Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 23:1-29

23  Nígbà tí ó ṣe, wọ́n wá ròyìn fún Dáfídì pé: “Kíyè sí i, àwọn Filísínì ń bá Kéílà+ jagun, wọ́n sì ń kó àwọn ilẹ̀ ìpakà ní ìkógun.”+  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ṣé kí n lọ, ṣé kí n sì ṣá àwọn Filísínì wọ̀nyí balẹ̀?” Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà wí fún Dáfídì pé: “Lọ, kí o sì ṣá àwọn Filísínì balẹ̀, kí o sì gba Kéílà là.”  Látàrí èyí, àwọn ọkùnrin Dáfídì wí fún un pé: “Wò ó! Àwa ń fòyà nígbà tí a wà níhìn-ín ní Júdà,+ mélòómélòó ni yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀ bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé a lọ sí Kéílà láti dojú kọ ojú ìlà ogun àwọn Filísínì!”+  Nítorí náà, Dáfídì tún wádìí síbẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.+ Jèhófà dá a lóhùn wàyí, ó sì wí pé: “Dìde, sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Kéílà, nítorí èmi yóò fi àwọn Filísínì lé ọ lọ́wọ́.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì lọ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí Kéílà, ó sì bá àwọn Filísínì jà, ó sì kó ohun ọ̀sìn wọn lọ, ṣùgbọ́n ó fi ìpakúpa rẹpẹtẹ ṣá wọn balẹ̀; Dáfídì sì wá di olùgbàlà àwọn olùgbé Kéílà.+  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Ábíátárì+ ọmọkùnrin Áhímélékì fẹsẹ̀ fẹ lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Kéílà, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ pẹ̀lú éfódì+ kan ní ọwọ́ rẹ̀.  Nígbà tí ó ṣe, a ròyìn fún Sọ́ọ̀lù pé: “Dáfídì ti wá sí Kéílà.”+ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ọlọ́run ti tà á sí ọwọ́ mi,+ nítorí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ nípa wíwá sínú ìlú ńlá tí ó ní àwọn ilẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú.”  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù fi ọlá àṣẹ pe gbogbo àwọn ènìyàn náà sí ogun, láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti sàga ti Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀.  Dáfídì sì wá mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù ń fẹ̀tàn hùmọ ibi+ sí òun. Nítorí náà, ó wí fún Ábíátárì àlùfáà pé: “Mú éfódì sún mọ́ tòsí.”+ 10  Dáfídì sì ń bá a lọ láti wí pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ dájúdájú pé Sọ́ọ̀lù ń wá ọ̀nà láti wá sí Kéílà láti run ìlú ńlá náà ní tìtorí mi.+ 11  Àwọn onílẹ̀ Kéílà yóò ha fi mi lé e lọ́wọ́? Sọ́ọ̀lù yóò ha sọ̀ kalẹ̀ wá gan-an gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́? Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́, sọ fún ìránṣẹ́ rẹ.” Jèhófà fèsì pé: “Yóò sọ̀ kalẹ̀ wá.”+ 12  Dáfídì sì ń bá a lọ láti wí pé: “Àwọn onílẹ̀ Kéílà yóò ha fi èmi àti àwọn ọkùnrin mi lé Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́?” Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà wí pé: “Wọn yóò ṣe ìfilénilọ́wọ́ náà.”+ 13  Ní kíá, Dáfídì dìde pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀ta ọkùnrin,+ wọ́n sì jáde kúrò ní Kéílà, wọ́n sì ń bá a lọ ní rírìn káàkiri ní ibikíbi tí wọ́n bá ti lè rìn káàkiri. A sì ròyìn fún Sọ́ọ̀lù pé Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà, nítorí náà, ó jáwọ́ nínú jíjáde lọ. 14  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní aginjù ní àwọn ibi tí ó ṣòro láti dé, ó sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ní aginjù Sífù.+ Sọ́ọ̀lù sì ń bá a nìṣó ní wíwá a nígbà gbogbo,+ Ọlọ́run kò sì fi í lé e lọ́wọ́.+ 15  Dáfídì sì wà nínú ìbẹ̀rù nítorí pé Sọ́ọ̀lù ti jáde lọ láti wá ọkàn rẹ̀ nígbà tí Dáfídì wà ní aginjù Sífù ní Hóréṣi.+ 16  Jónátánì ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù dìde wàyí, ó sì lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hóréṣì, kí ó bàa lè fún ọwọ́ rẹ̀ lókun+ nípa ti Ọlọ́run.+ 17  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Má fòyà;+ nítorí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́, ìwọ ni yóò sì jẹ ọba+ lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì di igbá-kejì rẹ; Sọ́ọ̀lù baba mi sì mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”+ 18  Nígbà náà ni àwọn méjèèjì jọ dá májẹ̀mú+ níwájú Jèhófà; Dáfídì sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ní Hóréṣì, Jónátánì alára sì lọ sí ilé rẹ̀. 19  Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Sífù+ gòkè lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà,+ wọ́n wí pé: “Dáfídì kò ha fi ara rẹ̀ pa mọ́+ nítòsí wa ní àwọn ibi tí ó ṣòro láti dé ní Hóréṣì,+ lórí òkè kékeré Hákílà,+ èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún Jéṣímónì?+ 20  Nísinsìnyí, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìfàsí ọkàn rẹ,+ ìwọ ọba, láti sọ̀ kalẹ̀, sọ̀ kalẹ̀ wá, ipa tiwa yóò sì jẹ́ láti fi í lé ọba lọ́wọ́.”+ 21  Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù wí pé: “Alábùkún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni yín,+ nítorí ẹ ní ìyọ́nú sí mi. 22  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lọ, ẹ ní ìforítì púpọ̀ sí i, kí ẹ sì wádìí dájú, kí ẹ sì rí ibi tí ó wà, níbi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbé wà—ẹnì yòówù tí ó bá rí i níbẹ̀—nítorí a ti sọ fún mi pé alálùmọ̀kọ́rọ́yí+ gbáà ni òun fuńra rẹ̀ jẹ́. 23  Kí ẹ sì wò, kí ẹ sì wádìí dájú nípa gbogbo ibi ìfarapamọ́ tí ó ń fi ara rẹ̀ pa mọ́ sí; kí ẹ sì padà wá sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀rí, èmi yóò sì bá yín lọ; dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ó bá wà ní ilẹ̀ náà, èmi pẹ̀lú yóò fẹ̀sọ̀ wá a kiri dájúdájú láàárín gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ Júdà.” 24  Nítorí náà, wọ́n dìde, wọ́n sì ṣáájú Sọ́ọ̀lù lọ sí Sífù,+ nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì wà ní aginjù Máónì+ ní Arábà+ sí apá gúúsù Jéṣímónì. 25  Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀ láti wá a.+ Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì, ní kíá, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibi àpáta gàǹgà,+ ó sì ń bá a lọ ní gbígbé ní aginjù Máónì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù wá gbọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa+ Dáfídì lọ sínú aginjù Máónì. 26  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Sọ́ọ̀lù wá sí ẹ̀gbẹ́ ìhín òkè ńlá náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀hún òkè ńlá náà. Nítorí náà, Dáfídì ṣe wéré láti lọ+ nítorí Sọ́ọ̀lù; ní gbogbo àkókò náà, Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ká Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ mọ́ láti gbá wọn mú.+ 27  Ṣùgbọ́n ońṣẹ́ kan wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó wí pé: “Ṣe kánkán, kí o sì lọ, nítorí àwọn Filísínì ti gbé sùnmọ̀mí wá sí ilẹ̀ náà!” 28  Látàrí ìyẹn, Sọ́ọ̀lù yí padà ní lílépa Dáfídì,+ ó sì lọ pàdé àwọn Filísínì. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Àpáta Gàǹgà Àwọn Ìpínyà. 29  Nígbà náà ni Dáfídì bá ọ̀nà rẹ̀ gòkè lọ láti ibẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní àwọn ibi tí ó ṣòro láti dé ní Ẹ́ń-gédì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé