Má sì jẹ́ kí èyí di okùnfà títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́ rẹ tàbí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún ọkàn-àyà olúwa mi, nípa títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ láìnídìí+ àti nípa mímú kí ọwọ́ olúwa mi fúnra rẹ̀ wá ṣe ìgbàlà ara rẹ̀.+ Dájúdájú, Jèhófà yóò sì ṣe rere fún olúwa mi, kí o sì rántí+ ẹrúbìnrin rẹ.” 32  Látàrí èyí, Dáfídì sọ fún Ábígẹ́lì pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi! 33  Ìbùkún sì ni fún ìlóyenínú rẹ,+ ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀,+ kí n sì mú kí ọwọ́ ara mi wá ṣe ìgbàlà mi.+ 34  Àti pé, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti ń bẹ, tí ó ti dá mi dúró kí n má bàa ṣe ọ́ léṣe,+ bí kì í bá ṣe pé o ṣe kánkán kí o bàa lè wá pàdé mi,+ dájúdájú, kì bá ti ṣẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí ń tọ̀ sára ògiri fún Nábálì di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.”+ 35  Pẹ̀lú ìyẹn, Dáfídì gba ohun tí ó mú wá fún un ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Gòkè lọ sí ilé rẹ ní àlàáfíà.+ Wò ó, mo ti fetí sí ohùn rẹ, kí n lè ní ìgbatẹnirò+ fún ìwọ fúnra rẹ.” 36  Lẹ́yìn náà, Ábígẹ́lì wọlé wá bá Nábálì, sì kíyè sí i, ó ń jẹ àsè ní ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àsè ọba;+ ọkàn-àyà Nábálì sì ń jẹ̀gbádùn nínú rẹ̀, ó sì ti mutí yó+ bìnàkò; obìnrin náà kò sì sọ ohun kan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀, títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀. 37  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀, nígbà tí wáìnì ti dá lójú Nábálì, aya rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún un. Ọkàn-àyà+ rẹ̀ sì kú ní inú rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ sì dà bí òkúta. 38  Lẹ́yìn ìyẹn, nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá kọjá lọ, Jèhófà sì kọlu+ Nábálì, tí ó fi kú. 39  Dáfídì sì wá gbọ́ pé Nábálì ti kú, nítorí náà, ó wí pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà, ẹni tí ó ti bá mi dá ẹjọ́+ ẹ̀gàn mi+ láti gbà mí lọ́wọ́ Nábálì, ó sì ti fa ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò nínú ìwà búburú,+ ìwà búburú Nábálì ni Jèhófà sì ti yí padà sí orí òun tìkára rẹ̀!”+ Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́, ó sì fi ọ̀ràn ìgbéyàwó lọ Ábígẹ́lì láti fẹ́ ẹ ṣe aya rẹ̀.+ 40  Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì wá sọ́dọ̀ Ábígẹ́lì ní Kámẹ́lì, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀, pé: “Dáfídì fúnra rẹ̀ ni ó rán wa wá sọ́dọ̀ rẹ láti mú ọ ṣe aya rẹ̀.” 41  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó dìde, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀,+ ó sì wí pé: “Ẹrúbìnrin rẹ rèé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́bìnrin láti máa wẹ ẹsẹ̀+ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.”+ 42  Nígbà náà ni Ábígẹ́lì+ ṣe kánkán, ó sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gun+ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ, tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin márùn-ún sì ń rìn bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; ó sì ń bá àwọn ońṣẹ́ Dáfídì lọ, ó sì wá di aya rẹ̀. 43  Dáfídì pẹ̀lú ti fẹ́ Áhínóámù+ láti Jésíréélì;+ àwọn obìnrin náà, àní àwọn méjèèjì , sì wá jẹ́ aya rẹ̀.+ 44  Ní ti Sọ́ọ̀lù, ó ti fi Míkálì+ ọmọbìnrin rẹ̀, aya Dáfídì, fún Pálítì+ ọmọkùnrin Láíṣì, tí ó wá láti Gálímù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé