Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 8:1-13

8  Wàyí o, ní ti àwọn oúnjẹ tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà:+ a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀.+ Ìmọ̀ a máa wú fùkẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa gbéni ró.+  Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ti ní ìmọ̀ ohun kan,+ síbẹ̀ kò tíì mọ̀ ọ́n gan-an bí ó ti yẹ kí ó mọ̀ ọ́n.+  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,+ ẹni yìí ni ó mọ̀.+  Wàyí o, ní ti jíjẹ+ àwọn oúnjẹ tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà, àwa mọ̀ pé òrìṣà kò jámọ́ nǹkan kan+ nínú ayé, àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo.+  Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí a ń pè ní “ọlọ́run”+ wà, yálà ní ọ̀run+ tàbí lórí ilẹ̀ ayé,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” àti ọ̀pọ̀ “olúwa”+ ti wà,  ní ti gidi, fún àwa Ọlọ́run+ kan ní ń bẹ Baba,+ láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ohun gbogbo ti wá, àti àwa fún un;+ Olúwa+ kan ni ó sì ń bẹ, Jésù Kristi,+ nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo fi wà,+ àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ yìí kò sí nínú gbogbo ènìyàn;+ ṣùgbọ́n àwọn kan, tí òrìṣà ti mọ́ lára títí di ìsinsìnyí, ń jẹ oúnjẹ gẹ́gẹ́ bí ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà,+ a sì sọ ẹ̀rí-ọkàn wọn, tí ó jẹ́ aláìlera, di ẹlẹ́gbin.+  Ṣùgbọ́n oúnjẹ kọ́ ni yóò mú kí a ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run;+ bí a kò bá jẹun, àwa kò kùnà láti dé ojú ìwọ̀n, bí a bá sì jẹun, àwa kò gba ìyìn kankan fún ara wa.+  Ṣùgbọ́n ẹ máa ṣọ́ra kí ọlá àṣẹ yín yìí, lọ́nà kan ṣáá, má di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tí ó jẹ́ aláìlera.+ 10  Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá rí ìwọ, tí o ní ìmọ̀, tí o rọ̀gbọ̀kú nídìí oúnjẹ nínú tẹ́ńpìlì òrìṣà, a kì yóò ha sún ẹ̀rí-ọkàn ẹni yẹn tí ó jẹ́ aláìlera dé àyè jíjẹ àwọn oúnjẹ tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà?+ 11  Ní ti gidi, nípasẹ̀ ìmọ̀ rẹ, ẹni tí ó jẹ́ aláìlera ni a ń ṣe lọ́ṣẹ́, arákùnrin rẹ ẹni tí Kristi tìtorí rẹ̀ kú.+ 12  Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá ń tipa báyìí ṣẹ̀ sí àwọn arákùnrin yín, tí ẹ sì ṣá ẹ̀rí-ọkàn+ wọn tí ó jẹ́ aláìlera lọ́gbẹ́, ẹ ń ṣẹ̀ sí Kristi. 13  Nítorí náà, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀,+ dájúdájú, èmi kì yóò tún jẹ ẹran láé, kí n má bàa mú arákùnrin mi kọsẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé