Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 13:1-23

13  Sọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni ọdún [?] nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba,+ ọdún méjì sì ni ó fi jọba lé Ísírẹ́lì lórí.  Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún ènìyàn fún ara rẹ̀ láti inú Ísírẹ́lì; ẹgbàá sì wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù ní Míkímáṣì+ àti ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Bẹ́tẹ́lì, ẹgbẹ̀rún sì wà pẹ̀lú Jónátánì+ ní Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì, ó sì rán ìyókù àwọn ènìyàn náà lọ, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀.  Nígbà náà ni Jónátánì ṣá ẹgbẹ́ ogun+ àwọn Filísínì+ tí ó wà ní Gébà+ balẹ̀; àwọn Filísínì sì gbọ́. Ní ti Sọ́ọ̀lù, ó mú kí a fun ìwo+ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ náà, pé: “Kí gbogbo àwọn Hébérù gbọ́ o!”  Gbogbo Ísírẹ́lì fúnra rẹ̀ sì gbọ́ tí a sọ pé: “Sọ́ọ̀lù ti ṣá ẹgbẹ́ ogun àwọn Filísínì balẹ̀, nísinsìnyí, Ísírẹ́lì ti di òórùn burúkú+ láàárín àwọn Filísínì.” Nítorí náà, a pe àwọn ènìyàn náà jọ láti tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù lọ sí Gílígálì.+  Àwọn Filísínì, ní tiwọn, kó ara wọn jọpọ̀ láti bá Ísírẹ́lì jà, ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun+ àti ẹgbàáta àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn ènìyàn bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó;+ wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n gòkè lọ, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti dó sí Míkímáṣì sí ìlà-oòrùn Bẹti-áfénì.+  Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì fúnra wọn sì rí i pé wọ́n wà nínú hílàhílo,+ nítorí pé a ni àwọn ènìyàn náà lára dé góńgó; àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn hòrò+ àti sínú àwọn ibi jíjinkòtò àti àwọn àpáta gàǹgà àti ihò abẹ́lẹ̀ àti àwọn kòtò omi.  Àwọn Hébérù tilẹ̀ sọdá Jọ́dánì+ lọ sí ilẹ̀ Gádì+ àti Gílíádì. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ṣì wà ní Gílígálì, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wárìrì bí wọ́n ti ń tẹ̀ lé e.+  Ó sì ń bá a lọ ní dídúró fún ọjọ́ méje de àkókò tí a yàn kalẹ̀ tí Sámúẹ́lì wí;+ Sámúẹ́lì kò sì wá sí Gílígálì, àwọn ènìyàn sì ń tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.  Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ mú ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ náà sún mọ́ mi.” Pẹ̀lú ìyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sísun náà.+ 10  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó parí rírú ẹbọ sísun náà, họ́wù, Sámúẹ́lì rèé tí ń wọlé bọ̀. Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sì bù kún un.+ 11  Nígbà náà ni Sámúẹ́lì sọ pé: “Kí ni ohun tí ìwọ ṣe?”+ Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Mo rí i pé àwọn ènìyàn ti fọ́n ká kúrò lọ́dọ̀ mi,+ àti ìwọ—ìwọ kò wá láàárín àwọn ọjọ́ tí a dá,+ àwọn Filísínì sì ń kóra jọpọ̀ ní Míkímáṣì,+ 12  nítorí náà, mo wí fún ara mi+ pé, ‘Wàyí o, àwọn Filísínì yóò sọ̀ kalẹ̀ wá gbéjà kò mí ní Gílígálì, èmi kò sì tíì tu Jèhófà lójú.’ Nítorí náà, mo ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ara+ mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sísun náà.” 13  Látàrí èyí, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ìwọ ti hùwà òmùgọ̀.+ Ìwọ kò pa àṣẹ+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí ó pa láṣẹ fún ọ,+ nítorí pé, ká ní o ti ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ì bá ti mú kí ìjọba rẹ fì dí múlẹ̀ gbọn-in lórí Ísírẹ́lì fún àkókò tí ó lọ kánrin. 14  Wàyí o, ìjọba rẹ kì yóò pẹ́.+ Dájúdájú, Jèhófà yóò wá ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà rẹ̀ lọ́rùn fún ara rẹ̀;+ Jèhófà yóò sì fàṣẹ yàn án ṣe aṣáájú+ lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún ọ mọ́.”+ 15  Nígbà náà ni Sámúẹ́lì dìde, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n gòkè lọ láti Gílígálì sí Gíbíà ti Bẹ́ńjámínì, Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí ka iye àwọn ènìyàn náà, àwọn tí a ṣì rí pẹ̀lú rẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀ta ọkùnrin.+ 16  Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí a ṣì rí pẹ̀lú wọn sì ń gbé ní Gébà+ ti Bẹ́ńjámínì. Ní ti àwọn Filísínì, wọ́n ti dó sí Míkímáṣì.+ 17  Agbo ọmọ ogun àwọn akóni-ní-ìkógun a sì máa jáde ogun láti ibùdó àwọn Filísínì ní àwùjọ ọmọ ogun mẹ́ta.+ Àwùjọ ọmọ ogun kan a yíjú sí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí Ọ́fírà,+ sí ilẹ̀ Ṣúálì, 18  àwùjọ ọmọ ogun kejì a sì yíjú sí ojú ọ̀nà Bẹti-hórónì,+ àwùjọ ọmọ ogun kẹta a sì yíjú sí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ààlà tí ó dojú kọ àfonífojì Sébóímù, síhà aginjù. 19  Wàyí o, a kò rí alágbẹ̀dẹ kankan ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí pé àwọn Filísínì ti wí pé: “Kí àwọn Hébérù má bàa rọ idà tàbí ọ̀kọ̀.”+ 20  Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a sì sọ̀ kalẹ̀ tọ àwọn Filísínì lọ, olúkúlùkù láti pọ́n abẹ ohun ìtúlẹ̀ rẹ̀ tàbí jígà rẹ̀ tàbí àáké rẹ̀ tàbí dòjé rẹ̀.+ 21  Iye tí a fi ń pọ́n nǹkan sì jẹ́ iye owó píìmù kan fún àwọn abẹ ohun ìtúlẹ̀ àti fún jígà àti fún àwọn ohun èlò eléyín mẹ́ta àti fún àáké àti fún díde ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù pinpin.+ 22  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ìjà ogun pé a kò rí idà+ tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù+ àti Jónátánì; ṣùgbọ́n a lè rí ọ̀kan tí ó jẹ́ ti Sọ́ọ̀lù àti ti Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀. 23  Wàyí o, ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó+ àwọn Filísínì a jáde ogun lọ sí ọ̀nà àfonífojì tóóró ti Míkímáṣì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé