Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 14:1-52

14  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kan pé, Jónátánì+ ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ẹmẹ̀wà tí ń ru àwọn ohun ìjà rẹ̀ pé: “Wá, sì jẹ́ kí a sọdá lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó àwọn Filísínì tí wọ́n wà ní òdì-kejì níbẹ̀ yẹn.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀.+  Sọ́ọ̀lù sì ń gbé ní ẹ̀yìn odi Gíbíà,+ lábẹ́ igi pómégíránétì tí ó wà ní Mígírónì; àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀ta ọkùnrin.+  (Áhíjà ọmọkùnrin Áhítúbù,+ arákùnrin Íkábódì,+ ọmọkùnrin Fíníhásì,+ ọmọkùnrin Élì,+ àlùfáà Jèhófà ní Ṣílò,+ sì ń gbé éfódì+ wọ̀.) Àwọn ènìyàn náà kò sì mọ̀ pé Jónátánì ti lọ.  Wàyí o, láàárín àwọn ọ̀nà àbákọjá tí Jónátánì fojú wá láti sọdá lọ bá ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó+ àwọn Filísínì ni àpáta gàǹgà tí ó dà bí eyín wà ní ìhà ìhín, tí àpáta gàǹgà tí ó dà bí eyín sì wà ní ìhà ọ̀hún, orúkọ èkíní sì ń jẹ́ Bósésì, orúkọ ìkejì sì ń jẹ́ Sénè.  Eyín èkíní jẹ́ ọwọ̀n ní àríwá, ó dojú kọ Míkímáṣì,+ ìkejì wà ní gúúsù, ó sì dojú kọ Gébà.+  Nítorí náà, Jónátánì sọ fún ẹmẹ̀wà, arùhámọ́ra rẹ̀ pé: “Wá, sì jẹ́ kí a sọdá lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó àwọn aláìdádọ̀dọ́+ wọ̀nyí. Bóyá Jèhófà yóò ṣiṣẹ́ fún wa, nítorí kò sí ìdílọ́wọ́ fún Jèhófà láti fi púpọ̀ tàbí díẹ̀ gbà là.”+  Látàrí èyí, arùhámọ́ra rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣe ohun yòówù tí ó bá wà ní ọkàn-àyà rẹ. Yíjú sí ibi tí o bá fẹ́. Èmi rèé pẹ̀lú rẹ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ọkàn-àyà rẹ.”+  Nígbà náà ni Jónátánì wí pé: “Kíyè sí i, àwa ń sọdá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin náà, sì jẹ́ kí a fi ara wa hàn wọ́n.  Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni wọ́n wí fún wa, ‘Ẹ dúró jẹ́ẹ́ títí a ó fi kàn yín lára!’ nígbà náà, àwa yóò dúró sí ibi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ. 10  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni wọ́n wí, ‘Ẹ gòkè wá gbéjà kò wa!’ nígbà náà, àwa yóò gòkè lọ, nítorí pé Jèhófà yóò fi wọ́n lé wa lọ́wọ́ dájúdájú, èyí sì jẹ́ àmì fún wa.”+ 11  Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn méjèèjì fi ara wọn han ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó àwọn Filísínì. Àwọn Filísínì sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Àwọn Hébérù rèé tí ń jáde wá láti inú àwọn ihò níbi tí wọ́n fi ara wọn pa mọ́ sí.”+ 12  Nítorí náà, àwọn ọkùnrin ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó náà dá Jónátánì àti arùhámọ́ra rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé: “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá, dájúdájú, àwa yóò sì fojú yín rí nǹkan!”+ Ní kíá, Jónátánì sọ fún arùhámọ́ra rẹ̀ pé: “Gòkè tẹ̀ lé mi, nítorí pé Jèhófà yóò fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ dájúdájú.”+ 13  Jónátánì sì ń fi ọwọ́+ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ rá gòkè lọ, àti arùhámọ́ra rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣubú níwájú Jónátánì,+ arùhámọ́ra rẹ̀ sì ń fi ikú pa wọ́n lẹ́yìn rẹ̀.+ 14  Ìpakúpa àkọ́kọ́ tí Jónátánì àti arùhámọ́ra rẹ̀ fi ṣá wọn balẹ̀ sì jẹ́ nǹkan bí ogún ọkùnrin láàárín nǹkan bí ìdajì ìlà ìtúlẹ̀ inú sarè pápá kan. 15  Nígbà náà ni ìwárìrì+ ṣẹlẹ̀ ní ibùdó inú pápá àti láàárín gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lára ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó; agbo ọmọ ogun àwọn akóni-ní-ìkógun+ sì wárìrì, àní àwọn pàápàá, ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì,+ ó sì di ìwárìrì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 16  Àwọn olùṣọ́ tí ó jẹ́ ti Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì sì wá rí i, sì wò ó! yánpọnyánrin náà fì síhìn-ín sọ́hùn-ún.+ 17  Sọ́ọ̀lù sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ka iye àwọn ènìyàn láti mọ ẹni tí ó ti jáde lọ nínú wa.” Nígbà tí wọ́n ṣe kíkà náà, họ́wù, wò ó! Jónátánì àti arùhámọ́ra rẹ̀ kò sí níbẹ̀. 18  Wàyí o, Sọ́ọ̀lù sọ fún Áhíjà+ pé: “Gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sún mọ́ tòsí!”+ (Nítorí pé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọjọ́ yẹn.)+ 19  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé bí Sọ́ọ̀lù ti ń bá àlùfáà náà sọ̀rọ̀,+ yánpọnyánrin tí ó wà ní ibùdó àwọn Filísínì ń bá a lọ, ó túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù sọ fún àlùfáà pé: “Dáwọ́ dúró.” 20  Bí a ṣe pe Sọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ jáde nìyẹn.+ Nítorí náà, wọ́n lọ títí wọ́n fi dé ojú ìjà ogun náà, idà olúkúlùkù sì ti wá dojú kọ ọmọnìkejì rẹ̀ níbẹ̀;+ ìlésá kìjokìjo náà pọ̀ gidigidi. 21  Àwọn Hébérù tí wọ́n sì jẹ́ ti àwọn Filísínì+ tẹ́lẹ̀ rí, tí wọ́n sì ti bá wọn gòkè lọ sí ibùdó yí ká, àní àwọn pàápàá ń fi ara wọn hàn pé wọ́n wà pẹ̀lú Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì. 22  Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n fara pa mọ́+ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù gbọ́ pé àwọn Filísínì ti fẹsẹ̀ fẹ, àwọn pẹ̀lú sì ń lépa wọn pẹ́kípẹ́kí nínú ìjà ogun náà. 23  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí gba Ísírẹ́lì là+ ní ọjọ́ yẹn, ìjà ogun náà sì ré kọjá sí Bẹti-áfénì.+ 24  Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pàápàá ni a sì ni lára dé góńgó ní ọjọ́ yẹn, síbẹ̀, Sọ́ọ̀lù sì mú kí àwọn ènìyàn náà wá sábẹ́ ẹ̀jẹ́ ìbúra+ kan, pé: “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó bá jẹ oúnjẹ kí ó tó di alẹ́ àti títí èmi yóò fi gbẹ̀san+ lára àwọn ọ̀tá mi!” Kò sì sí ẹnì kan nínú àwọn ènìyàn náà tí ó tọ́ oúnjẹ wò.+ 25  Gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà sì dé inú ẹgàn, nígbà tí ó ṣẹlẹ̀ pé oyin+ wà ní orí pápá. 26  Nígbà tí àwọn ènìyàn náà dé inú ẹgàn, họ́wù, wò ó! ìrotótó oyin+ wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ sẹ́nu, nítorí pé àwọn ènìyàn ń fòyà ìbúra náà.+ 27  Ní ti Jónátánì, kò gbọ́ nígbà tí baba rẹ̀ mú kí àwọn ènìyàn náà wá sábẹ́ ìbúra,+ nítorí náà, ó na orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì tẹ̀ ẹ́ bọ afárá oyin náà, ó sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí tàn yanran.+ 28  Látàrí èyí, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn náà dáhùn, ó sì wí pé: “Baba rẹ mú kí àwọn ènìyàn wá sábẹ́ ìbúra lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀, pé: ‘Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó bá jẹ oúnjẹ lónìí!’”+ (Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ àwọn ènìyàn náà.)+ 29  Bí ó ti wù kí ó rí, Jónátánì wí pé: “Baba mi ti mú ìtanùlẹ́gbẹ́+ wá sórí ilẹ̀ yìí. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wo bí ojú mi ti tàn yanran nítorí pé mo tọ́ oyin díẹ̀ yìí wò.+ 30  Mélòómélòó ni ì bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ká ní àwọn ènìyàn náà ti jẹ+ lónìí nínú ohun ìfiṣèjẹ àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí!+ Nítorí ìpakúpa lára àwọn Filísínì kò tíì pọ̀ nísinsìnyí.”+ 31  Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣá àwọn Filísínì balẹ̀ láti Míkímáṣì+ títí dé Áíjálónì,+ ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà gidigidi.+ 32  Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwọra kù gììrì sí ohun ìfiṣèjẹ,+ wọ́n sì ń mú àgùntàn àti màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n sì ń pa wọ́n sórí ilẹ̀, àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.+ 33  Nítorí náà, wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Wò ó! Àwọn ènìyàn yìí ń ṣẹ̀ sí Jèhófà nípa jíjẹ ẹ́ mọ́ ẹ̀jẹ̀.”+ Látàrí èyí, ó wí pé: “Ẹ ti ṣe àdàkàdekè. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi.” 34  Lẹ́yìn ìyẹn, Sọ́ọ̀lù wí pé: “Ẹ tú ká sáàárín àwọn ènìyàn, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù yín mú akọ màlúù tirẹ̀ àti, olúkúlùkù, àgùntàn tirẹ̀, sún mọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí ẹ sì ṣe pípa àti jíjẹ náà ní ibí yìí, kí ẹ má sì ṣẹ̀ sí Jèhófà nípa jíjẹ ẹ́ mọ́ ẹ̀jẹ̀.’”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbogbo ènìyàn náà, olúkúlùkù, mú akọ màlúù tirẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ ní òru yẹn sún mọ́ tòsí, ó sì ṣe pípa náà níbẹ̀. 35  Sọ́ọ̀lù sì tẹ̀ síwájú láti mọ pẹpẹ+ kan fún Jèhófà. Ìyẹn ni ó fi bẹ̀rẹ̀ pẹpẹ mímọ fún Jèhófà.+ 36  Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù wí pé: “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀ kalẹ̀ tọ àwọn Filísínì lọ ní òru, kí a sì piyẹ́ wọn títí ilẹ̀ òwúrọ̀ yóò fi mọ́,+ ẹ má sì jẹ́ kí a ṣẹ́ ẹyọ ẹnì kan kù nínú wọn.”+ Wọ́n fèsì pé: “Ṣe gbogbo ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ.” Nígbà náà ni àlùfáà sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a tọ Ọlọ́run tòótọ́ lọ níhìn-ín.”+ 37  Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé: “Ṣé kí n sọ̀ kalẹ̀ tọ àwọn Filísínì lọ?+ Ìwọ yóò ha fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ bí?”+ Kò sì dá a lóhùn ní ọjọ́ yẹn.+ 38  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ sún mọ́ ìhín,+ gbogbo ẹ̀yin gíríkì ọkùnrin nínú àwọn ènìyàn,+ kí ẹ sì wádìí dájú, kí ẹ sì wá ọ̀nà tí ẹ̀ṣẹ̀ yìí gbà wáyé lónìí. 39  Nítorí bí Jèhófà, ẹni tí ó jẹ́ Olùdáǹdè Ísírẹ́lì, ti ń bẹ láàyè, àní bí ó bá jẹ́ nínú Jónátánì ọmọkùnrin mi ni, síbẹ̀, yóò kú dájúdájú.”+ Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó dá a lóhùn nínú gbogbo àwọn ènìyàn náà. 40  Ó sì ń bá a lọ ní sísọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Ẹ̀yin fúnra yín yóò wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, èmi àti Jónátánì ọmọkùnrin mi—àwa yóò sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì .” Látàrí èyí, àwọn ènìyàn náà sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ.”+ 41  Sọ́ọ̀lù sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún Jèhófà pé: “Ọlọ́run Ísírẹ́lì, fúnni ní Túmímù!”+ Nígbà náà ni a mú Jónátánì àti Sọ́ọ̀lù, àwọn ènìyàn náà sì jáde lọ.+ 42  Wàyí o, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ ṣẹ́ kèké+ láti pinnu láàárín èmi àti Jónátánì ọmọkùnrin mi.” A sì mú Jónátánì. 43  Nígbà náà ni Sọ́ọ̀lù sọ fún Jónátánì pé: “Sọ fún mi, Kí ni o ṣe?”+ Nítorí náà, Jónátánì sọ fún un, ó sì wí pé: “Ní ti tòótọ́ mo tọ́ oyin díẹ̀ wò lórí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ mi.+ Èmi nìyí! Jẹ́ kí n kú!” 44  Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Báyìí ni kí Ọlọ́run ṣe, báyìí sì ni kí ó fi kún un,+ dájúdájú, bí ìwọ kì yóò bá kú,+ Jónátánì.” 45  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Jónátánì yóò ha kú, tí ó ti mú ìgbàlà ńláǹlà yìí+ ṣe ní Ísírẹ́lì? Kò ṣée ronú kàn!+ Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè,+ ẹyọ kan nínú irun orí+ rẹ̀ kì yóò bọ́ sí ilẹ̀; nítorí ó bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ lónìí yìí.”+ Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn ènìyàn tún Jónátánì rà padà,+ kò sì kú. 46  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù fà sẹ́yìn kúrò ní títọ àwọn Filísínì lẹ́yìn, àwọn Filísínì sì lọ sí ipò wọn.+ 47  Sọ́ọ̀lù sì ń ṣe àkóso lórí Ísírẹ́lì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá gbogbo ọ̀tá rẹ̀ jagun yíká-yíká, ní bíbá Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ àti Édómù+ àti àwọn ọba Sóbà+ àti àwọn Filísínì+ jagun; ibikíbi tí ó bá yíjú sí, a sì dá wọn lẹ́bi.+ 48  Ó sì ń bá a lọ ní gbígbé ìgbésẹ̀ akíkanjú,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣá Ámálékì+ balẹ̀, ó sì dá Ísírẹ́lì nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn tí ń kó wọn ní ìkógun. 49  Àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù sì wá jẹ́ Jónátánì+ àti Íṣífì àti Maliki-ṣúà,+ àti pé, ní ti orúkọ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì , orúkọ àkọ́bí ni Mérábù,+ orúkọ àbúrò sì ni Míkálì.+ 50  Orúkọ aya Sọ́ọ̀lù sì ni Áhínóámù ọmọbìnrin Áhímáásì, orúkọ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sì ni Ábínérì+ ọmọkùnrin Nérì, arákùnrin òbí Sọ́ọ̀lù. 51  Kíṣì+ sì ni baba Sọ́ọ̀lù, Nérì+ baba Ábínérì sì ni ọmọkùnrin Ábíélì. 52  Ogun náà sì ń bá a lọ ní gbígbóná mọ́ àwọn Filísínì ní gbogbo ọjọ́ Sọ́ọ̀lù.+ Nígbà tí Sọ́ọ̀lù bá rí alágbára ńlá ọkùnrin èyíkéyìí tàbí akíkanjú èyíkéyìí, òun a mú un sọ́dọ̀ ara rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé