Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 22:1-23

22  Nítorí náà, Dáfídì tẹ̀ síwájú láti lọ láti ibẹ̀,+ ó sì sá lọ+ sí hòrò+ Ádúlámù;+ àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ilé baba rẹ̀ pátá sì wá gbọ́, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ níbẹ̀.  Gbogbo ọkùnrin tí ó wà nínú wàhálà+ àti gbogbo ọkùnrin tí ó ní ẹni tí wọ́n jẹ ní gbèsè+ àti gbogbo ọkùnrin tí ó ní ìkorò ọkàn+ sì bẹ̀rẹ̀ sí kóra jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ ó sì wá jẹ́ olórí lórí wọn;+ nǹkan bí irínwó ọkùnrin sì wá wà pẹ̀lú rẹ̀.  Lẹ́yìn náà, Dáfídì lọ láti ibẹ̀ sí Mísípè ní Móábù, ó sì wí fún ọba Móábù+ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí baba mi àti ìyá mi+ máa gbé pẹ̀lú yín títí èmi yóò fi mọ ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó mú wọn tẹ̀ dó síwájú ọba Móábù, wọ́n sì ń bá a lọ láti máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ pé Dáfídì fi wà ní ibi tí kò ṣeé dé.+  Nígbà tí ó ṣe, Gádì+ wòlíì wí fún Dáfídì pé: “Má ṣe máa bá a nìṣó ní gbígbé ní ibi tí kò ṣeé dé. Lọ, kí ìwọ fúnra rẹ sì wá sí ilẹ̀ Júdà.”+ Nítorí náà, Dáfídì lọ, ó sì wá sí igbó Hérétì.  Sọ́ọ̀lù sì wá gbọ́ pé Dáfídì àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ni a ti ṣàwárí, bí Sọ́ọ̀lù ti jókòó sí Gíbíà lábẹ́ igi támáríkì+ tí ó wà lórí ibi gíga pẹ̀lú ọ̀kọ̀+ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró yí i ká.  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró yí i ká pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Bẹ́ńjámínì. Ọmọkùnrin Jésè+ yóò ha fún gbogbo yín ní pápá àti àwọn ọgbà àjàrà pẹ̀lú?+ Yóò ha yan gbogbo yín ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún?  Nítorí ẹ ti di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun, gbogbo yín, sí mi; kò sì sí ẹnì kankan tí ó sọ ọ́ di mímọ̀ ní etí mi+ nígbà tí ọmọkùnrin tèmi bá ọmọkùnrin Jésè dá májẹ̀mú,+ kò sì sí ẹnì kankan nínú yín tí ó bá mi kẹ́dùn, tí ó sì sọ ọ́ di mímọ̀ ní etí mi pé ọmọkùnrin tèmi ti gbé ìránṣẹ́ tèmi dìde sí mi gẹ́gẹ́ bí olùba ní ibùba bí ó ṣe rí ní òní yìí.”  Látàrí èyí, Dóẹ́gì+ ọmọ Édómù, bí ó ti jẹ́ pé a yàn án sípò lórí àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù, dáhùn, ó sì wí pé: “Mo rí ọmọkùnrin Jésè tí ó wá sí Nóbù sọ́dọ̀ Áhímélékì+ ọmọkùnrin Áhítúbù.+ 10  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà fún un; ó sì fún un ní àwọn ìpèsè oúnjẹ,+ ó sì fún un ní idà+ Gòláyátì tí í ṣe Filísínì.” 11  Ní kíá, ọba ránṣẹ́ pe Áhímélékì ọmọkùnrin Áhítúbù àlùfáà àti gbogbo ilé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ní Nóbù.+ Nítorí náà, gbogbo wọn wá sọ́dọ̀ ọba. 12  Wàyí o, Sọ́ọ̀lù wí pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀, ìwọ ọmọkùnrin Áhítúbù!” ó dáhùn pé: “Èmi nìyí, olúwa mi.” 13  Sọ́ọ̀lù sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Èé ṣe tí ẹ fi di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí mi,+ ìwọ àti ọmọkùnrin Jésè, nípa fífún tí o fún un ní búrẹ́dì àti idà, tí ìṣèwádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run sì wáyé fún un, láti dìde sí mi gẹ́gẹ́ bí olùba ní ibùba bí ó ṣe rí ní òní yìí?”+ 14  Látàrí èyí, Áhímélékì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé: “Lára gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ta ni ó dà bí Dáfídì,+ olùṣòtítọ́,+ àti ọkọ ọmọ+ ọba àti olórí lórí ẹ̀ṣọ́ rẹ, tí a sì bọlá fún ní ilé rẹ?+ 15  Òní ni mo ha bẹ̀rẹ̀ sí wádìí+ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un bí? Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi! Kí ọba má ṣe ka ohunkóhun sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn àti sí gbogbo ilé baba mi pátá, nítorí ìránṣẹ́ rẹ kò mọ ohun kékeré tàbí púpọ̀ nínú gbogbo èyí.”+ 16  Ṣùgbọ́n ọba wí pé: “Áhímélékì, dájúdájú, ìwọ yóò kú,+ ìwọ pẹ̀lú gbogbo ilé baba rẹ.”+ 17  Pẹ̀lú ìyẹn, ọba sọ fún àwọn sárésáré+ tí ó dúró yí i ká pé: “Ẹ yí padà kí ẹ sì fi ikú pa àwọn àlùfáà Jèhófà, nítorí pé ọwọ́ àwọn náà wà pẹ̀lú Dáfídì àti nítorí pé wọ́n mọ̀ pé ó jẹ́ olùfẹsẹ̀fẹ, wọn kò sì sọ ọ́ di mímọ̀ ní etí mi!”+ Àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì fẹ́ na ọwọ́ wọn jáde láti fipá kọlu àwọn àlùfáà Jèhófà.+ 18  Níkẹyìn, ọba wí fún Dóẹ́gì+ pé: “Ìwọ yí padà, kí o sì fipá kọlu àwọn àlùfáà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dóẹ́gì ọmọ Édómù+ yí padà, òun fúnra rẹ̀ sì fipá kọlu àwọn àlùfáà, ní ọjọ́ yẹn, ó sì fi ikú pa+ ọkùnrin márùn-dín-láàádọ́rùn-ún tí ń wọ éfódì+ aṣọ ọ̀gbọ̀. 19  Àní Nóbù+ ìlú ńlá àwọn àlùfáà pàápàá ni ó fi ojú idà kọlù, ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú àti akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn ni ó fi ojú idà kọlù. 20  Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀kan lára ọmọkùnrin Áhímélékì ọmọkùnrin Áhítúbù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ábíátárì,+ sá àsálà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ fẹ láti tẹ̀ lé Dáfídì. 21  Nígbà náà ni Ábíátárì sọ fún Dáfídì pé: “Sọ́ọ̀lù ti pa àwọn àlùfáà Jèhófà.” 22  Látàrí èyí, Dáfídì wí fún Ábíátárì pé: “Mo mọ̀ dáadáa ní ọjọ́ yẹn,+ nítorí pé Dóẹ́gì ọmọ Édómù wà níbẹ̀, pé láìsí àní-àní, yóò sọ fún Sọ́ọ̀lù.+ Èmi fúnra mi ti ṣe àìtọ́ sí gbogbo ọkàn ilé baba rẹ. 23  Sáà máa gbé pẹ̀lú mi. Má fòyà, nítorí ẹnì yòówù tí ń wá ọkàn mi ń wá ọkàn rẹ, nítorí ìwọ jẹ́ ẹni tí ó nílò ìdáàbòbò lọ́dọ̀ mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé