Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 18:1-30

18  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ tán, ọkàn Jónátánì+ pàápàá wá fà mọ́+ ọkàn Dáfídì, Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn òun tìkára rẹ̀.+  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù mú un ní ọjọ́ yẹn, kò sì yọ̀ǹda fún un kí ó padà sí ilé baba rẹ̀.+  Jónátánì àti Dáfídì sì tẹ̀ síwájú láti dá májẹ̀mú,+ nítorí tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn òun tìkára rẹ̀.+  Síwájú sí i, Jónátánì bọ́ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí ó wọ̀, ó sì fi í fún Dáfídì, àti ẹ̀wù rẹ̀ pẹ̀lú, àní àti idà rẹ̀ àti ọrun rẹ̀ àti ìgbànú rẹ̀ pàápàá.  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ. Ibikíbi tí Sọ́ọ̀lù bá rán an, òun a hùwà lọ́nà ìmòyemèrò,+ tí Sọ́ọ̀lù fi fi í ṣolórí àwọn ọkùnrin ogun;+ ó sì jọ pé ó dára ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn náà àti ní ojú àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti ń wọlé bọ̀, nígbà tí Dáfídì padà dé láti ibi tí ó ti ṣá àwọn Filísínì balẹ̀, àwọn obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá láti inú gbogbo ìlú ńlá Ísírẹ́lì pẹ̀lú orin+ àti ijó láti pàdé Sọ́ọ̀lù Ọba, pẹ̀lú ìlù tanboríìnì,+ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀+ àti pẹ̀lú gòjé.  Àwọn obìnrin tí ń ṣe ayẹyẹ sì ń bá a nìṣó ní dídáhùn padà pé: “Sọ́ọ̀lù ti ṣá ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀ balẹ̀, Àti Dáfídì ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá tirẹ̀.”+  Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí bínú gidigidi,+ àsọjáde yìí sì burú ní ojú ìwòye rẹ̀, tí ó fi wí pé: “Wọ́n fún Dáfídì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá, ṣùgbọ́n wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún, kìkì ipò ọba sì ni ó kù láti fi fún un!”+  Sọ́ọ̀lù sì ń wo Dáfídì tìfuratìfura láti ọjọ́ yẹn lọ.+ 10  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì + pé, ẹ̀mí búburú ti Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Sọ́ọ̀lù,+ tí ó fi ń ṣe bí wòlíì+ láàárín ilé, bí Dáfídì ti ń fi ọwọ́+ rẹ̀ ta ohun èlò orin, bí àwọn ọjọ́ ìṣáájú; ọ̀kọ̀ sì wà ní ọwọ́ Sọ́ọ̀lù.+ 11  Sọ́ọ̀lù sì ju ọ̀kọ̀+ náà, ó sì wí pé: “Èmi yóò gún Dáfídì àní mọ́ ògiri!”+ ṣùgbọ́n Dáfídì yí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kúrò níwájú rẹ̀, lẹ́ẹ̀mejì .+ 12  Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí fòyà+ Dáfídì nítorí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù.+ 13  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù mú un kúrò ní àwùjọ+ tirẹ̀, ó sì yàn án ṣe olórí ẹgbẹ̀rún fún un; ó sì ń jáde lọ déédéé, ó sì ń wọlé níwájú àwọn ènìyàn náà.+ 14  Dáfídì sì ń bá a lọ ní híhùwà lọ́nà ìmòyemèrò+ nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 15  Sọ́ọ̀lù sì ń rí i pé ó ń hùwà lọ́nà ìmòyemèrò gan-an,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bẹ̀rù rẹ̀. 16  Gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà sì nífẹ̀ẹ́ Dáfídì, nítorí pé ó ń jáde lọ, ó sì ń wọlé níwájú wọn. 17  Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “Mérábù+ ọmọbìnrin mi tí ó dàgbà jù lọ rèé. Òun ni èmi yóò fi fún ọ ṣe aya.+ Kì kì pé kí o fi ara rẹ hàn ní akíkanjú ènìyàn fún mi, kí o sì máa ja àwọn ogun Jèhófà.”+ Ṣùgbọ́n ní ti Sọ́ọ̀lù, ó sọ fún ara rẹ̀ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ mi wá sára rẹ̀, ṣùgbọ́n ọwọ́ àwọn Filísínì ni kí ó wá sára rẹ̀.”+ 18  Látàrí èyí, Dáfídì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ta ni mí, ta sì ni àwọn ẹbí mi, ìdílé baba mi, ní Ísírẹ́lì, tí èmi yóò fi di ọkọ ọmọ ọba?”+ 19  Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣẹlẹ̀ pé ní àkókò fífi Mérábù, ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, fún Dáfídì, òun alára ni a ti fi fún Ádíríélì,+ tí í ṣe Méhólátì,+ láti fi í ṣe aya. 20  Wàyí o, Míkálì,+ ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gidigidi, wọ́n sì lọ ròyìn rẹ̀ fún Sọ́ọ̀lù, ọ̀ran náà sì jẹ́ dídùn inú rẹ̀. 21  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Èmi yóò fi í fún un, kí ó lè jẹ́ ìdẹkùn fún un,+ àti pé kí ọwọ́ àwọn Filísínì lè wá sára rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “Nípasẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn obìnrin méjèèjì ni ìwọ yóò bá mi dána lónìí.” 22  Síwájú sí i, Sọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá Dáfídì sọ̀rọ̀ ní bòókẹ́lẹ́ pé, ‘Wò ó! Ọba ti ní inú dídùn sí ọ, gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ pàápàá sì ti kó sínú ìfẹ́ fún ọ. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, bá ọba dána.’” 23  Àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní etí Dáfídì, ṣùgbọ́n Dáfídì sọ pé: “Ṣé ohun tí ó rọrùn ni lójú yín láti bá ọba dána, nígbà tí mo jẹ́ ọkùnrin aláìnílọ́wọ́+ àti ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí?”+ 24  Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù ròyìn fún un, pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ bí èyí ni Dáfídì sọ.” 25  Látàrí ìyẹn, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Èyí ni ohun tí ẹ ó sọ fún Dáfídì, ‘Kì í ṣe owó ìgbéyàwó+ ni ọba ní inú dídùn sí bí kò ṣe ọgọ́rùn-ún adọ̀dọ́+ àwọn Filísínì, láti gbẹ̀san+ ara rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá ọba.’” Ṣùgbọ́n ní ti Sọ́ọ̀lù, ó ti pète-pèrò láti mú kí Dáfídì ṣubú láti ọwọ́ àwọn Filísínì. 26  Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ròyìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Dáfídì, ọ̀ràn náà sì jẹ́ dídùn inú Dáfídì, láti bá ọba dána,+ àwọn ọjọ́ náà kò sì tíì parí. 27  Nítorí náà, Dáfídì dìde, òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì lọ, wọ́n sì ṣá+ igba ọkùnrin balẹ̀ lára àwọn Filísínì, Dáfídì sì mú adọ̀dọ́+ wọn wá, ó sì fi wọ́n fún ọba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye, láti bá ọba dána. Ẹ̀wẹ̀, Sọ́ọ̀lù fi Míkálì ọmọbìnrin rẹ̀ fún un ṣe aya.+ 28  Sọ́ọ̀lù sì wá rí i, ó sì mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú Dáfídì.+ Ní ti Míkálì, ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ 29  Sọ́ọ̀lù sì tún ní ìbẹ̀rù púpọ̀ sí i nítorí Dáfídì, Sọ́ọ̀lù sì wá jẹ́ ọ̀tá Dáfídì nígbà gbogbo.+ 30  Àwọn ọmọ aládé+ Filísínì a sì jáde lọ, a sì ṣẹlẹ̀ pé nígbàkúùgbà tí wọ́n bá jáde lọ Dáfídì a hùwà lọ́nà ìmòyemèrò+ jù lọ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù; orúkọ rẹ̀ sì wá ṣe iyebíye gidigidi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé