Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Pétérù 1:1-25

1  Pétérù, àpọ́sítélì+ Jésù Kristi, sí àwọn olùgbé fún ìgbà díẹ̀+ tí wọ́n tú ká káàkiri+ ní Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà,+ Éṣíà, àti Bítíníà, sí àwọn ẹni tí a yàn+  ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba,+ pẹ̀lú ìsọdimímọ́ nípa ẹ̀mí,+ fún ète jíjẹ́ onígbọràn wọn àti fífi ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi+ wọ́n+ wọn: Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà pọ̀ sí i fún yín.+  Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi,+ nítorí ní ìbámu pẹ̀lú àánú ńlá rẹ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun+ sí ìrètí tí ó wà láàyè+ nípasẹ̀ àjíǹde+ Jésù Kristi kúrò nínú òkú,  sí ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá.+ A fi í pa mọ́ ní ọ̀run de ẹ̀yin,+  tí agbára Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ṣọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́+ fún ìgbàlà+ kan tí a múra tán láti ṣí payá+ ní sáà àkókò ìkẹyìn.+  Nínú òtítọ́ yìí ni ẹ̀yin ń yọ̀ gidigidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nísinsìnyí, bí ó bá gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá yín,+  kí ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín tí a ti dán wò,+ tí ó níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà tí ń ṣègbé láìka fífi tí a fi iná dá an wò sí,+ lè jẹ́ èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá+ Jésù Kristi.  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i sójú nísinsìnyí, síbẹ̀ ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, ẹ sì ń yọ̀ gidigidi pẹ̀lú ìdùnnú aláìṣeé-fẹnusọ àti ológo,  bí ẹ ti ń rí òpin ìgbàgbọ́ yín gbà, ìgbàlà ọkàn yín.+ 10  Ní ti ìgbàlà yìí gan-an, ìwádìí aláápọn àti ìwákáàkiri àfẹ̀sọ̀ṣe+ ni àwọn wòlíì ṣe, àwọn tí wọ́n ti sọ tẹ́lẹ̀+ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi lélẹ̀ lọ́tọ̀ fún yín.+ 11  Wọ́n ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àyẹ̀wò nípa àsìkò+ náà gan-an tàbí irú àsìkò tí ẹ̀mí+ tí ń bẹ nínú wọn tọ́ka sí ní ti Kristi+ nígbà tí ó ń jẹ́rìí ṣáájú nípa àwọn ìjìyà fún Kristi+ àti nípa àwọn ògo+ tí yóò tẹ̀ lé ìwọ̀nyí. 12  A ṣí i payá fún wọn pé, kì í ṣe fún àwọn fúnra wọn,+ bí kò ṣe fún yín, ni wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ àwọn ohun tí a ti kéde+ fún yín nísinsìnyí nípasẹ̀ àwọn tí ó ti polongo ìhìn rere fún yín pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́+ tí a rán jáde láti ọ̀run. Nǹkan wọ̀nyí gan-an ni àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wò ní àwòfín.+ 13  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ mú èrò inú yín gbára dì fún ìgbòkègbodò,+ ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré;+ ẹ gbé ìrètí yín ka inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí,+ èyí tí a óò mú wá fún yín nígbà ìṣípayá+ Jésù Kristi. 14  Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà+ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí nínú àìmọ̀kan yín, 15  ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín,+ 16  nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.”+ 17  Síwájú sí i, bí ẹ bá ń ké pe Baba tí ń ṣèdájọ́ láìṣe ojúsàájú+ ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ olúkúlùkù, ẹ hùwà pẹ̀lú ìbẹ̀rù+ nígbà tí ẹ ń ṣe àtìpó.+ 18  Nítorí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí ó lè díbàjẹ́,+ pẹ̀lú fàdákà tàbí wúrà, ni a fi dá yín nídè+ kúrò nínú ọ̀nà ìwà yín aláìléso, tí ẹ gbà nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ láti ọwọ́ àwọn baba ńlá yín. 19  Ṣùgbọ́n ó jẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye,+ bí ti ọ̀dọ́ àgùntàn aláìlábààwọ́n+ àti aláìléèérí, àní ti Kristi.+ 20  Lóòótọ́, a mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé,+ ṣùgbọ́n a fi í hàn kedere ní òpin àwọn àkókò nítorí ẹ̀yin+ 21  tí ẹ tipasẹ̀ rẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,+ ẹni tí ó gbé e dìde kúrò nínú òkú,+ tí ó sì fún un ní ògo;+ kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà nínú Ọlọ́run.+ 22  Nísinsìnyí tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ gaara+ nípa ìgbọràn yín sí òtítọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni ará+ tí kò ní àgàbàgebè gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.+ 23  Nítorí tí a ti fún yín ní ìbí tuntun,+ kì í ṣe nípasẹ̀ irú-ọmọ+ tí ó lè díbàjẹ́,+ bí kò ṣe nípasẹ̀ èyí tí kò lè díbàjẹ́,+ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè,+ tí ó sì wà pẹ́ títí.+ 24  Nítorí “gbogbo ẹran ara dà bí koríko, gbogbo ògo rẹ̀ sì dà bí ìtànná koríko;+ koríko a di rírọ, òdòdó a sì rẹ̀ dànù,+ 25  ṣùgbọ́n àsọjáde Jèhófà wà títí láé.”+ Tóò, èyí ni “àsọjáde”+ náà, tí a ti polongo+ fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé