Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Pétérù 5:1-14

5  Nítorí náà, àwọn àgbà ọkùnrin tí ó wà láàárín yín ni mo fún ní ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí, nítorí èmi náà jẹ́ àgbà ọkùnrin+ pẹ̀lú wọn àti ẹlẹ́rìí+ àwọn ìjìyà Kristi, àní alájọpín ògo tí a ó ṣí payá:+  Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ agbo Ọlọ́run+ tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú;+ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí,+ bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà;  bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ+ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run+ lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.+  Nígbà tí a bá sì fi olórí olùṣọ́ àgùntàn+ hàn kedere, ẹ ó gba adé ògo+ tí kì í ṣá.+  Lọ́nà kan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, ẹ wà ní ìtẹríba+ fún àwọn àgbà ọkùnrin. Ṣùgbọ́n gbogbo yín, ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì,+ nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.+  Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ;+  bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn+ yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.+  Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́,+ ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.+  Ṣùgbọ́n ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i,+ ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé àwọn ohun kan náà lọ́nà ìyà jíjẹ ni a ń ṣe ní àṣeparí nínú gbogbo ẹgbẹ́ àwọn arákùnrin yín nínú ayé.+ 10  Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀,+ Ọlọ́run inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo, ẹni tí ó pè yín sí ògo àìnípẹ̀kun+ rẹ̀ ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Kristi, yóò fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,+ yóò sì sọ yín di alágbára.+ 11  Òun ni kí agbára ńlá jẹ́ tirẹ̀+ títí láé. Àmín. 12  Nípasẹ̀ Sílífánù,+ arákùnrin olùṣòtítọ́, bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé sí yín ní ọ̀rọ̀ díẹ̀,+ láti fún yín ní ìṣírí àti ìjẹ́rìí àfi-taratara-ṣe pé èyí ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tòótọ́ ti Ọlọ́run; ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú rẹ̀.+ 13  Obìnrin tí ń bẹ ní Bábílónì,+ àyànfẹ́ bí ẹ̀yin, kí yín, Máàkù+ ọmọkùnrin mi ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. 14  Ẹ fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kí ara yín.+ Àlàáfíà fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé