Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 9:1-27

9  Èmi kò ha lómìnira bí?+ Èmi kì í ha ṣe àpọ́sítélì bí?+ Èmi kò ha ti rí Jésù Olúwa wa bí?+ Ẹ̀yin ha kọ́ ni iṣẹ́ mi nínú Olúwa?  Bí èmi kì í bá ṣe àpọ́sítélì sí àwọn ẹlòmíràn, ó dájú hán-ún pé mo jẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ẹ̀yin, nítorí ẹ̀yin ni èdìdì tí ń fìdí òtítọ́ jíjẹ́ àpọ́sítélì mi múlẹ̀+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.  Ìgbèjà mi sí àwọn tí ń wádìí mi wò nìyí:+  Àwa ní ọlá àṣẹ láti jẹ+ àti láti mu, àbí a kò ní?  Àwa ní ọlá àṣẹ láti máa mú arábìnrin káàkiri gẹ́gẹ́ bí aya,+ àní gẹ́gẹ́ bí àwọn àpọ́sítélì yòókù àti àwọn arákùnrin Olúwa+ àti Kéfà,+ àbí a kò ní?  Àbí kìkì Bánábà+ àti èmi ni kò ní ọlá àṣẹ láti fà sẹ́yìn kúrò nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́?+  Ta ni ẹni tí ó jẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun ní ìnáwó ara rẹ̀? Ta ní ń gbin ọgbà àjàrà tí kì í sì í jẹ nínú èso rẹ̀?+ Àbí ta ní ń ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo ẹran tí kì í sì í jẹ lára wàrà agbo ẹran náà?+  Èmi ha ń sọ nǹkan wọ̀nyí nípasẹ̀ àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n ti ẹ̀dá ènìyàn bí?+ Àbí Òfin+ pẹ̀lú kò ha sọ nǹkan wọ̀nyí?  Nítorí nínú òfin Mósè, a kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dí akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí ó bá ń pa ọkà.”+ Ṣé àwọn akọ màlúù ni Ọlọ́run ń bìkítà fún? 10  Tàbí ó ha jẹ́ pé látòkè délẹ̀ nítorí tiwa ni ó ṣe sọ ọ́? Ní ti gidi, nítorí tiwa ni a ṣe kọ̀wé rẹ̀,+ nítorí ẹni tí ń túlẹ̀ yẹ kí ó túlẹ̀ ní ìrètí, ẹni tí ó sì ń pakà yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìrètí jíjẹ́ alábàápín.+ 11  Bí àwa bá ti fúnrúgbìn àwọn ohun ti ẹ̀mí+ fún yín, ó ha jẹ́ nǹkan bàbàrà bí àwa yóò bá ká àwọn nǹkan tí ó wà fún ara láti ọ̀dọ̀ yín?+ 12  Bí àwọn ènìyàn mìíràn bá ṣalábàápín ọlá àṣẹ yìí lórí yín,+ àwa kò ha ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́pọ̀lọpọ̀? Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwa kò tíì lo ọlá àṣẹ yìí,+ ṣùgbọ́n a ń mú ohun gbogbo mọ́ra, kí a má bàa ṣe ìdílọ́wọ́ kankan fún ìhìn rere+ nípa Kristi. 13  Ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tí ń ṣe iṣẹ́ ọlọ́wọ̀ a máa jẹ+ àwọn nǹkan tẹ́ńpìlì, àwọn tí wọ́n sì máa ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́+ nígbà gbogbo nídìí pẹpẹ ní ìpín kan fún ara wọn pẹ̀lú pẹpẹ? 14  Lọ́nà yìí, pẹ̀lú, Olúwa fàṣẹ lélẹ̀+ fún àwọn tí ń pòkìkí ìhìn rere láti máa wà láàyè nípasẹ̀ ìhìn rere.+ 15  Ṣùgbọ́n èmi kò tíì lo ẹyọ kan ṣoṣo nínú ìpèsè wọ̀nyí.+ Ní tòótọ́, èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí kí ó bàa lè rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn tèmi, nítorí yóò sàn fún mi láti kú—kò sí ènìyàn kankan tí yóò sọ ìdí tí mo ní fún ṣíṣògo+ di aláìjámọ́ nǹkan kan! 16  Wàyí o, bí mo bá ń polongo ìhìn rere,+ kì í ṣe ìdí kankan fún mi láti ṣògo, nítorí àìgbọ́dọ̀máṣe+ wà lórí mi. Ní ti gidi, mo gbé+ bí èmi kò bá polongo ìhìn rere! 17  Bí mo bá ń ṣe èyí tinútinú,+ mo ní èrè;+ ṣùgbọ́n bí mo bá ń ṣe é ní ìlòdìsí ohun tí mo fẹ́, síbẹ̀síbẹ̀ mo ní iṣẹ́ ìríjú+ kan tí a fi sí ìkáwọ́ mi. 18  Kí wá ni èrè mi? Pé bí mo ti ń polongo ìhìn rere kí n lè mú ìhìn rere wá láìgba owó,+ kí n má bàa lo ọlá àṣẹ mi nínú ìhìn rere ní ìlòkúlò. 19  Nítorí, bí mo tilẹ̀ wà lómìnira lọ́wọ́ gbogbo ènìyàn, mo ti fi ara mi ṣe ẹrú+ fún gbogbo ènìyàn, kí n lè jèrè+ àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ. 20  Àti nítorí náà, fún àwọn Júù mo dà bí Júù,+ kí n lè jèrè àwọn Júù; fún àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin mo dà bí ẹni tí ń bẹ lábẹ́ òfin,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi kò sí lábẹ́ òfin,+ kí n lè jèrè àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin. 21  Fún àwọn tí wọ́n wà láìní òfin+ mo dà bí aláìní òfin,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò wà láìní òfin sí Ọlọ́run ṣùgbọ́n lábẹ́ òfin+ sí Kristi,+ kí n lè jèrè àwọn tí wọ́n wà láìní òfin. 22  Fún àwọn aláìlera mo di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera.+ Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo,+ kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là. 23  Ṣùgbọ́n mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín+ nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. 24  Ẹ kò ha mọ̀ pé gbogbo àwọn sárésáré+ nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà?+ Ẹ sáré+ ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́.+ 25  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, olúkúlùkù ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu+ nínú ohun gbogbo. Wàyí o, dájúdájú, wọ́n ń ṣe é kí wọ́n lè gba adé tí ó lè díbàjẹ́,+ ṣùgbọ́n àwa kí a lè gba èyí tí kò lè díbàjẹ́.+ 26  Nítorí náà, bí mo ti ń sáré+ kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́;+ 27  ṣùgbọ́n mo ń lu ara+ mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà+ lọ́nà kan ṣáá.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé