Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Pétérù 2:1-25

2  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ẹ mú gbogbo ìwà búburú kúrò+ àti gbogbo ìtànjẹ àti àgàbàgebè àti ìlara àti gbogbo onírúurú ìsọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,+  àti pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí,+ ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà+ tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà,+  kìkì bí ẹ bá ti tọ́ ọ wò pé onínúrere ni Olúwa.+  Ní wíwá sọ́dọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sọ́dọ̀ òkúta ààyè,+ tí a kọ̀ tì,+ òtítọ́ ni, láti ọwọ́ ènìyàn,+ ṣùgbọ́n àyànfẹ́, tí ó ṣe iyebíye lọ́dọ̀ Ọlọ́run,+  ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí àwọn òkúta ààyè ni a ń gbé ró gẹ́gẹ́ bí ilé ti ẹ̀mí+ fún ète iṣẹ́ àlùfáà mímọ́, láti máa rú àwọn ẹbọ ti ẹ̀mí+ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi.+  Nítorí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ pé: “Wò ó! Èmi yóò fi òkúta kan lélẹ̀ ní Síónì, àyànfẹ́, òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé, tí ó ṣe iyebíye; kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ tí yóò wá sí ìjákulẹ̀ lọ́nàkọnà.”+  Nítorí náà, ẹ̀yin ni òun ṣe iyebíye fún, nítorí tí ẹ jẹ́ onígbàgbọ́; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà gbọ́, “òkúta kan náà gan-an tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì+ ti di olórí igun ilé,”+  àti “òkúta ìkọ̀sẹ̀ àti àpáta ràbàtà ìdìgbòlù.”+ Àwọn wọ̀nyí ń kọsẹ̀ nítorí tí wọ́n jẹ́ aláìgbọràn sí ọ̀rọ̀ náà. Fún ète yìí gan-an ni a ṣe yàn wọ́n kalẹ̀ pẹ̀lú.+  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ “ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́,+ àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní,+ kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá”+ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.+ 10  Nítorí ẹ kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run;+ ẹ̀yin ni àwọn tí a kò ti fi àánú hàn sí tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ àwọn tí a ti fi àánú hàn sí.+ 11  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo gbà yín níyànjú gẹ́gẹ́ bí àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀+ láti máa ta kété sí àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara,+ tí í ṣe àwọn ohun náà gan-an tí ń bá ìforígbárí nìṣó lòdì sí ọkàn.+ 12  Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà+ tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.+ 13  Nítorí Olúwa, ẹ fi ara yín sábẹ́+ gbogbo ohun tí ẹ̀dá ènìyàn ṣẹ̀dá:+ yálà sábẹ́ ọba+ gẹ́gẹ́ bí onípò gíga 14  tàbí sábẹ́ àwọn gómìnà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó rán láti fi ìyà jẹ àwọn aṣebi ṣùgbọ́n láti yin àwọn olùṣe rere.+ 15  Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, pé nípa ṣíṣe rere kí ẹ lè dí ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan mọ́ àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú lẹ́nu.+ 16  Ẹ wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni òmìnira,+ síbẹ̀ kí ẹ di òmìnira yín mú, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí bojúbojú fún ìwà búburú,+ bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọ́run.+ 17  Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo,+ ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará,+ ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run,+ ẹ máa fi ọlá fún ọba.+ 18  Kí àwọn ìránṣẹ́ ilé wà ní ìtẹríba+ fún àwọn olúwa wọn pẹ̀lú gbogbo ìbẹ̀rù yíyẹ,+ kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti afòyebánilò nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ó ṣòro láti tẹ́ lọ́rùn pẹ̀lú. 19  Nítorí bí ẹnì kan, nítorí ẹ̀rí-ọkàn sí Ọlọ́run, bá ní àmúmọ́ra lábẹ́ àwọn ohun tí ń kó ẹ̀dùn-ọkàn báni, tí ó sì jìyà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.+ 20  Nítorí iyì wo ni ó wà nínú rẹ̀ bí ẹ bá fara dà á nígbà tí ẹ ń dẹ́ṣẹ̀, tí a sì ń gbá yín lábàrá?+ Ṣùgbọ́n bí ẹ bá fara dà á nígbà tí ẹ bá ń ṣe rere, tí ẹ sì ń jìyà,+ èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ 21  Ní ti tòótọ́, ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín,+ ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.+ 22  Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan,+ bẹ́ẹ̀ ni a kò rí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.+ 23  Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀,+ kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà.+ Nígbà tí ó ń jìyà,+ kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni+ tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo. 24  Òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀+ wa lórí òpó igi,+ kí a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀,+ kí a sì wà láàyè sí òdodo. Àti pé “nípa ìnà rẹ̀ ni a mú yín lára dá.”+ 25  Nítorí tẹ́lẹ̀ rí, ẹ dà bí àwọn àgùntàn, tí ń ṣáko lọ;+ ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ ti padà sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn+ àti alábòójútó ọkàn yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé