Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 15:1-35

15  Nígbà náà ni Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Èmi ni ẹni tí Jèhófà rán láti fòróró yàn+ ọ́ ṣe ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì, wàyí o, fetí sí ohùn àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà.+  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ wí, ‘Èmi yóò béèrè fún ìjíhìn+ lórí ohun tí Ámálékì ṣe sí Ísírẹ́lì, nígbà tí ó gbé ara rẹ̀ kalẹ̀ láti gbéjà kò ó ní ọ̀nà, nígbà tí ó ń gòkè bọ̀ láti Íjíbítì.+  Wàyí o, lọ, kí o sì ṣá Ámálékì+ balẹ̀, kí o sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun+ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní, kí o má sì ṣe ní ìyọ́nú sí i, kí o sì fi ikú pa wọ́n,+ ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ọmọdé àti ọmọ ẹnu ọmú,+ akọ màlúù àti àgùntàn, ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sọ́ọ̀lù fi ọlá àṣẹ pe àwọn ènìyàn náà, ó sì ka iye wọn ní Téláímù,+ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá àwọn ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn ọkùnrin Júdà.+  Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ títí ó fi dé ìlú ńlá Ámálékì, ó sì ba ní ibùba lẹ́bàá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá.  Láàárín àkókò yìí, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kénì+ pé: “Ẹ lọ,+ ẹ kúrò, ẹ sọ̀ kalẹ̀ kúrò ní àárín àwọn ọmọ Ámálékì, kí n má bàa gbá ọ lọ pẹ̀lú wọn. Ní ti ìwọ, o ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì+ nígbà tí wọ́n ń gòkè bọ̀ láti Íjíbítì.”+ Nítorí náà, àwọn Kénì kúrò ní àárín Ámálékì.  Lẹ́yìn ìyẹn, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Ámálékì+ balẹ̀ láti Háfílà+ títí dé Ṣúrì,+ tí ó wà ní iwájú Íjíbítì.  Ó sì mú Ágágì+ ọba Ámálékì láàyè, gbogbo àwọn ènìyàn yòókù ni ó sì fi ojú idà yà sọ́tọ̀ fún ìparun.+  Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù àti àwọn ènìyàn náà ní ìyọ́nú sí Ágágì àti sí èyí tí ó dára jù lọ nínú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran+ àti àwọn tí ó sanra àti sí àwọn àgbò àti sí gbogbo ohun tí ó dára, wọn kò sì fẹ́ yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Ní ti gbogbo ẹrù tí ó jẹ́ ohun ìtẹ́ńbẹ́lú, tí a sì kọ̀ sílẹ̀, ìwọ̀nyí ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìparun. 10  Wàyí o, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Sámúẹ́lì wá, pé: 11  “Mo kẹ́dùn+ pé mo ti mú kí Sọ́ọ̀lù jẹ ọba, nítorí pé ó ti yí padà+ kúrò ní títọ̀ mí lẹ́yìn, kò sì mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ.”+ Ó sì mú wàhálà-ọkàn bá Sámúẹ́lì,+ ó sì ń bá a nìṣó ní kíké jáde sí Jèhófà láti òru mọ́jú.+ 12  Nígbà náà ni Sámúẹ́lì dìde ní kùtùkùtù láti pàdé Sọ́ọ̀lù ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n a ròyìn fún Sámúẹ́lì, pé: “Sọ́ọ̀lù wá sí Kámẹ́lì,+ sì wò ó! ó gbé ohun ìránnilétí+ kan nà ró fún ara rẹ̀, lẹ́yìn náà, ó sì yí padà, ó sì sọdá, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Gílígálì.” 13  Níkẹyìn, Sámúẹ́lì tọ Sọ́ọ̀lù wá, Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Alábùkún+ ni ọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Mo ti pa ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́.”+ 14  Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì sọ pé: “Kí wá ni ìró yìí tí ó jẹ́ ti agbo ẹran ní etí-ìgbọ́ mi túmọ̀ sí, àti ìró ọ̀wọ́ ẹran tí mo ń gbọ́?”+ 15  Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámálékì ni wọ́n ti mú wọn wá, nítorí pé àwọn ènìyàn náà ní ìyọ́nú+ sí èyí tí ó dára jù lọ nínú agbo ẹran àti nínú ọ̀wọ́ ẹran, fún ète rírúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ;+ ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣẹ́ kù ni a ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun.” 16  Látàrí èyí, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Dákẹ́! Èmi yóò sì sọ ohun tí Jèhófà sọ fún mi ní òru àná fún ọ.”+ Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Sọ ọ́!” 17  Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kì í ha ṣe ìgbà tí o kéré lójú ara rẹ+ ni o jẹ́ olórí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti fòróró yàn+ ọ́ ṣe ọba lé Ísírẹ́lì lórí? 18  Lẹ́yìn náà, Jèhófà rán ọ ní iṣẹ́ àfiránni kan, ó sì sọ pé, ‘Lọ, kí o sì ya àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀+ náà, àwọn ọmọ Ámálékì, sọ́tọ̀ fún ìparun, kí o sì bá wọn jà títí ìwọ yóò fi pa wọ́n run pátápátá.’+ 19  Nítorí náà, èé ṣe tí o kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, ṣùgbọ́n tí o bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwọra kù gììrì sí ohun ìfiṣèjẹ,+ tí o sì ń ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà?”+ 20  Bí ó ti wù kí ó rí, Sọ́ọ̀lù wí fún Sámúẹ́lì pé: “Ṣùgbọ́n mo ti ṣègbọràn+ sí ohùn Jèhófà ní ti pé mo lọ ṣe iṣẹ́ àfiránni tí Jèhófà rán mi, mo sì mú Ágágì+ ọba Ámálékì wá, ṣùgbọ́n Ámálékì ni mo ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun.+ 21  Àwọn ènìyàn náà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àgùntàn àti màlúù nínú àwọn ohun ìfiṣèjẹ náà, èyí tí ó jẹ́ ààyò jù lọ nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun, láti fi rúbọ+ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Gílígálì.”+ 22  Ẹ̀wẹ̀, Sámúẹ́lì sọ pé: “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣègbọràn+ sàn ju ẹbọ,+ fífetísílẹ̀ sàn ju ọ̀rá+ àwọn àgbò; 23  nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀+ jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ìwoṣẹ́,+ fífi ìkùgbù ti ara ẹni síwájú sì jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú lílo agbára abàmì àti ère tẹ́ráfímù.+ Níwọ̀n bí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, òun kọ̀ ọ́ ní ọba.”+ 24  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù wí fún Sámúẹ́lì pé: “Mo ti ṣẹ̀;+ nítorí mo ti tẹ àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà àti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ lójú, nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn ènìyàn náà+ tí mo sì ṣègbọràn sí ohùn wọn. 25  Wàyí o, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì + mí, kí o sì bá mi padà, kí n lè wólẹ̀+ fún Jèhófà.” 26  Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Èmi kì yóò bá ọ padà, nítorí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, Jèhófà sì kọ̀ ọ́ láti máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Ísírẹ́lì.”+ 27  Bí Sámúẹ́lì ti ń yíjú padà láti lọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rá etí gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ tí kò lápá mú, ṣùgbọ́n ó fà ya.+ 28  Látàrí èyí, Sámúẹ́lì sọ fún un pé: “Jèhófà ti fa ìṣàkóso ọba Ísírẹ́lì ya+ kúrò lọ́wọ́ rẹ lónìí, dájúdájú, yóò sì fi í fún ọmọnìkejì rẹ tí ó sàn jù ọ́.+ 29  Ní àfikún, Ẹni Títayọ Lọ́lá Ísírẹ́lì+ kì yóò já sí èké,+ Òun kì yóò sì kábàámọ̀, nítorí Òun kì í ṣe ará ayé tí yóò fi kábàámọ̀.”+ 30  Látàrí èyí, ó wí pé: “Mo ti ṣẹ̀. Jọ̀wọ́, bọlá fún mi+ wàyí, ní iwájú àwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn mi àti ní iwájú Ísírẹ́lì, kí o sì bá mi padà, dájúdájú, èmi yóò sì wólẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”+ 31  Nítorí náà, Sámúẹ́lì padà tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ fún Jèhófà. 32  Lẹ́yìn ìyẹn, Sámúẹ́lì sọ pé: “Ẹ mú Ágágì ọba Ámálékì sún mọ́ mi.” Nígbà náà ni Ágágì fi ìlọ́tìkọ̀ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, Ágágì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ara rẹ̀ pé: “Ní tòótọ́, ìrírí kíkorò ikú ti lọ.” 33  Bí ó ti wù kí ó rí, Sámúẹ́lì sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí idà+ rẹ tí mú àwọn obìnrin ṣòfò ọmọ wọn, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe mú ìyá rẹ+ di ẹni tí ó ṣòfò ọmọ jù lọ láàárín àwọn obìnrin.”+ Pẹ̀lú ìyẹn, Sámúẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Ágágì sí wẹ́wẹ́ níwájú Jèhófà ní Gílígálì.+ 34  Wàyí o, Sámúẹ́lì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí Rámà, Sọ́ọ̀lù, ní tirẹ̀, sì gòkè lọ sí ilé rẹ̀ ní Gíbíà+ ti Sọ́ọ̀lù. 35  Sámúẹ́lì kò sì tún rí Sọ́ọ̀lù mọ́ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, nítorí pé Sámúẹ́lì ti wọnú ìṣọ̀fọ̀+ fún Sọ́ọ̀lù. Ní ti Jèhófà, ó kẹ́dùn pé òun ti fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé