Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 20:1-42

20  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ fẹ+ kúrò ní Náótì ní Rámà. Bí ó ti wù kí ó rí, ó wá, ó sì wá sọ níwájú Jónátánì pé: “Kí ni mo ṣe?+ Kí ni ìṣìnà mi, kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá níwájú baba rẹ, nítorí ó ń wá ọkàn mi?”  Látàrí èyí, ó wí fún un pé: “Kò ṣée ronú kàn!+ Ìwọ kì yóò kú. Wò ó! Baba mi kì yóò ṣe ohun ńlá tàbí ohun kékeré láìsọ ọ́ di mímọ̀ ní etí mi;+ kí sì ni ìdí tí baba mi yóò fi fi ọ̀ràn yìí pa mọ́ fún mi?+ Èyí kò ṣẹlẹ̀.”  Ṣùgbọ́n Dáfídì búra+ ní àfikún, ó sì wí pé: “Dájúdájú, baba rẹ yóò mọ̀ pé mo ti rí ojú rere ní ojú rẹ,+ nítorí náà, yóò sì wí pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí Jónátánì mọ èyí, kí inú rẹ̀ má bàa bàjẹ́.’ Ṣùgbọ́n, ní ti tòótọ́, bí Jèhófà ti ń bẹ,+ bí ọkàn rẹ sì ti ń bẹ,+ nǹkan bí ìṣísẹ̀ kan ni ó wà láàárín èmi àti ikú!”+  Jónátánì sì ń bá a lọ láti sọ fún Dáfídì pé: “Ohun yòówù tí ọkàn rẹ bá sọ ni èmi yóò ṣe fún ọ.”  Látàrí èyí, Dáfídì wí fún Jónátánì pé: “Wò ó! Ọ̀la ni òṣùpá tuntun,+ láìkùnà, ó sì yẹ kí èmi fúnra mi jókòó pẹ̀lú ọba láti jẹun; sì rán mi lọ, èmi yóò sì fi ara mi pa mọ́+ nínú pápá títí di ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ kẹta.  Bí baba rẹ bá lọ nímọ̀lára àìsí níbẹ̀ mi, nígbà náà, kí o wí pé, ‘Dáfídì fi taratara béèrè ìyọ̀ǹda ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́wọ́ mi láti sáré lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ìlú ńlá rẹ̀, nítorí pé ẹbọ ọdọọdún wà níbẹ̀ fún gbogbo ìdílé náà.’+  Bí ó bá jẹ́ pé bí ó ti wí ni pé, ‘Ó dára!’ ó túmọ̀ sí àlàáfíà fún ìránṣẹ́ rẹ. Ṣùgbọ́n bí ó bá lọ bínú pẹ́nrẹ́n, mọ̀ pé ohun búburú ni ó ti pinnu.+  Kí o sì ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ,+ nítorí o ti mú ìránṣẹ́ rẹ wá sínú májẹ̀mú+ Jèhófà pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n bí ìṣìnà bá wà nínú mi,+ fúnra rẹ fi ikú pa mí, nítórí, èé ṣe tí yóò fi jẹ́ ọ̀dọ̀ baba rẹ ni ìwọ yóò mú mi lọ?”  Jónátánì fèsì pé: “Ìyẹn kò ṣée ronú kàn nípa rẹ! Ṣùgbọ́n bí mo bá mọ̀ rárá pé ibi ni baba mi ti pinnu pé kí ó wá sórí rẹ, èmi kò ha ní sọ fún ọ bí?”+ 10  Nígbà náà ni Dáfídì wí fún Jónátánì pé: “Ta ni yóò sọ fún mi bóyá ohun tí baba rẹ yóò fi dá ọ lóhùn le koko?” 11  Ẹ̀wẹ̀, Jónátánì wí fún Dáfídì pé: “Sáà wá, sì jẹ́ kí a jáde lọ sí pápá.” Nítorí náà, àwọn méjèèjì jáde lọ sí pápá. 12  Jónátánì sì ń bá a lọ láti wí fún Dáfídì pé: “Kí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ [jẹ́ ẹlẹ́rìí]+ pé èmi yóò lu baba mi lẹ́nu gbọ́rọ̀ ní ìwòyí ọ̀la, tàbí ní ọ̀túnla, tí inú rẹ̀ bá sì yọ́ sí Dáfídì, nígbà náà, èmi kì yóò ha ránṣẹ́ sí ọ, kí n sì sọ ọ́ di mímọ̀ ní etí rẹ dájúdájú? 13  Bẹ́ẹ̀ ni kí Jèhófà ṣe sí Jónátánì, bẹ́ẹ̀ sì ni kí ó fi kún un,+ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó dára lójú baba mi láti ṣe ibi sí ọ, tí èmi kò sọ ọ́ di mímọ̀ ní etí rẹ ní tòótọ́, kí n sì rán ọ lọ, tí ìwọ kò sì lọ ní àlàáfíà dájúdájú. Kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi.+ 14  Bí èmi bá ṣì wà láàyè,+ ìwọ kì yóò ha, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kì yoo ha ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jehofa sí mi, kí n má bàa kú?+ 15  Àti pé ìwọ kì yóò sì ké inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tìrẹ kúrò ní wíwà pẹ̀lú agbo ilé mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí Jèhófà bá ké àwọn ọ̀tá Dáfídì kúrò, olúkúlùku wọn kúrò ní ojú ilẹ̀, 16  ni a kì yóò ké orúkọ Jónátánì kúrò ní ilé Dáfídì.+ Jèhófà yóò sì béèrè rẹ̀ ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá Dáfídì.” 17  Nítorí náà, Jónátánì tún búra fún Dáfídì nítorí ìfẹ́ rẹ̀ fún un; nítorí pé bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ọkàn ara rẹ̀ ni ó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ 18  Jónátánì sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Ọ̀la ni òṣùpá tuntun,+ dájúdájú, a óò nímọ̀lára àìsí níbẹ̀ rẹ, nítorí pé ìjókòó rẹ yóò ṣófo kalẹ̀. 19  Àti pé, dájúdájú, ní ọjọ́ kẹta, a ó nímọ̀lára àìsí níbẹ̀ rẹ gidigidi; kí o sì wá sí ibi tí o fi ara rẹ pa mọ́+ sí ní ọjọ́ iṣẹ́, kí o sì wà níhìn-ín nítòsí òkúta yìí. 20  Ní tèmi, èmi yóò sì ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ kan rẹ̀, láti rán wọn sí ibi tí mo fẹ́, sí ibi àfojúsùn kan. 21  Sì wò ó! èmi yóò rán ẹmẹ̀wà pé, ‘Lọ, wá àwọn ọfà náà.’ Bí mo bá wí fún ẹmẹ̀wà náà ní pàtó pé, ‘Wò ó! Àwọn ọfà náà wà ní ìhà ìhín rẹ, kó wọn,’ nígbà náà, kí o wá, nítorí pé ó túmọ̀ sí àlàáfíà fún ọ, kò sì sí ọ̀ràn kankan, bí Jèhófà ti ń bẹ.+ 22  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ báyìí ni mo wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin náà pé, ‘Wò ó! Àwọn ọfà náà ṣì jì nnà sí ọ,’ máa lọ, nítorí pé Jèhófà ti rán ọ lọ. 23  Ní ti ọ̀rọ̀ tí a jọ sọ,+ èmi àti ìwọ, họ́wù, kí Jèhófà wà láàárín èmi àti ìwọ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ 24  Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti fi ara rẹ̀ pa mọ́ ní pápá.+ Ó sì wá jẹ́ òṣùpá tuntun, ọba sì mú ìjókòó rẹ̀ nídìí oúnjẹ láti jẹun.+ 25  Ọba sì jókòó sórí ìjókòó rẹ̀ bí ti àtẹ̀yìnwá, sórí ìjókòó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri; Jónátánì sì dojú kọ ọ́, Ábínérì+ sì jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n àyè Dáfídì ṣófo. 26  Sọ́ọ̀lù kò sì sọ ohunkóhun rárá ní ọjọ́ yẹn, nítorí ó wí fún ara rẹ̀ pé: “Ohun kan ti ṣẹlẹ̀ tí kò fi mọ́,+ nítorí pé a kò tíì wẹ̀ ẹ́ mọ́.” 27  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé òṣùpá tuntun, ní ọjọ́ kejì , pé àyè Dáfídì ń bá a lọ ní ṣíṣófo kalẹ̀. Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù wí fún Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí ọmọkùnrin Jésè+ kò fi wá síbi oúnjẹ yálà ní àná tàbí lónìí?” 28  Nítorí náà, Jónátánì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Dáfídì fi taratara béèrè ìyọ̀ǹda ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́wọ́ mi láti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 29  Ó sì ń bá a lọ ní sísọ pé, ‘Jọ̀wọ́, rán mi lọ, nítorí pé a ní ẹbọ ìdílé nínú ìlú ńlá, arákùnrin mi ni ó sì pàṣẹ fún mi. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, bí mo bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n yọ́ lọ, kí n lè rí àwọn arákùnrin mi.’ Ìdí nìyẹn tí kò fi wá síbi tábìlì ọba.” 30  Nígbà náà ni ìbínú+ Sọ́ọ̀lù gbóná sí Jónátánì, ó sì wí fún un pé: “Ìwọ ọmọkùnrin tí ó jẹ́ ti ọlọ̀tẹ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin,+ èmi kò ha mọ̀ dáadáa pé ìwọ ń yan ọmọkùnrin Jésè sí ìtìjú ara rẹ àti sí ìtìjú apá ìkọ̀kọ̀ ìyá rẹ?+ 31  Fún gbogbo ọjọ́ tí ọmọkùnrin Jésè bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀, ìwọ àti ipò ọba rẹ kì yóò fì dí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ránṣẹ́ lọ mú un wá fún mi, nítorí pé yóò kú dandan.”+ 32  Bí ó ti wù kí ó rí, Jónátánì dá Sọ́ọ̀lù baba rẹ̀ lóhùn, ó sì wí fún un pé: “Èé ṣe tí a ó fi fi ikú pa á?+ Kí ni ohun tí ó ṣe?”+ 33  Pẹ̀lú ìyẹn, Sọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ sí i láti fi gún un;+ Jónátánì sì wá mọ̀ pé baba òun ti pinnu láti fi ikú pa Dáfídì.+ 34  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jónátánì dìde kúrò nídìí tábìlì nínú ìgbóná-gbóoru ìbínú,+ kò sì jẹ oúnjẹ ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn òṣùpá tuntun, nítorí a ti bà á nínú jẹ́ ní ti ọ̀ràn Dáfídì,+ nítorí pé baba rẹ̀ tẹ́ ẹ lógo.+ 35  Ó sì ṣẹlẹ̀, ní òwúrọ̀, pé Jónátánì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí pápá ibi tí Dáfídì fi àdéhùn sí,+ ọ̀dọ́ ẹmẹ̀wà kan sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 36  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, sáré, wá àwọn ọfà tí èmi yóò ta.”+ Ẹmẹ̀wà náà sáré, òun fúnra rẹ̀ sì ta ọfà náà láti mú kí ó lọ ré kọjá rẹ̀. 37  Nígbà tí ẹmẹ̀wà náà lọ títí dé ibi tí ọfà tí Jónátánì ta wà, Jónátánì bẹ̀rẹ̀ sí pe ẹmẹ̀wà náà láti ẹ̀yìn, ó sì sọ pé: “Ọfà náà kò ha ṣì jì nnà sí ọ?”+ 38  Jónátánì sì ń bá a lọ láti pe ẹmẹ̀wà náà láti ẹ̀yìn pé: “Ṣe kánkán! Gbé ìgbésẹ̀ kíákíá! Má ṣe dúró jẹ́ẹ́!” Ẹmẹ̀wà Jónátánì sì ń ṣa àwọn ọfà náà nígbà náà, ó sì wá sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. 39  Ní ti ẹmẹ̀wà náà, kò mọ ohunkóhun; kìkì Jónátánì àti Dáfídì fúnra wọn ni ó mọ̀ nípa ọ̀ràn náà. 40  Lẹ́yìn náà, Jónátánì fi àwọn ohun ìjà rẹ̀ fún ẹmẹ̀wà tí ó jẹ́ tirẹ̀, ó sì wí fún un pé: “Lọ, kó wọn lọ sí ìlú ńlá.” 41  Ẹmẹ̀wà náà lọ. Ní ti Dáfídì, ó dìde láti tòsí apá gúúsù. Nígbà náà ni ó dojú bolẹ̀,+ ó sì tẹrí ba nígbà mẹ́ta; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu,+ wọ́n sì ń sunkún fún ara wọn, títí Dáfídì fi sunkún jù lọ.+ 42  Jónátánì sì ń bá a lọ láti sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ ní àlàáfíà,+ níwọ̀n bí àwa méjèèjì ti búra,+ ní orúkọ Jèhófà, pé, ‘Kí Jèhófà fúnra rẹ̀ wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín ọmọ mi àti ọmọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.’”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì dìde, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, Jónátánì alára sì wá sí ìlú ńlá.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé