Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 21:1-15

21  Lẹ́yìn náà, Dáfídì wá sí Nóbù,+ sọ́dọ̀ Áhímélékì àlùfáà; Áhímélékì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì nígbà tí ó pàdé Dáfídì, nígbà náà ni ó sì wí fún un pé: “Èé ṣe tí ó fi ṣe ìwọ nìkan, tí kò sì sí ẹnikẹ́ni pẹ̀lú rẹ?”+  Látàrí èyí, Dáfídì wí fún Áhímélékì àlùfáà pé: “Ọba fúnra rẹ̀ paṣẹ fún mi nípa ọ̀ràn kan,+ ó sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohunkóhun rárá nípa ọ̀ràn tí mo rán ọ àti nípa èyí tí mo pa láṣẹ fún ọ.’ Mo sì ti bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin ṣe àdéhùn láti pàdé wọn ní ibi báyìí-báyìí.  Wàyí o, bí ìṣù búrẹ́dì márùn-ún bá wà ní ìkáwọ́ rẹ, sáà fi wọ́n lé mi lọ́wọ́, tàbí ohun yòówù tí a bá lè rí.”+  Ṣùgbọ́n àlùfáà náà dá Dáfídì lóhùn, ó sì wí pé: “Kò sí búrẹ́dì lásán ní ọwọ́ mi, ṣùgbọ́n búrẹ́dì mímọ́ wà;+ kìkì bí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà bá ti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀dá obìnrin,+ ó kéré tán.”  Nítorí náà, Dáfídì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé: “Ṣùgbọ́n ẹ̀dá obìnrin ni a ti pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa bákan náà bí ti tẹ́lẹ̀ rí, nígbà tí mo jáde lọ,+ ẹ̀yà ara àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ mímọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ àfiránni náà fúnra rẹ̀ jẹ́ ṣákálá. Mélòómélòó ni ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ lónìí, nígbà tí ènìyàn ti di mímọ́ nínú ẹ̀yà ara rẹ̀?”  Látàrí ìyẹn, àlùfáà fún un ní ohun tí ó jẹ́ mímọ́,+ nítorí pé kò sí búrẹ́dì níbẹ̀ bí kò ṣe búrẹ́dì àfihàn tí a mú kúrò níwájú Jèhófà+ kí a bàa lè fi ọ̀tun búrẹ́dì síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a mú un kúrò.  Wàyí o, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù wà níbẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí a dá dúró+ níwájú Jèhófà, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Dóẹ́gì+ ọmọ Édómù,+ sàràkí nínú àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ó jẹ́ ti Sọ́ọ̀lù.+  Dáfídì sì ń bá a lọ láti wí fún Áhímélékì pé: “Ṣé kò sí nǹkan kan ní ìkáwọ́ rẹ níhìn-ín ni, bí ọ̀kọ̀ tàbí idà? Nítorí èmi kò mú idà tèmi tàbí àwọn ohun ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé ọ̀ràn ọba náà jẹ́ kánjúkánjú.”  Àlùfáà náà fèsì pé: “Idà Gòláyátì+ ará Filísínì, ẹni tí ìwọ ṣá balẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Éláhì+—òun rèé, tí a fi aṣọ àlàbora wé, lẹ́yìn éfódì.+ Bí ó bá jẹ́ òun ni ìwọ yóò mú fún ara rẹ, mú un, nítorí kò sí òmíràn níhìn-ín yàtọ̀ sí i.” Dáfídì sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kò sí èyí tí ó dà bí rẹ̀. Fi í fún mi.” 10  Nígbà náà ni Dáfídì dìde, ó sì ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀ fẹ+ ní tìtorí Sọ́ọ̀lù ní ọjọ́ yẹn, níkẹyìn, ó dé ọ̀dọ̀ Ákíṣì ọba Gátì.+ 11  Àwọn ìránṣẹ́ Ákíṣì sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé: “Dáfídì ọba+ ilẹ̀ náà ha kọ́ yìí? Kì í ha ṣe ẹni yìí ní wọ́n ń fi ijó+ dáhùn sí, pé, ‘Sọ́ọ̀lù ti ṣá ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀ balẹ̀, Àti Dáfídì ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá tirẹ̀’?”+ 12  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ọkàn-àyà rẹ̀, ó sì fòyà gidigidi+ ní tìtorí Ákíṣì ọba Gátì. 13  Nítorí náà, ó pa orí pípé rẹ̀ dà+ ní ojú wọn,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí asínwín ní ọwọ́ wọn, ó sì ń ṣe àwọn àmì sára àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè, ó sì jẹ́ kí itọ́ rẹ̀ ṣàn sára irùngbọ̀n rẹ̀. 14  Níkẹyìn, Ákíṣì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Kíyè sí i, ẹ rí ọkùnrin tí ń hùwà ayírí. Èé ṣe tí ẹ fi mú un wá sọ́dọ̀ mi? 15  Mo ha nílò àwọn ènìyàn tí ó ti di ayírí, tí ẹ fi mú ẹni yìí wá láti hùwà ayírí lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi? Ó ha yẹ kí ẹni yìí wọ ilé mi bí?”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé