Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 2:1-36

2  Hánà sì ń bá a lọ láti gbàdúrà,+ ó sì wí pé: “Ọkàn-àyà mi yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà,+ Ìwo mi ni a gbé ga ní tòótọ́ nínú Jèhófà.+ Ẹnu mi ni a mú gbòòrò sí àwọn ọ̀tá mi, Nítorí mo yọ̀ nínú ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ.+  Kò sí ẹnì kankan tí ó jẹ́ mímọ́ bí Jèhófà, nítorí kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;+ Kò sì sí àpáta kan tí ó dà bí Ọlọ́run wa.+  Ẹ má sọ̀rọ̀ lọ́nà ìrera púpọ̀ lápọ̀jù, Ẹ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan jáde lọ láìníjàánu láti ẹnu yín,+ Nítorí Ọlọ́run ìmọ̀ ni Jèhófà,+ Láti ọwọ́ rẹ̀ ni a sì ti ń díwọ̀n ìṣe lọ́nà títọ́.+  Àwọn ọkùnrin alágbára ńlá nínú lílo ọrun kún fún ìpayà,+ Ṣùgbọ́n àwọn tí ń kọsẹ̀ fi ìmí di àmùrè.+  Àwọn tí wọ́n jẹ àjẹyó yóò fi ara wọn háyà nítorí oúnjẹ,+ Ṣùgbọ́n ní ti tòótọ́ ebi ṣíwọ́ pípa àwọn tí ebi ń pa.+ Àní àgàn pàápàá ti bí méje,+ Ṣùgbọ́n okun ti tán nínú obìnrin tí ó ní ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ọmọ.+  Jèhófà jẹ́ Olùpani àti Olùpa ìwàláàyè mọ́,+ Olùmúni sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù,+ Ó sì ń múni gòkè wá.+  Jèhófà jẹ́ Asọnidòtòṣì+ àti Asọnidọlọ́rọ̀,+ Olùrẹniwálẹ̀, àti Agbéniga+ pẹ̀lú,  Olùgbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde kúrò nínú ekuru;+ Láti inú kòtò eérú ni ó ti ń gbé òtòṣì sókè,+ Láti mú kí wọ́n jókòó pẹ̀lú àwọn ọ̀tọ̀kùlú; ìtẹ́ ògo+ ni ó sì ń fún wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.+ Nítorí ti Jèhófà ni àwọn ọwọ̀n ilẹ̀ ayé,+ Ó sì gbé ilẹ̀ eléso lé orí wọn.  Ó ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ẹsẹ̀ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀;+ Ní ti àwọn ẹni burúkú, a pa wọ́n lẹ́nu mọ́ nínú òkùnkùn,+ Nítorí kì í ṣe nípa agbára ni ọwọ́ ènìyàn fi ń mókè.+ 10  Ní ti Jèhófà, àwọn tí ń bá a fà á ni a óò já láyà;+ Yóò sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run.+ Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò ṣe ìdájọ́ àwọn òpin ilẹ̀ ayé,+ Kí ó lè fi okun fún ọba rẹ̀,+ Kí ó lè gbé ìwo ẹni àmì òróró rẹ̀ ga.”+ 11  Nígbà náà ni Ẹlikénà lọ sí Rámà sí ilé rẹ̀; àti ní ti ọmọdékùnrin náà, ó di òjíṣẹ́+ Jèhófà níwájú Élì àlùfáà. 12  Wàyí o, àwọn ọmọkùnrin Élì jẹ́ aláìdára fún ohunkóhun;+ wọn kò ka Jèhófà sí.+ 13  Ní ti ẹ̀tọ́ àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn náà,+ nígbàkigbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń rú ẹbọ, ẹmẹ̀wà àlùfáà a wá pẹ̀lú àmúga oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀, nígbà tí ẹran ń hó lọ́wọ́ gan-an,+ 14  a sì tì í bọ inú bàsíà tàbí ìkòkò ìse-oúnjẹ oníga ìdìmú méjì tàbí òdù tàbí ìkòkò ìse-oúnjẹ oníga ìdìmú kan. Ohunkóhun tí àmúga náà bá mú wá sókè ni àlùfáà ń mú fún ara rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń ṣe nìyẹn ní Ṣílò sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń wá síbẹ̀.+ 15  Bákan náà, kí wọ́n tó mú ọ̀rá rú èéfín rárá,+ ẹmẹ̀wà àlùfáà a wá, a sì wí fún ọkùnrin tí ń rúbọ pé: “Fún mi ní ẹran láti yan fún àlùfáà, kí ó bàa lè jẹ́ pé ẹran tútù ni yóò gbà lọ́wọ́ rẹ kì í ṣe bíbọ̀.”+ 16  Nígbà tí ọkùnrin náà bá wí fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n kọ́kọ́ mú ọ̀rá rú èéfín ná.+ Lẹ́yìn náà, mú ohun yòówù tí ọkàn rẹ bá fà sí fún ara rẹ,”+ òun a wí ní ti tòótọ́ pé: “Rárá, ṣùgbọ́n o gbọ́dọ̀ mú un wá nísinsìnyí; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò ní láti fi ipá mú un!”+ 17  Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹmẹ̀wà náà sì wá pọ̀ gidigidi níwájú Jèhófà;+ nítorí àwọn ọkùnrin náà hùwà àìlọ́wọ̀ sí ọrẹ ẹbọ Jèhófà.+ 18  Sámúẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́+ níwájú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin kan, ó sán éfódì aṣọ ọ̀gbọ̀.+ 19  Bákan náà, ìyá rẹ̀ a ṣe aṣọ àwọ̀lékè kékeré tí kò lápá fún un, a sì mú un gòkè wá fún un láti ọdún dé ọdún nígbà tí ó bá gòkè wá pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ láti rú ẹbọ ọdọọdún.+ 20  Élì sì súre+ fún Ẹlikénà àti aya rẹ̀, ó sì wí pé: “Kí Jèhófà yan ọmọ fún ọ láti ọ̀dọ̀ aya yìí ní ipò ohun tí a wínni, tí a wín Jèhófà.”+ Wọ́n sì lọ sí ipò wọn. 21  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà yí àfiyèsí rẹ̀ sí Hánà,+ tí ó fi lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì .+ Ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní dídàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà.+ 22  Élì sì darúgbó gidigidi, ó sì ti gbọ́+ nípa gbogbo ohun tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ń bá a nìṣó ní ṣíṣe+ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti bí wọ́n ti máa ń sùn ti àwọn obìnrin+ tí ń sìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 23  Ó sì máa ń wí fún wọn pé:+ “Èé ṣe ti ẹ fi ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àwọn nǹkan báwọ̀nyí?+ Nítorí ohun tí mo ń gbọ́ nípa yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn burú.+ 24  Bẹ́ẹ̀ kọ́,+ ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, nítorí pé ìròyìn tí kò dára ni mo ń gbọ́, tí àwọn ènìyàn Jèhófà ń mú kí ó lọ yí ká.+ 25  Bí ènìyàn bá ṣẹ ènìyàn,+ Ọlọ́run yóò parí ìjà fún un;+ ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ Jèhófà ni ènìyàn ṣẹ̀,+ ta ní ń bẹ láti gbàdúrà fún un?”+ Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sí ohùn baba wọn,+ nítorí pé ó wu Jèhófà wàyí láti fi ikú pa wọ́n.+ 26  Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, ó sì túbọ̀ ń jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.+ 27  Ènìyàn Ọlọ́run+ kan sì tọ Élì wá, ó sì wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Èmi kò ha ṣí ara mi payá ní tòótọ́ fún ilé baba ńlá rẹ nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì gẹ́gẹ́ bí ẹrú fún ilé Fáráò?+ 28  Yíyàn ni a sì yàn án fún mi láti inú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì,+ kí ó máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, kí ó sì máa gòkè lọ sórí pẹpẹ mi+ láti mú èéfín ẹbọ rú tùù sókè, kí ó máa wọ éfódì níwájú mi, kí n lè fi gbogbo ọrẹ ẹbọ àfinásun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ilé baba ńlá rẹ.+ 29  Èé ṣe tí ẹ fi ń tàpá sí ẹbọ mi+ àti ọrẹ ẹbọ mi tí mo pa láṣẹ nínú ibùgbé mi,+ o sì ń bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ jù mí lọ nípa fífi èyí tí ó dára jù lọ nínú olúkúlùkù ọrẹ ẹbọ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi+ bọ́ ara yín sanra?+ 30  “‘Ìdí nìyẹn tí àsọjáde Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi jẹ́ pé: “Mo sọ ní tòótọ́ pé, Ní ti ilé rẹ àti ilé baba ńlá rẹ, wọn yóò máa rìn níwájú mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ Ṣùgbọ́n nísinsìnyí àsọjáde Jèhófà ni pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, nítorí pé àwọn tí ń bọlá fún mi+ ni èmi yóò bọlá fún,+ àwọn tí ó sì ń tẹ́ńbẹ́lú mi yóò jẹ́ aláìjámọ́ pàtàkì.”+ 31  Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí èmi yóò gé apá rẹ kúrò dájúdájú àti apá ilé baba ńlá rẹ, tí kì yóò fi sí arúgbó kan nínú ilé rẹ.+ 32  Ní ti tòótọ́, ìwọ yóò sì rí elénìní nínú ibùgbé mi láàárín gbogbo rere tí a ṣe sí Ísírẹ́lì;+ kì yóò sì wá sí arúgbó kan nínú ilé rẹ láé. 33  Síbẹ̀, ọkùnrin kan sì ń bẹ tí í ṣe tìrẹ, tí èmi kì yóò ké kúrò ní wíwà ní ibi pẹpẹ mi, kí ó lè mú kí ojú rẹ kọṣẹ́ àti láti mú kí ọkàn rẹ joro dànù; ṣùgbọ́n iye tí ó pọ̀ jù nínú ilé rẹ ni gbogbo wọn yóò ti ọwọ́ idà ènìyàn kú.+ 34  Èyí sì ni àmì fún ọ tí yóò dé bá àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì:+ Àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan.+ 35  Dájúdájú, èmi yóò sì gbé àlùfáà olùṣòtítọ́ kan dìde fún ara mi.+ Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà mi àti nínú ọkàn mi ni òun yóò ṣe; èmi yóò sì kọ́ ilé wíwà pẹ́ títí kan fún un dájúdájú, òun yóò sì máa rìn níwájú ẹni àmì òróró mi+ nígbà gbogbo dájúdájú. 36  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹ́ kù+ nínú ilé rẹ yóò wá, yóò sì tẹrí ba fún un nítorí sísan owó àti nítorí ìṣù búrẹ́dì ribiti, yóò sì sọ dájúdájú pé: “Jọ̀wọ́, fi mí sí ọ̀kan nínú àwọn ipò iṣẹ́ àlùfáà, kí n lè máa jẹ ẹ̀já búrẹ́dì.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé