Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 19:1-24

19  Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù bá Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa fífi ikú pa Dáfídì.+  Ní ti Jónátánì, ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, ó ní inú dídùn sí Dáfídì púpọ̀púpọ̀.+ Nítorí náà, Jónátánì sọ fún Dáfídì, pé: “Sọ́ọ̀lù baba mi ń wá ọ̀nà láti ṣe ikú pa ọ́. Wàyí o, máa ṣọ́ra, jọ̀wọ́, ní òwúrọ̀, kí o sì wà ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì fi ara rẹ pa mọ́.+  Èmi, ní tèmi, yóò sì jáde lọ, dájúdájú, èmi yóò sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ baba mi ní pápá níbi tí ìwọ yóò wà, èmi fúnra mi yóò sì bá ọ bá baba mi sọ̀rọ̀, dájúdájú, èmi yóò sì rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, èmi yóò sì sọ fún ọ dájúdájú.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jónátánì sọ̀rọ̀ Dáfídì ní dáadáa+ fún Sọ́ọ̀lù baba rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Kí ọba má ṣẹ̀+ sí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí kò ṣẹ̀ ọ́, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì dára gidigidi sí ọ.+  Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi ọkàn rẹ̀ sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀,+ ó sì ṣá Filísínì náà balẹ̀,+ tí ó fi jẹ́ pé Jèhófà ṣe ìgbàlà nláǹlà+ fún gbogbo Ísírẹ́lì. Ìwọ rí i, o sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀. Nítorí náà, èé ṣe tí ìwọ yóò fi ṣẹ̀ sí ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ní mímú kí a ṣe ikú pa+ Dáfídì lórí asán?”+  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù ṣègbọràn sí ohùn Jónátánì, Sọ́ọ̀lù sì búra pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ a kì yóò fi ikú pa á.”  Lẹ́yìn náà, Jónátánì pe Dáfídì, Jónátánì sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún un. Nígbà náà ni Jónátánì mú Dáfídì tọ Sọ́ọ̀lù wá, ó sì ń bá a lọ níwájú rẹ̀ bí ti tẹ́lẹ̀ rí.+  Nígbà tí ó ṣe, ogun tún bẹ́ sílẹ̀, Dáfídì sì jáde ogun, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn Filísínì jà, ó sì fi ìpakúpa rẹpẹtẹ ṣá wọn balẹ̀,+ wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ kúrò níwájú rẹ̀.+  Ẹ̀mí búburú+ ti Jèhófà sì wá bà lé Sọ́ọ̀lù nígbà tí ó jókòó nínú ilé rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, bí Dáfídì ti ń fi ọwọ́ rẹ̀ ta ohun èlò orin. 10  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù wá ọ̀nà láti fi ọ̀kọ̀ gún Dáfídì mọ́ ògiri,+ ṣùgbọ́n ó yẹ̀+ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kúrò níwájú Sọ́ọ̀lù, tí ó fi sọ ọ̀kọ̀ náà wọnú ògiri. Dáfídì alára sì sá lọ, kí ó lè sá àsálà ní òru yẹn.+ 11  Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù rán àwọn ońṣẹ́+ lọ sí ilé Dáfídì láti ṣọ́ ọ, kí wọ́n sì ṣe ikú pa á ní òwúrọ̀;+ ṣùgbọ́n Míkálì aya rẹ̀ sọ fún Dáfídì, pé: “Bí o kò bá jẹ́ kí ọkàn rẹ sá àsálà ní òru òní, lọ́la, ìwọ yóò jẹ́ ọkùnrin tí a fi ikú pa.” 12  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Míkálì mú kí Dáfídì sọ̀ kalẹ̀ gba ojú fèrèsé, kí ó bàa lè lọ, kí ó sì fẹsẹ̀ fẹ, kí ó sì sá àsálà.+ 13  Nígbà náà ni Míkálì mú ère tẹ́ráfímù,+ ó sì fi í sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú, ó sì fi àwọ̀n irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀, lẹ́yìn èyí tí ó fi ẹ̀wù bò ó. 14  Wàyí o, Sọ́ọ̀lù rán àwọn ońṣẹ́ láti mú Dáfídì, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Ó ń ṣàìsàn.”+ 15  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù rán àwọn ońṣẹ́ náà láti lọ rí Dáfídì, pé: “Ẹ gbé e gòkè wá fún mi lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀, kí n lè ṣe ikú pa á.”+ 16  Nígbà tí àwọn ońṣẹ́ náà wọlé, họ́wù, ère tẹ́ráfímù ni ó wà lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú níbẹ̀ àti àwọ̀n irun ewúrẹ́ ní ibi orí rẹ̀. 17  Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù sọ fún Míkálì pé: “Èé ṣe tí o fi ṣe àgálámàṣà+ sí mi báyìí, tí o fi rán ọ̀tá mi+ lọ kí ó lè sá àsálà?” Ẹ̀wẹ̀, Míkálì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Òun fúnra rẹ̀ ni ó sọ fún mi pé, ‘Rán mi lọ! Èé ṣe tí èmi yóò ṣe fi ikú pa ọ́?’” 18  Ní ti Dáfídì, ó fẹsẹ̀ fẹ, ó sì sá àsálà,+ ó sì dé ọ̀dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà.+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un nípa gbogbo ohun tí Sọ́ọ̀lù ti ṣe sí i. Nígbà náà, òun àti Sámúẹ́lì lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Náótì.+ 19  Nígbà tí ó ṣe, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ Sọ́ọ̀lù, pé: “Wò ó! Dáfídì wà ní Náótì ní Rámà.” 20  Ní kíá, Sọ́ọ̀lù rán àwọn ońṣẹ́ láti mú Dáfídì. Nígbà tí wọ́n wá rí i tí àwọn tí ó jẹ́ àgbàlagbà lára àwọn wòlíì ń sọ tẹ́lẹ̀, tí Sámúẹ́lì sì dúró ní àyè rẹ̀ lórí wọn, ẹ̀mí+ Ọlọ́run sì wá bà lé àwọn ońṣẹ́ Sọ́ọ̀lù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hùwà bí wòlíì,+ àwọn pẹ̀lú. 21  Nígbà tí wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán àwọn ońṣẹ́ mìíràn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hùwà bí wòlíì, àwọn pẹ̀lú. Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù tún rán àwọn ońṣẹ́, ọ̀wọ́ kẹta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hùwà bí wòlíì, àwọn pẹ̀lú. 22  Níkẹyìn, òun pẹ̀lú lọ sí Rámà. Nígbà tí ó lọ títí dé ibi ìkùdu ńlá tí ó wà ní Sékù, ó bẹ̀rẹ̀ sí wádìí, ó sì sọ pé: “Ibo ni Sámúẹ́lì àti Dáfídì wà?” Wọ́n fèsì pé: “Níbẹ̀ ní Náótì+ ní Rámà.” 23  Ó sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ nìṣó láti ibẹ̀ lọ sí Náótì ní Rámà, ẹ̀mí+ Ọlọ́run sì wá bà lé e, bẹ́ẹ̀ ni, òun pàápàá, ó sì ń rìn lọ, ó sì ń bá a lọ ní híhùwà bí wòlíì títí ó fi dé Náótì ní Rámà. 24  Òun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ ẹ̀wù ara rẹ̀, ó sì hùwà bí wòlíì níwájú Sámúẹ́lì, òun pẹ̀lú, ó sì ṣubú sílẹ̀ ní ìhòòhò ní gbogbo ọjọ́ yẹn àti ní gbogbo òru yẹn.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi wá ń sọ pé: “Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú ha wà lára àwọn wòlíì bí?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé