Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Sámúẹ́lì 1:1-28

1  Wàyí o, ọkùnrin kan báyìí wà, ará Ramataimu-sófíímù+ ti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù,+ orúkọ rẹ̀ sì ni Ẹlikénà,+ ọmọkùnrin Jéróhámù, ọmọkùnrin Élíhù, ọmọkùnrin Tóhù, ọmọkùnrin Súfì ,+ ará Éfúráímù.  Ó sì ní aya méjì , orúkọ ọ̀kan ń jẹ́ Hánà, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Pẹ̀nínà. Pẹ̀nínà sì wá ní àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò ní ọmọ.+  Ọkùnrin yẹn sì máa ń gòkè lọ láti ìlú ńlá rẹ̀ láti ọdún dé ọdún láti wólẹ̀,+ kí ó sì rúbọ sí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Ṣílò.+ Àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì , Hófínì àti Fíníhásì+ sì jẹ́ àlùfáà Jèhófà+ níbẹ̀.  Ó sì wá di ọjọ́ kan nígbà tí Ẹlikénà bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ, ó sì fi àwọn ìpín fún Pẹ̀nínà aya rẹ̀ àti gbogbo ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀;+  ṣùgbọ́n ó fún Hánà ní ìpín kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Hánà ni ó nífẹ̀ẹ́,+ àti pé, ní ti Jèhófà, ó ti sé ilé ọlẹ̀ rẹ̀.+  Orogún rẹ̀ pẹ̀lú sì ń mú un bínú+ gidigidi nítorí àtimú kí àìbalẹ̀-ọkàn bá a nítorí tí Jèhófà ti sé ilé ọlẹ̀ rẹ̀.  Bí ó sì ti máa ń ṣe nìyẹn lọ́dọọdún,+ nígbàkúùgbà tí ó bá gòkè lọ sí ilé Jèhófà.+ Bí ó ti máa ń mú un bínú nìyẹn, tí ó fi máa ń sunkún, kò sì ní jẹun.  Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Hánà, èé ṣe tí o fi ń sunkún, èé sì ti ṣe tí o kò fi jẹun, èé sì ti ṣe tí ìbànújẹ́ fi dé bá ọkàn-àyà rẹ?+ Èmi kò ha sàn fún ọ ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ bí?”+  Nígbà náà ni Hánà dìde, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹun tán ní Ṣílò àti lẹ́yìn mímu, nígbà tí Élì àlùfáà jókòó lórí ìjókòó lẹ́bàá òpó ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì+ Jèhófà. 10  Ó sì ní ìkorò ọkàn,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà,+ ó sì ń sunkún gidigidi.+ 11  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ ẹ̀jẹ́,+ ó sì wí pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, láìkùnà, bí ìwọ yóò bá wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ ẹrúbìnrin+ rẹ níṣẹ̀ẹ́, tí o sì rántí mi+ ní ti tòótọ́, tí ìwọ kì yóò sì gbàgbé ẹrúbìnrin rẹ, tí o sì fún ẹrúbìnrin rẹ ní ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin ní ti tòótọ́, èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ fẹ́lẹ́ kì yóò sì kan orí rẹ̀.”+ 12  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó gbàdúrà lọ títí+ níwájú Jèhófà, Élì ń wo ẹnu rẹ̀. 13  Ní ti Hánà, ó ń sọ̀rọ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀;+ ètè rẹ̀ nìkan ni ó ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, a kò sì gbọ́ ohùn rẹ̀. Ṣùgbọ́n Élì kà á sí pé ó mutí para ni.+ 14  Nítorí náà, Élì wí fún un pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣe bí ọ̀mùtípara?+ Mú wáìnì rẹ kúrò lára rẹ.” 15  Látàrí èyí, Hánà dáhùn, ó sì wí pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi! Obìnrin tí a ni ẹ̀mí rẹ̀ lára dé góńgó ni èmi; èmi kò sì mu wáìnì àti ọtí tí ń pani, ṣùgbọ́n mo ń tú ọkàn mi síta níwájú Jèhófà.+ 16  Má ka ẹrúbìnrin rẹ sí obìnrin aláìdára fún ohunkóhun,+ nítorí láti inú ọ̀pọ̀ yanturu ìdàníyàn mi àti ìbìnújẹ́ mi ni mo ti ń sọ̀rọ̀ títí di ìsinsìnyí.”+ 17  Nígbà náà ni Élì dáhùn, ó sì wí pé: “Máa lọ ní àlàáfíà,+ kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.”+ 18  Ó fèsì pé: “Kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ rí ojú rere ní ojú rẹ.”+ Obìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì jẹun,+ ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.+ 19  Nígbà náà ni wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú Jèhófà, lẹ́yìn èyí tí wọ́n padà, wọ́n sì wá sí ilé wọn ní Rámà.+ Wàyí o, Ẹlikénà ní ìbádàpọ̀+ pẹ̀lú Hánà aya rẹ̀, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí rántí rẹ̀.+ 20  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìyípo ọdún pé Hánà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ+ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, nítorí, ó wí pé, “ọwọ́ Jèhófà ni mo ti béèrè+ rẹ̀.” 21  Nígbà tí ó ṣe, ọkùnrin náà Ẹlikénà gòkè lọ pẹ̀lú gbogbo agbo ilé rẹ̀ láti rú ẹbọ ọdọọdún+ sí Jèhófà àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀jẹ́ rẹ̀.+ 22  Ní ti Hánà, òun kò gòkè lọ,+ nítorí ó ti sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Gbàrà tí a bá ti já ọmọdékùnrin náà lẹ́nu ọmú,+ èmi yóò mú un wá, yóò sì fara hàn níwájú Jèhófà, yóò sì máa gbé níbẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ 23  Látàrí èyí, Ẹlikénà ọkọ rẹ̀+ wí fún un pé: “Ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ.+ Dúró sí ilé títí ìwọ yóò fi já a lẹ́nu ọmú. Kì kì pé kí Jèhófà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.”+ Nítorí náà, obìnrin náà dúró sí ilé, ó sì ń tọ́jú ọmọkùnrin rẹ̀ títí ó fi já a lẹ́nu ọmú.+ 24  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbàrà tí ó ti já a lẹ́nu ọmú, ó mú un gòkè wá pẹ̀lú ara rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù ọlọ́dún mẹ́ta àti ìyẹ̀fun òṣùwọ̀n eéfà kan àti ìṣà wáìnì títóbi kan,+ ó sì wọnú ilé Jèhófà ní Ṣílò.+ Ọmọdékùnrin náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 25  Nígbà náà ni wọ́n pa akọ màlúù náà, wọ́n sì mú ọmọdékùnrin náà tọ Élì+ wá. 26  Pẹ̀lú ìyẹn, ó wí pé: “Dákun, olúwa mi! Nípa ìwàláàyè ọkàn+ rẹ, olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró pẹ̀lú rẹ ní ibí yìí láti gbàdúrà sí Jèhófà.+ 27  Ọmọdékùnrin yìí ni mo gbàdúrà nípa rẹ̀ pé kí Jèhófà yọ̀ǹda ìtọrọ+ tí mo ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 28  Èmi, ẹ̀wẹ̀, sì ti wín Jèhófà.+ Ní gbogbo ọjọ́ tí ó bá wà, ẹni tí a béèrè fún Jèhófà ni.” Ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba níbẹ̀ fún Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé