Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Sámúẹ́lì 12:1-25

12  Níkẹyìn, Sámúẹ́lì wí fún gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Kíyè sí i, èmi ti fetí sí ohùn yín ní ti gbogbo ohun tí ẹ wí fún mi,+ pé kí n mú kí ọba jẹ lé yín lórí.+  Wàyí o, ọba náà rèé tí ń rìn níwájú yín!+ Ní tèmi, mo ti darúgbó,+ mo sì ti hewú,+ àti àwọn ọmọkùnrin mi, àwọn rèé pẹ̀lú yín,+ èmi—èmi sì ti rìn níwájú yín láti ìgbà èwe mi títí di òní yìí.+  Èmi nìyí. Ẹ dáhùn lòdì sí mi ní iwájú Jèhófà àti ní iwájú ẹni àmì òróró+ rẹ̀: Akọ màlúù ta ni mo gbà+ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà tàbí ta ni mo lù ní jì bìtì tàbí ta ni mo ni lára tàbí ọwọ́ ta ni mo ti gba owó mẹ́numọ́, tí mo fi ní láti fi í pa ojú mi mọ́?+ Èmi yóò sì ṣe ìmúpadàbọ̀sípò fún yín.”+  Wọ́n fèsì pé: “Ìwọ kò lù wá ní jì bìtì, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni wá lára, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹyọ ẹnì kan.”+  Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Jèhófà ni ẹlẹ́rìí lòdì sí yín, ẹni àmì òróró+ rẹ̀ sì ni ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé ẹ kò rí nǹkan kan rárá ní ọwọ́ mi.”+ Wọ́n fèsì pé: “Òun ni ẹlẹ́rìí.”  Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Jèhófà [ni ẹlẹ́rìí], ẹni tí ó lo Mósè àti Áárónì, tí ó sì mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì.+  Wàyí o, ẹ mú ìdúró yín, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín níwájú Jèhófà, [èmi yóò sì ròyìn lẹ́sẹẹsẹ fún yín] gbogbo ìṣe òdodo+ Jèhófà tí ó ti ṣe fún yín àti fún àwọn baba ńlá yín.  “Gbàrà tí Jékọ́bù dé Íjíbítì,+ tí àwọn baba ńlá yín sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́,+ Jèhófà tẹ̀ síwájú láti rán Mósè+ àti Áárónì, kí wọ́n lè mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní Íjíbítì, kí wọ́n sì mú kí wọ́n máa gbé ní ibí yìí.+  Wọ́n sì gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi tà+ wọ́n sí ọwọ́ Sísérà+ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hásórì àti sí ọwọ́ àwọn Filísínì+ àti sí ọwọ́ ọba Móábù,+ wọ́n sì ń bá wọn jà ṣáá. 10  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́,+ wọ́n sì wí pé, ‘A ti ṣẹ̀,+ nítorí a ti fi Jèhófà sílẹ̀, kí a lè sin àwọn Báálì+ àti àwọn ère Áṣítórétì;+ wàyí o, dá wa nídè+ kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wa, kí a lè sìn ọ́.’ 11  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti rán Jerubáálì+ àti Bédánì àti Jẹ́fútà+ àti Sámúẹ́lì,+ ó sì dá yín nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá yín ní gbogbo àyíká, kí ẹ bàa lè máa gbé ní ààbò.+ 12  Nígbà tí ẹ rí i pé Náháṣì+ ọba àwọn ọmọ Ámónì wá gbéjà kò yín, ẹ ń bá a nìṣó ní sísọ fún mi pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ọba kan ni kí ó jẹ lé wa lórí!’+ ní gbogbo àkókò náà, Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọba yín.+ 13  Wàyí o, ọba náà tí ẹ yàn rèé, ẹni tí ẹ béèrè;+ sì kíyè sí i, Jèhófà ti fi ọba kan jẹ lé yín lórí.+ 14  Bí ẹ óò bá bẹ̀rù Jèhófà,+ tí ẹ ó sì sìn ín+ ní ti tòótọ́, tí ẹ ó sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀,+ tí ẹ kì yóò sì ṣọ̀tẹ̀+ sí àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, ẹ̀yin àti ọba náà tí yóò jẹ lé yín lórí, dájúdájú, yóò jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run yín. 15  Ṣùgbọ́n bí ẹ kì yóò bá ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà,+ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọni Jèhófà+ ní ti tòótọ́, dájúdájú, ọwọ́ Jèhófà yóò wà lòdì sí ẹ̀yin àti àwọn baba yín.+ 16  Wàyí o, pẹ̀lú, ẹ mú ìdúró yín, kí ẹ sì rí ohun ńlá yìí tí Jèhófà yóò ṣe lójú yín. 17  Òní kì í ha ṣe ọjọ́ ìkórè àlìkámà?+ Èmi yóò ké pe+ Jèhófà, kí ó lè mú ààrá àti òjò+ wá; nígbà náà, ẹ mọ̀, kí ẹ sì rí i pé ọ̀pọ̀ yanturu+ ni ibi tí ẹ ti ṣe lójú Jèhófà ní bíbéèrè ọba fún ara yín.” 18  Látàrí ìyẹn, Sámúẹ́lì ké pe Jèhófà,+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ààrá àti òjò wá ní ọjọ́ yẹn,+ tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ènìyàn náà fi bẹ̀rù Jèhófà àti Sámúẹ́lì gidigidi. 19  Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Gbàdúrà+ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, níwọ̀n bí a kò ti fẹ́ kú; nítorí pé a ti fi ibi kan kún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè ọba fún ara wa.” 20  Nítorí náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ má fòyà.+ Ẹ̀yin—ẹ ti ṣe gbogbo ibi yìí. Kì kì pé kí ẹ má ṣe yà kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn,+ kí ẹ sì fi gbogbo ọkàn-àyà yín sin Jèhófà.+ 21  Kí ẹ má sì yà sí títọ òtúbáńtẹ́+ lẹ́yìn, èyí tí kò ṣàǹfààní,+ tí kì í sì í dáni nídè, nítorí pé òtúbáńtẹ́ ni wọ́n. 22  Nítorí Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì,+ nítorí orúkọ ńlá rẹ̀,+ nítorí pé Jèhófà ti dáwọ́ lé e láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀.+ 23  Ní ti èmi pẹ̀lú, kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ṣẹ̀ sí Jèhófà nípa ṣíṣíwọ́ láti gbàdúrà nítorí yín;+ èmi yóò sì fún yín ní ìtọ́ni+ ní ọ̀nà rere+ àti títọ́. 24  Kì kì pé kí ẹ bẹ̀rù+ Jèhófà, kí ẹ sì sìn ín ní òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà yín;+ nítorí ẹ rí àwọn ohun ńlá tí ó ti ṣe fún yín.+ 25  Ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi ìwà ọ̀dájú ṣe ohun búburú, a óò gbá yín lọ,+ ẹ̀yin àti ọba yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé