Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Pétérù 4:1-19

4  Nítorí náà, níwọ̀n bí Kristi ti jìyà nínú ẹran ara,+ ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ fi ìtẹ̀sí èrò orí kan náà di ara yín ní ìhámọ́ra;+ nítorí pé ẹni tí ó ti jìyà nínú ẹran ara ti yọwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀,+  fún ète pé kí ó lè gbé ìyókù àkókò rẹ̀ nínú ẹran ara,+ kì í tún ṣe fún ìfẹ́-ọkàn ènìyàn mọ́, bí kò ṣe fún ìfẹ́ Ọlọ́run.  Nítorí àkókò+ tí ó ti kọjá lọ ti tó fún yín láti fi ṣe ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè,+ nígbà tí ẹ ń tẹ̀ síwájú nínú àwọn ìwà àìníjàánu,+ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àṣejù nídìí wáìnì,+ àwọn àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí mímu, àti àwọn ìbọ̀rìṣà tí ó lòdì sí òfin.+  Nítorí ẹ kò bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú wọn ní ipa ọ̀nà yìí sínú kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà,+ ó rú wọn lójú, wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.+  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò jíhìn fún ẹni+ tí ó ti múra tán láti ṣèdájọ́ àwọn tí ó wà láàyè àti àwọn tí ó ti kú.+  Ní ti tòótọ́, fún ète yìí ni a fi polongo ìhìn rere fún àwọn òkú pẹ̀lú,+ kí a lè ṣèdájọ́ wọn ní ti ẹran ara ní ojú ìwòye ènìyàn+ ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láàyè ní ti ẹ̀mí+ ní ojú ìwòye Ọlọ́run.  Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.+ Nítorí náà, ẹ yè kooro ní èrò inú,+ kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn.+  Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì,+ nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.+  Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì láìsí ìráhùn.+ 10  Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.+ 11  Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó sọ̀rọ̀ bí pé àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀+ Ọlọ́run ni;+ bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́,+ kí ó ṣe ìránṣẹ́ bí ẹni tí ó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè;+ kí a lè yin Ọlọ́run lógo+ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ògo+ àti agbára ńlá jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín. 12  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí iná tí ń jó láàárín yín rú yín lójú, èyí tí ń ṣẹlẹ̀ sí yín fún àdánwò,+ bí ẹni pé ohun àjèjì ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí yín. 13  Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀+ níwọ̀n bí ẹ ti jẹ́ alájọpín nínú àwọn ìjìyà Kristi,+ kí ẹ lè yọ̀, kí ẹ sì ní ayọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú nígbà ìṣípayá+ ògo rẹ̀. 14  Bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi,+ ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀,+ nítorí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.+ 15  Àmọ́ ṣá o, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má jìyà+ gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn tàbí olè tàbí aṣebi tàbí gẹ́gẹ́ bí olùyọjúràn+ sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn. 16  Ṣùgbọ́n bí òun bá jìyà+ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, kí ó má ṣe tijú,+ ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní yíyin Ọlọ́run lógo ní orúkọ yìí. 17  Nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti tó fún ìdájọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run.+ Wàyí o, bí ó bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wa,+ kí ni yóò jẹ́ òpin àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere Ọlọ́run?+ 18  “Bí ó bá sì jẹ́ pé agbára káká ni a fi ń gba olódodo là,+ níbo ni aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò gbé yọjú?”+ 19  Nítorí bẹ́ẹ̀, kí àwọn tí ń jìyà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run máa bá a nìṣó ní fífi ọkàn wọn lé Ẹlẹ́dàá olùṣòtítọ́ lọ́wọ́ bí wọ́n ti ń ṣe rere.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé