Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 24:1-22

24  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Sọ́ọ̀lù padà kúrò lẹ́yìn àwọn Filísínì,+ wọ́n wá ròyìn fún un, pé: “Wò ó! Dáfídì wà ní aginjù Ẹ́ń-gédì.”+  Sọ́ọ̀lù sì tẹ̀ síwájú láti mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún àṣàyàn ọkùnrin+ nínú gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá Dáfídì+ àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lórí àwọn àpáta dídán borokoto ti àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá.+  Níkẹyìn, ó dé ibi àwọn ọgbà àgùntàn tí a fi òkúta ṣe ní ojú ọ̀nà, níbi tí hòrò kan wà. Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù wọlé láti gbọnsẹ̀,+ nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wà ní ìjókòó ní àwọn apá hòrò+ náà tí ó jì nnà jù lọ lẹ́yìn.  Àwọn ọkùnrin Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Ọjọ́ náà nìyí tí Jèhófà sọ fún ọ ní tòótọ́ pé, ‘Wò ó! Èmi yóò fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́,+ kí o sì ṣe sí i gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti dára ní ojú rẹ.’”+ Nítorí náà, Dáfídì dìde, ó sì rọra gé etí gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí ó jẹ́ ti Sọ́ọ̀lù.  Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé ọkàn-àyà Dáfídì ń gbún un+ ṣáá nítorí ìdí náà pé ó gé etí gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí ó jẹ́ ti Sọ́ọ̀lù.  Nítorí náà, ó wí fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n ṣe ohun yìí sí olúwa mi, ẹni àmì òróró+ Jèhófà, nípa nína ọwọ́ mi lòdì sí i, nítorí pé ẹni àmì òróró Jèhófà ni.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fọ́n àwọn ọkùnrin rẹ̀ ká, kò sì gbà wọ́n láyè láti dìde sí Sọ́ọ̀lù.+ Ní ti Sọ́ọ̀lù, ó dìde kúrò nínú hòrò náà, ó sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.  Nítorí náà, Dáfídì dìde lẹ́yìn ìgbà náà, ó sì jáde kúrò nínú hòrò náà, ó sì nahùn pe Sọ́ọ̀lù, pé: “Olúwa mi+ ọba!” Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù wo ẹ̀yìn rẹ̀, Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba mọ́lẹ̀, ní dídojúbolẹ̀,+ ó sì wólẹ̀.  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Èé ṣe tí o fi ń fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ènìyàn,+ pé, ‘Wò ó! Dáfídì ń wá ìṣelọ́ṣẹ́ rẹ’? 10  Kíyè sí i, ojú rẹ rí i lónìí bí Jèhófà ti fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú hòrò náà; ẹnì kan sì sọ pé kí n pa+ ọ́, ṣùgbọ́n mo káàánú fún ọ, mo sì wí pé, ‘Èmi kì yóò na ọwọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni àmì òróró+ Jèhófà ni.’ 11  Baba mi,+ sì wò ó, bẹ́ẹ̀ ni, wo etí gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá ní ọwọ́ mi, nítorí pé nígbà tí mo gé etí gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá, èmi kò pa ọ́. Mọ̀, kí o sì rí i pé kò sí ìwà búburú+ tàbí ìdìtẹ̀ kankan ní ọwọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ́, bí o ti ń lúgọ de ọkàn mi láti gbà á kúrò.+ 12  Kí Jèhófà ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ìwọ;+ kí Jèhófà sì gbẹ̀san+ fún mi lára rẹ, ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò wá sára rẹ.+ 13  Gan-an gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbàanì ti sọ pé, ‘Ọ̀dọ̀ àwọn ẹni burúkú ni ìwà burúkú yóò ti jáde lọ,’+ ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò wá sára rẹ. 14  Ta ni ọba Ísírẹ́lì ń sáré lé? Ta ni ìwọ ń lépa? Ṣé òkú ajá?+ Ṣé ẹyọ eégbọn kan ṣoṣo?+ 15  Kí Jèhófà sì di onídàájọ́, kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ìwọ, òun yóò sì rí i, yóò sì bá mi dá ẹjọ́+ mi, yóò sì ṣe ìdájọ́ mi láti gbà mí lọ́wọ́ rẹ.” 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní ìṣẹ́jú tí Dáfídì parí sísọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ṣé ohùn rẹ nìyí, Dáfídì ọmọkùnrin mi?”+ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sunkún.+ 17  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ jẹ́ olódodo jù mí lọ,+ nítorí pé ìwọ ni ó ṣe ohun rere sí mi,+ èmi sì ni ẹni tí ó ṣe ibi sí ọ. 18  Ìwọ—ìwọ sì ti sọ ohun rere tí o ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi lónìí ní ti pé Jèhófà fi mí lé ọ lọ́wọ́,+ ìwọ kò sì pa mí. 19  Wàyí o, níbi tí ó ti sẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan rí ọ̀tá rẹ̀, yóò ha rán an lọ lójú ọ̀nà rere bí?+ Nítorí náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò fi rere san án fún ọ,+ nítorí òtítọ́ náà pé o ti ṣe é fún mi lónìí yìí. 20  Wàyí o, wò ó! mo mọ̀ dáadáa pé, laíkùnà, ìwọ yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba,+ àti pé ìjọba Ísírẹ́lì yóò wà pẹ́ títí ní ọwọ́ rẹ dájúdájú. 21  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, fi Jèhófà búra+ fún mi pé ìwọ kì yóò ké irú-ọmọ mi kúrò lẹ́yìn mi, àti pé ìwọ kì yóò pa orúkọ mi rẹ́ ráúráú kúrò ní ilé baba mi.”+ 22  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì búra fún Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn èyí tí Sọ́ọ̀lù lọ sí ilé rẹ̀.+ Ní ti Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, wọ́n gòkè lọ sí ibi tí ó ṣòro láti dé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé