Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 11:1-15

11  Náháṣì ará Ámónì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ, ó sì dó ti Jábẹ́ṣì+ ní Gílíádì. Látàrí ìyẹn, gbogbo ọkùnrin Jábẹ́ṣì wí fún Náháṣì pé: “Bá wa dá májẹ̀mú, kí a lè sìn ọ́.”+  Nígbà náà ni Náháṣì ará Ámónì wí fún wọn pé: “Lábẹ́ ipò yìí ni èmi yóò fi bá yín dá a, lábẹ́ ipò ti yíyọ+ gbogbo ojú ọ̀tún yín jáde, èmi yóò sì fi í ṣe ẹ̀gàn fún gbogbo Ísírẹ́lì.”+  Ẹ̀wẹ̀, àwọn àgbà ọkùnrin Jábẹ́ṣì wí fún un pé: “Fún wa ní ọjọ́ méje sí i, dájúdájú, àwa yóò sì rán àwọn ońṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì, bí kò bá sì sí olùgbàlà+ fún wa, nígbà náà, àwa yóò jáde tọ̀ ọ́ wá.”  Nígbà tí ó ṣe, àwọn ońṣẹ́ náà dé Gíbíà+ ti Sọ́ọ̀lù, wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ náà ní etí àwọn ènìyàn, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún.+  Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù rèé tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀wọ́ ẹran láti pápá, Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Kí ní ṣe àwọn ènìyàn, tí wọ́n fi ń sunkún?” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jábẹ́ṣì fún un.  Ẹ̀mí+ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Sọ́ọ̀lù ní gbígbọ́ tí ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ sì gbóná gidigidi.+  Nítorí náà, ó mú akọ màlúù méjì , ó sì gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì fi ìwọ̀nyí ránṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì+ nípa ọwọ́ àwọn ońṣẹ́ náà pé: “Ẹnì yòówù nínú wa tí kò bá jáde gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Sọ́ọ̀lù àti ti Sámúẹ́lì, báyìí ni a ó ṣe sí màlúù rẹ̀!”+ Ìbẹ̀rùbojo+ Jèhófà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ènìyàn náà tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi jáde gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo.+  Nígbà náà ni ó ka iye+ wọn ní Bésékì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀.  Wàyí o, wọ́n wí fún àwọn ońṣẹ́ tí ó wá pé: “Èyí ni ohun tí ẹ óò wí fún àwọn ọkùnrin Jábẹ́ṣì ní Gílíádì: ‘Lọ́la, ìgbàlà yóò ṣẹlẹ̀ fún yín nígbà tí oòrùn bá mú.’”+ Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn ońṣẹ́ náà wá, wọ́n sì wí fún àwọn ọkùnrin Jábẹ́ṣì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀. 10  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkùnrin Jábẹ́ṣì wí pé: “Lọ́la, àwa yóò jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ sì ṣe sí wa ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó bá dára ní ojú yín.”+ 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì pé Sọ́ọ̀lù+ bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ènìyàn náà sí àwùjọ ọmọ ogun mẹ́ta;+ wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí àárín ibùdó náà ní ìṣọ́ òwúrọ̀,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ọmọ Ámónì+ balẹ̀ títí ọ̀sán fi pọ́n. Nígbà tí ó ṣẹ́ ku àwọn kan, nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tú wọn ká, kò sì sí méjì lára wọn tí ó ṣẹ́ kù tí ó wà pa pọ̀.+ 12  Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Sámúẹ́lì pé: “Ta ni ẹni tí ń wí pé, ‘Sọ́ọ̀lù—yóò ha jẹ ọba lé wa lórí bí?’+ Ẹ fi àwọn ènìyàn náà lé wa lọ́wọ́, kí a lè fi ikú pa wọ́n.”+ 13  Bí ó ti wù kí ó rí, Sọ́ọ̀lù wí pé: “Kò sí ènìyàn kan tí a ó fi ikú pa lónìí yìí,+ nítorí pé lónìí Jèhófà ti ṣe ìgbàlà ní Ísírẹ́lì.”+ 14  Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a lọ sí Gílígálì+ kí a lè ṣe ipò ọba náà lákọ̀tun níbẹ̀.”+ 15  Nítorí náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà lọ sí Gílígálì, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba níbẹ̀ níwájú Jèhófà ní Gílígálì. Nígbà náà ni wọ́n rú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ níbẹ̀ níwájú Jèhófà,+ ibẹ̀ sì ni Sọ́ọ̀lù àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì ti ń bá a lọ láti yọ̀ ní ìwọ̀n tí ó kọyọyọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé