Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Pétérù 3:1-22

3  Lọ́nà kan náà,+ ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba+ fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn+ sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè+ wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn,+  nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́+ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.  Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti irun dídì lóde ara+ àti ti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára+ tàbí ti wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè,  ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀+ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́+ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù,+ èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.  Nítorí, nígbà yẹn lọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obìnrin mímọ́ tí wọ́n ní ìrètí nínú Ọlọ́run máa ń ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní fífi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ tiwọn,  gẹ́gẹ́ bí Sárà ti máa ń ṣègbọràn sí Ábúráhámù, ní pípè é ní “olúwa.”+ Ẹ sì ti di ọmọ rẹ̀, kìkì bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣe rere, tí ẹ kò sì bẹ̀rù okùnfà èyíkéyìí fún ìpayà.+  Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé lọ́nà kan náà+ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀,+ kí ẹ máa fi ọlá fún wọn+ gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ tún ti jẹ́ ajogún+ ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.+  Lákòótán, gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà,+ kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn,+ kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú,+  kí ẹ má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe+ tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn,+ ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre,+ nítorí tí a pè yín sí ipa ọ̀nà yìí, kí ẹ lè jogún ìbùkún. 10  Nítorí, “ẹni tí yóò bá nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè, tí yóò sì rí àwọn ọjọ́ rere,+ kí ó kó ahọ́n+ rẹ̀ níjàánu kúrò nínú ohun búburú àti ètè rẹ̀ kúrò nínú ṣíṣe ẹ̀tàn,+ 11  ṣùgbọ́n kí ó yí padà kúrò nínú ohun búburú,+ kí ó sì máa ṣe ohun rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.+ 12  Nítorí tí ojú+ Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn;+ ṣùgbọ́n ojú Jèhófà lòdì sí àwọn tí ń ṣe àwọn ohun búburú.”+ 13  Ní tòótọ́, ta ni ẹni tí yóò pa yín lára bí ẹ bá di onítara fún ohun rere?+ 14  Ṣùgbọ́n àní bí ẹ bá ní láti jìyà nítorí òdodo pàápàá, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀.+ Àmọ́ ṣá o, ohun ìbẹ̀rù wọn ni kí ẹ má bẹ̀rù,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má di ẹni tí a kó ṣìbáṣìbo bá.+ 15  Ṣùgbọ́n ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín,+ kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà+ níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù+ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀. 16  Ẹ di ẹ̀rí-ọkàn rere mú,+ pé nínú ohun náà tí a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín, kí ojú lè ti+ àwọn tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà rere yín ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi.+ 17  Nítorí ó sàn láti jìyà nítorí pé ẹ ń ṣe rere,+ bí ìfẹ́ Ọlọ́run bá fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀, ju kí ó jẹ́ nítorí pé ẹ ń ṣe ibi.+ 18  Họ́wù, Kristi pàápàá kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ láìtún kú mọ́ láé,+ olódodo fún àwọn aláìṣòdodo,+ kí ó lè ṣamọ̀nà yín dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ ẹni tí a fi ikú pa nínú ẹran ara,+ ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí.+ 19  Nínú ipò yìí pẹ̀lú, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú ẹ̀wọ̀n,+ 20  àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìgbọràn nígbà kan,+ nígbà tí sùúrù Ọlọ́run+ ń dúró ní àwọn ọjọ́ Nóà, nígbà tí a ń kan ọkọ̀ áàkì lọ́wọ́,+ nínú èyí tí a gbé àwọn ènìyàn díẹ̀ la omi já láìséwu, èyíinì ni, ọkàn mẹ́jọ.+ 21  Èyíinì tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí ni ó ń gbà yín là nísinsìnyí pẹ̀lú,+ èyíinì ni, ìbatisí, (kì í ṣe mímú èérí ara kúrò, bí kò ṣe ìbéèrè tí a ṣe sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún ẹ̀rí-ọkàn rere,)+ nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi.+ 22  Ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ nítorí tí ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ọ̀run; a sì fi àwọn áńgẹ́lì+ àti àwọn aláṣẹ àti àwọn agbára sábẹ́ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé