Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 16:1-23

16  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà wí fún Sámúẹ́lì pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù,+ nígbà tí ó jẹ́ pé èmi, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ti kọ̀ ọ́ láti máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì?+ Fi òróró kún ìwo rẹ,+ kí o sì lọ. Èmi yóò rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè+ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí pé mo ti pèsè ọba fún ara mi lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.”+  Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì sọ pé: “Báwo ni mo ṣe lè lọ? Gbàrà tí Sọ́ọ̀lù bá gbọ́ nípa rẹ̀, dájúdájú yóò pa mí.”+ Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Mú ẹgbọrọ abo màlúù kan láti inú ọ̀wọ́ ẹran dání, ìwọ yóò sì sọ pé, ‘Láti rúbọ sí Jèhófà ni ìdí tí mo fi wá.’+  Kí o sì pe Jésè síbi ẹbọ náà; èmi, ní tèmi, yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe di mímọ̀ fún ọ,+ kí o sì bá mi fòróró yan+ ẹni tí mo bá tọ́ka sí fún ọ.”  Sámúẹ́lì sì tẹ̀ síwájú láti ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Nígbà tí ó dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá náà bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì+ bí wọ́n ti pàdé rẹ̀, nítorí náà, wọ́n wí pé: “Wíwá rẹ ha túmọ̀ sí àlàáfíà bí?”+  Ó fèsì pé: “Ó túmọ̀ sí àlàáfíà. Láti rúbọ sí Jèhófà ni ìdí tí mo fi wá. Ẹ sọ ara yín di mímọ́,+ kí ẹ sì bá mi lọ síbi ẹbọ náà.” Nígbà náà ni ó sọ Jésè àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ di mímọ́, lẹ́yìn èyí tí ó pè wọ́n síbi ẹbọ náà.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ṣe wọlé, tí ó sì tajú kán rí Élíábù,+ ní kíá, ó sọ pé: “Dájúdájú, ẹni àmì òróró rẹ̀ wà níwájú Jèhófà.”  Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ní ìdúró,+ nítorí pé èmi ti kọ̀ ọ́. Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan [ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan],+ nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú;+ ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà+ jẹ́.”  Nígbà náà ni Jésè pe Ábínádábù,+ ó sì jẹ́ kí ó kọjá níwájú Sámúẹ́lì, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Jèhófà kò yan ẹni yìí pẹ̀lú.”  Tẹ̀ lé e Jésè mú kí Ṣámáhì+ kọjá, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Jèhófà kò yan ẹni yìí pẹ̀lú.” 10  Nítorí náà, Jésè mú kí méje nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọjá níwájú Sámúẹ́lì; síbẹ̀ Sámúẹ́lì sọ fún Jésè pé: “Jèhófà kò yan àwọn wọ̀nyí.” 11  Níkẹyìn, Sámúẹ́lì sọ fún Jésè pé: “Gbogbo àwọn ọmọdékùnrin náà ha nìyí bí?” Ó fèsì pé: “Èyí àbíkẹ́yìn ni ó ṣẹ́ kù títí di ìsinsìnyí,+ sì wò ó! ó ń kó àwọn àgùntàn jẹ koríko.”+ Látàrí ìyẹn, Sámúẹ́lì sọ fún Jésè pé: “Ránṣẹ́ lọ wá a wá, nítorí pé a kì yóò jókòó láti jẹun títí di ìgbà tí yóò fi dé ìhín.” 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ránṣẹ́, ó sì mú kí ó wá. Wàyí o, ó jẹ́ apọ́nbéporẹ́,+ ọ̀dọ́kùnrin kan tí ojú rẹ̀ lẹ́wà, ó sì rẹwà ní ìrísí. Nígbà náà ni Jèhófà sọ pé: “Dìde, fòróró yàn án, nítorí pé òun nìyí!”+ 13  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sámúẹ́lì mú ìwo òróró,+ ó sì fòróró yàn án láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Dáfídì láti ọjọ́ yẹn lọ.+ Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì dìde, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí Rámà.+ 14  Ẹ̀mí ti Jèhófà sì lọ kúrò+ lára Sọ́ọ̀lù, ẹ̀mí búburú+ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà sì ń kó ìpayà bá a. 15  Àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, ẹ̀mí búburú ti Ọlọ́run ń kó ìpayà bá ọ. 16  Jọ̀wọ́, jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ó wà níwájú rẹ pé kí wọ́n wá ọkùnrin tí ó jẹ́ ọ̀jáfáfá+ nínú títa háàpù.+ Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ẹ̀mí búburú ti Ọlọ́run bá bà lé ọ, òun yóò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ta á, dájúdájú, nǹkan yóò sì lọ dáadáa fún ọ.” 17  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ pèsè ọkùnrin kan fún mi tí ó ń ṣe dáadáa ní títa háàpù, kí ẹ sì mú un tọ̀ mí wá.”+ 18  Ọ̀kan nínú àwọn ẹmẹ̀wà náà sì tẹ̀ síwájú láti dáhùn, ó sì wí pé: “Wò ó! Mo ti rí bí ọmọkùnrin kan tí ó jẹ́ ti Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú títa háàpù,+ ó sì jẹ́ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin+ àti ọkùnrin ogun+ àti olùbánisọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ onílàákàyè+ àti ọkùnrin tí ó dára délẹ̀,+ Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.”+ 19  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù rán àwọn ońṣẹ́ sí Jésè pé: “Fi Dáfídì ọmọkùnrin rẹ, tí ó wà pẹ̀lú agbo ẹran, ránṣẹ́ sí mi.”+ 20  Nítorí náà, Jésè mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, oúnjẹ àti ìgò awọ+ wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ nípa ọwọ́ Dáfídì ọmọkùnrin rẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù.+ 21  Bí Dáfídì ṣe wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù nìyẹn, tí ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un;+ ó sì wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi, ó sì wá di arùhámọ́ra rẹ̀.+ 22  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù ránṣẹ́ sí Jésè, pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Dáfídì máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, nítorí pé ó ti rí ojú rere ní ojú mi.” 23  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá bà lé Sọ́ọ̀lù, Dáfídì a mú háàpù, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ ta á; ìtura a sì wà fún Sọ́ọ̀lù, nǹkan a sì máa lọ dáadáa fún un, ẹ̀mí búburú náà a sì lọ kúrò lára rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé