Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 17:1-58

17  Àwọn Filísínì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ibùdó wọn jọpọ̀ fún ogun. Nígbà tí a kó wọn jọpọ̀ sí Sókóhì,+ èyí tí ó jẹ́ ti Júdà, nígbà náà ni wọ́n dó sáàárín Sókóhì àti Ásékà,+ ní Efesi-dámímù.+  Ní ti Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, wọ́n kó ara wọn jọpọ̀, wọ́n sì dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Éláhì,+ wọ́n sì tẹ́ ìtẹ́gun láti pàdé àwọn Filísínì.  Àwọn Filísínì sì dúró lórí òkè ńlá ní ìhà ìhín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró lórí òkè ńlá ní ìhà ọ̀hún, àfonífojì sì wà láàárín wọn.  Akọgun kan sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti àwọn ibùdó àwọn Filísínì, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gòláyátì,+ láti Gátì,+ gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.+  Àṣíborí bàbà sì wà ní orí rẹ̀, ó sì gbé ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin+ ṣe wọ̀, èyí tí ó ní àwọn ìpẹ́ agbẹ́nuléra, ìwọ̀n ẹ̀wù náà tí a fi àdàrọ irin ṣe sì jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣékélì bàbà.  Kóbìtà bàbà sì wà lókè ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ẹ̀ṣín+ bàbà láàárín àwọn èjì ká rẹ̀.  Ẹ̀rú igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì dà bí ìtì igi àwọn olófì,+ abẹ ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ṣékélì irin; ẹni tí ó gbé apata ńlá sì ń lọ níwájú rẹ̀.  Nígbà náà ni ó dúró jẹ́ẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí náhùn jáde sí ìlà ogun Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi jáde wá láti tẹ́ ìtẹ́gun? Kì í ha ṣe èmi ni Filísínì náà, tí ẹ̀yin sì jẹ́ ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù?+ Ẹ yan ọkùnrin kan fún ara yín, kí ẹ sì jẹ́ kí ó sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ mí wá.  Bí ó bá lè bá mi jà, tí ó sì ṣá mi balẹ̀, nígbà náà, àwa yóò di ìránṣẹ́ fún yín. Ṣùgbọ́n bí èmi fúnra mi bá figẹ̀ wọngẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí mo sì ṣá a balẹ̀, ẹ̀yin pẹ̀lú yóò di ìránṣẹ́ fún wa, ẹ ó sì máa sìn wá.”+ 10  Filísínì náà sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Èmi fúnra mi ṣáátá+ ìlà ogun Ísírẹ́lì lónìí yìí. Ẹ fún mi ní ọkùnrin kan, kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ jà!”+ 11  Nígbà tí Sọ́ọ̀lù+ àti gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí Filísínì náà sọ, àyà wọ́n já, wọ́n sì fòyà gidigidi.+ 12  Wàyí o, Dáfídì jẹ́ ọmọkùnrin ará Éfúrátà+ yìí láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésè. Ó sì ní ọmọkùnrin mẹ́jọ.+ Ní àwọn ọjọ́ Sọ́ọ̀lù, ọkùnrin náà sì ti darúgbó láàárín àwọn ènìyàn. 13  Àwọn mẹ́ta tí ó dàgbà jù lọ nínú àwọn ọmọkùnrin Jésè sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ. Wọ́n tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù lọ sí ogun,+ orúkọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó lọ sí ogun náà sì ni Élíábù+ àkọ́bí, àti Ábínádábù+ ọmọkùnrin rẹ̀ èkejì àti Ṣámáhì+ ẹ̀kẹta. 14  Dáfídì sì ni àbíkẹ́yìn,+ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó dàgbà jù lọ sì tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù. 15  Dáfídì máa ń lọ, ó sì máa ń padà láti ọ̀dọ̀ Sọ́ọ̀lù láti ṣètọ́jú àgùntàn+ baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. 16  Filísínì náà sì ń bá a nìṣó ní jíjáde wá síwájú ní òwúrọ̀ kùtùkùtù àti ní ìrọ̀lẹ́, ó sì mú ìdúró rẹ̀ fún ogójì ọjọ́. 17  Nígbà náà ni Jésè wí fún Dáfídì ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, kó òṣùwọ̀n eéfà àyangbẹ ọkà+ yìí àti ìṣù búrẹ́dì mẹ́wàá wọ̀nyí lọ fún àwọn arákùnrin rẹ, tètè gbé wọn lọ sí ibùdó fún àwọn arakùnrin rẹ. 18  Kí o sì mú wàrà wọ̀nyí tí a pín sí ìpín mẹ́wàá lọ fún olórí ẹgbẹ̀rún;+ pẹ̀lúpẹ̀lù, kí o bójú tó àwọn arákùnrin rẹ ní ti àlàáfíà wọn,+ kí o sì gba àmì ìdánilójú kan bọ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn.” 19  Láàárín àkókò yìí, Sọ́ọ̀lù àti àwọn àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yòókù wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Éláhì,+ wọ́n ń bá àwọn Filísínì jà.+ 20  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì fi àwọn àgùntàn sílẹ̀ sábẹ́ àbójútó olùtọ́jú, ó sì kó àwọn ìpèsè náà, ó sì lọ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésè ti pàṣẹ fún un.+ Nígbà tí ó dé gbàgede ibùdó,+ àwọn ẹgbẹ́ ológun ń jáde lọ síbi ìlà ogun,+ wọ́n sì kígbe sókè fún ìjà ogun náà. 21  Ísírẹ́lì àti àwọn Filísínì sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ ìlà ogun láti pàdé ìlà ogun. 22  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì fi ẹrù àjò+ náà sílẹ̀ sábẹ́ àbójútó olùtọ́jú ẹrù àjò,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ síbi ìlà ogun. Nígbà tí ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí béèrè nípa àlàáfíà àwọn arákùnrin rẹ̀.+ 23  Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, họ́wù, kíyè sí i, akọgun náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gòláyátì,+ tí í ṣe Filísínì náà láti Gátì,+ ń gòkè bọ̀ láti ìlà ogun àwọn Filísínì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà bí ti ìṣáájú,+ Dáfídì sì fetí sí i. 24  Ní ti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì, nígbà tí wọ́n rí ọkùnrin náà, họ́wù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ ní tìtorí rẹ̀, wọ́n sì fòyà gidigidi.+ 25  Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ẹ ha rí ọkùnrin tí ń gòkè bọ̀ yìí? Nítorí àtiṣáátá+ Ísírẹ́lì ni ó fi ń gòkè bọ̀. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ọkùnrin tí ó bá ṣá a balẹ̀, ọba yóò fi ọrọ̀ ńláǹlà sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀, yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún un,+ ilé baba rẹ̀ ni yóò sì dá sílẹ̀ lómìnira ní Ísírẹ́lì.”+ 26  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó dúró nítòsí rẹ̀ pé: “Kí ni ohun tí a ó ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá ṣá Filísínì+ náà tí ó wà níbẹ̀ yẹn balẹ̀, tí ó sì yí ẹ̀gàn kúrò lórí Ísírẹ́lì ní ti tòótọ́?+ Nítorí ta ni Filísínì aláìdádọ̀dọ́+ yìí jẹ́ tí yóò fi máa ṣáátá+ àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè?”+ 27  Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà gẹ́gẹ́ bí ti ìṣáájú fún un, pé: “Bí a ó ti ṣe nìyí fún ọkùnrin náà tí ó bá ṣá a balẹ̀.” 28  Élíábù+ arákùnrin rẹ̀ tí ó dàgbà jù lọ sì wá gbọ́ bí ó ti ń bá àwọn ọkùnrin náà sọ̀rọ̀, ìbínú Élíábù sì gbóná sí Dáfídì,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi sọ pé: “Èé ṣe tí o fi sọ̀ kalẹ̀ wá? Abẹ́ àbójútó ta ni o sì fi ìwọ̀nba àwọn àgùntàn wọnnì sílẹ̀ sí ní aginjù?+ Èmi alára mọ ìkùgbù rẹ àti búburú ọkàn-àyà rẹ+ dáadáa, nítorí pé o ti sọ̀ kalẹ̀ wá fún ète àtirí ìjà ogun náà.”+ 29  Dáfídì fèsì pé: “Kí ni mo tíì ṣe báyìí? Kì í ha ṣe ọ̀rọ̀ kan lásán ni bí?”+ 30  Pẹ̀lú ìyẹn, ó yí padà kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí ẹlòmíràn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ kan náà bí ti ìṣáájú,+ ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn náà sì fún un ní èsì bí ti tẹ́lẹ̀ rí.+ 31  Nítorí náà, a wá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ, wọ́n sì lọ sọ ọ́ níwájú Sọ́ọ̀lù. Fún ìdí yìí ó mú kí ó wá. 32  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà ọkùnrin èyíkéyìí rẹ̀wẹ̀sì nínú rẹ̀.+ Ìránṣẹ́ rẹ fúnra rẹ̀ yóò lọ, yóò sì bá Filísínì yìí jà ní ti tòótọ́.”+ 33  Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ kò lè lọ bá Filísínì yìí láti bá a jà,+ nítorí ọmọdékùnrin lásán-làsàn ni ọ́,+ òun sì jẹ́ ọkùnrin ogun láti ìgbà ọmọdékùnrin rẹ̀.” 34  Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ìránṣẹ́ rẹ di olùṣọ́ àgùntàn baba rẹ̀ láàárín agbo ẹran, kìnnìún kan sì wá,+ àti béárì kan pẹ̀lú, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé àgùntàn lọ nínú agbo ẹran ọ̀sìn. 35  Mo sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, mo sì ṣá a balẹ̀,+ mo sì gbà á sílẹ̀ ní ẹnu rẹ̀. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí dìde sí mi, mo rá irùngbọ̀n rẹ̀ mú, mo sì ṣá a balẹ̀, mo sì fi ikú pa á. 36  Àti kìnnìún àti béárì náà ni ìránṣẹ́ rẹ ṣá balẹ̀; Filísínì aláìdádọ̀dọ́+ yìí yóò sì dà bí ọ̀kan nínú wọn, nítorí ó ti ṣáátá+ àwọn ìlà ogun+ Ọlọ́run alààyè.”+ 37  Dáfídì wá fi kún un pé: “Jèhófà, ẹni tí ó dá mi nídè kúrò ní àtẹ́sẹ̀ kìnnìún náà àti kúrò ní àtẹ́sẹ̀ béárì náà, òun ni ẹni tí yóò dá mi nídè kúrò ní ọwọ́ Filísínì yìí.”+ Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ, kí Jèhófà fúnra rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ.”+ 38  Wàyí o, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀wù rẹ̀ wọ Dáfídì, ó sì fi àṣíborí bàbà dé e ní orí, lẹ́yìn èyí tí ó gbé ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe wọ̀ ọ́. 39  Nígbà náà ni Dáfídì sán idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó sì dáwọ́ lé àtilọ [ṣùgbọ́n kò lè lọ], nítorí pé kò tíì dán wọn wò rí. Níkẹyìn, Dáfídì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Èmi kò lè wọ nǹkan wọ̀nyí lọ, nítorí èmi kò tíì dán wọn wò rí.” Nítorí náà, Dáfídì bọ́ wọn kúrò.+ 40  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú ọ̀pá rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yan òkúta márùn-ún tí ó jọ̀lọ̀ jù lọ fún ara rẹ̀ láti inú àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, ó sì fi wọ́n sínú àpò olùṣọ́ àgùntàn rẹ̀ tí ó ń lò gẹ́gẹ́ bí ìkóhunsí, kànnàkànnà+ rẹ̀ sì wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ Filísínì náà. 41  Filísínì náà sì ń bọ̀, ó túbọ̀ ń sún mọ́ Dáfídì sí i, ọkùnrin tí ó gbé apata ńlá sì wà níwájú rẹ̀. 42  Wàyí o, nígbà tí Filísínì náà wò, tí ó sì rí Dáfídì, ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú+ rẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọmọdékùnrin+ àti apọ́nbéporẹ́,+ tí ó lẹ́wà ní ìrísí.+ 43  Nípa báyìí, Filísínì náà sọ fún Dáfídì pé: “Ṣé ajá+ ni mí, tí ìwọ fi ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ọ̀pá?” Pẹ̀lú ìyẹn, Filísínì náà fi àwọn ọlọ́run rẹ̀ pe ibi sọ̀ kalẹ̀ wá sórí Dáfídì.+ 44  Filísínì náà sì ń bá a lọ láti sọ fún Dáfídì pé: “Sáà máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko inú pápá.”+ 45  Ẹ̀wẹ̀, Dáfídì sọ fún Filísínì náà pé: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín,+ ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá.+ 46  Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́,+ dájúdájú, èmi yóò sì ṣá ọ balẹ̀, èmi yóò sì mú orí rẹ kúrò lára rẹ; dájúdájú, èmi yóò sì fi àwọn òkú ibùdó àwọn Filísínì fún àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run lónìí yìí àti fún àwọn ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé;+ àwọn ènìyàn gbogbo ilẹ̀ ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì.+ 47  Gbogbo ìjọ yìí yóò sì mọ̀ pé kì í ṣe idà tàbí ọ̀kọ̀ ni Jèhófà fi ń gbani là,+ nítorí pé ti Jèhófà ni ìjà ogun náà,+ òun yóò sì fi yín lé wa lọ́wọ́.”+ 48  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, Filísínì náà dìde, ó sì ń bọ̀, ó sì túbọ̀ ń sún mọ́ tòsí láti pàdé Dáfídì, Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe wéré, ó sì ń sáré lọ síhà ìlà ogun láti pàdé Filísínì náà.+ 49  Nígbà náà ni Dáfídì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àpò rẹ̀, ó sì mú òkúta kan níbẹ̀, ó sì gbọ̀n ọ́n, tí ó fi ba+ Filísínì náà ní iwájú orí, òkúta náà sì wọ iwájú orí rẹ̀ lọ, ó sì ṣubú ní ìdojúbolẹ̀ sórí ilẹ̀.+ 50  Nítorí náà, Dáfídì, pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, lágbára ju Filísínì náà, ó sì ṣá Filísínì náà balẹ̀, ó sì fi ikú pa á; kò sì sí idà ní ọwọ́ Dáfídì.+ 51  Dáfídì sì ń bá a lọ ní sísáré, ó sì wá dúró lórí Filísínì náà. Nígbà náà ni ó mú idà rẹ̀,+ ó sì fà á yọ nínú àkọ̀ rẹ̀, ó sì fi ikú pa á pátápátá nígbà tí ó fi í gé orí rẹ̀ kúrò.+ Àwọn Filísínì sì wá rí i pé alágbára ńlá wọ́n ti kú, wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ.+ 52  Látàrí ìyẹn, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti ti Júdà dìde, wọ́n sì hó yèè, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa+ àwọn Filísínì títí lọ dé àfonífojì + àti títí dé àwọn ẹnubodè Ékírónì,+ àwọn tí ó gbọgbẹ́ lọ́nà tí ó lè yọrí sí ikú nínú àwọn Filísínì ń bá a nìṣó ní ṣíṣubú lójú ọ̀nà láti Ṣááráímù,+ títí dé Gátì àti títí dé Ékírónì. 53  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà kúrò nínú lílépa àwọn Filísínì kíkankíkan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ibùdó wọn ní ìkógun.+ 54  Nígbà náà ni Dáfídì gbé orí+ Filísínì náà, ó sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, àwọn ohun ìjà rẹ̀ ni ó sì fi sínú àgọ́ rẹ̀.+ 55  Wàyí o, ní ìṣẹ́jú tí Sọ́ọ̀lù rí Dáfídì tí ń jáde lọ pàdé Filísínì náà, ó sọ fún Ábínérì+ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun pé: “Ábínérì, ọmọkùnrin+ ta ni+ ọmọdékùnrin yìí?” Ábínérì fèsì pé: “Nípa ìwàláàyè ọkàn rẹ, ìwọ ọba, èmi kò mọ̀ rárá!” 56  Nítorí náà, ọba sọ pé: “Ìwọ wádìí nípa ọmọkùnrin ẹni tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà jẹ́.” 57  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbàrà tí Dáfídì padà láti ibi tí ó ti ṣá Filísínì náà balẹ̀, Ábínérì sì mú un wá síwájú Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú orí+ Filísínì náà ní ọwọ́ rẹ̀. 58  Wàyí o, Sọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Ọmọkùnrin ta ni ọ́, ọmọdékùnrin?” Dáfídì fèsì pé: “Ọmọkùnrin Jésè+ ìránṣẹ́ rẹ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé