Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 7:1-40

7  Wàyí o, ní ti àwọn ohun tí ẹ kọ̀wé nípa rẹ̀, ó dára kí ọkùnrin má ṣe fọwọ́ kan+ obìnrin;  síbẹ̀, nítorí ìgbòdekan àgbèrè,+ kí olúkúlùkù ọkùnrin ní aya tirẹ̀,+ kí olúkúlùkù obìnrin sì ní ọkọ tirẹ̀.  Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un;+ ṣùgbọ́n kí aya pẹ̀lú máa ṣe bákan náà fún ọkọ rẹ̀.+  Aya kì í lo ọlá àṣẹ lórí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ a máa ṣe bẹ́ẹ̀;+ bákan náà, pẹ̀lú, ọkọ kì í lo ọlá àṣẹ lórí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n aya rẹ̀ a máa ṣe bẹ́ẹ̀.+  Ẹ má ṣe máa fi du ara yín lẹ́nì kìíní-kejì,+ àyàfi nípasẹ̀ àjọgbà fún àkókò tí a yàn kalẹ̀,+ kí ẹ lè ya àkókò sọ́tọ̀ fún àdúrà, kí ẹ sì tún lè jùmọ̀ wà pa pọ̀, kí Sátánì má bàa máa dẹ yín wò+ nítorí àìlèmáradúró+ yín.  Bí ó ti wù kí ó rí, èmi sọ èyí lọ́nà ìyọ̀ǹda bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀,+ kì í ṣe lọ́nà àṣẹ.+  Ṣùgbọ́n ì bá wù mí kí gbogbo ènìyàn rí bí èmi fúnra mi ti rí.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù ní ẹ̀bùn+ tirẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọ̀kan lọ́nà yìí, òmíràn lọ́nà yẹn.  Wàyí o, èmi sọ fún àwọn ènìyàn tí kò gbéyàwó+ àti àwọn opó pé, ó dára kí wọ́n wà, àní bí èmi ti wà.+  Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá ní ìkóra-ẹni-níjàánu,+ kí wọ́n gbéyàwó, nítorí ó sàn láti gbéyàwó+ ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara ẹni gbiná.+ 10  Àwọn tí wọ́n gbéyàwó ni mo fún ní àwọn ìtọ́ni, síbẹ̀ kì í ṣe èmi bí kò ṣe Olúwa,+ pé kí aya má lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀;+ 11  ṣùgbọ́n bí ó bá lọ ní ti gidi, kí ó wà láìlọ́kọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀; kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀. 12  Ṣùgbọ́n àwọn yòókù ni èmi sọ fún, bẹ́ẹ̀ ni, èmi, kì í ṣe Olúwa+ pé: Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi obìnrin náà sílẹ̀; 13  àti obìnrin tí ó ní ọkọ tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí ọkùnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. 14  Nítorí ọkọ tí kò gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀, aya tí kò sì gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú arákùnrin náà; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ọmọ yín ì bá jẹ́ aláìmọ́+ ní ti gidi, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n jẹ́ mímọ́.+ 15  Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò gbà gbọ́ náà bá tẹ̀ síwájú láti lọ,+ jẹ́ kí ó lọ; arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan kò sí ní ipò ìsìnrú lábẹ́ irúfẹ́ àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pè yín sí àlàáfíà.+ 16  Nítorí, aya, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba ọkọ rẹ là?+ Tàbí, ọkọ, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba aya rẹ là?+ 17  Kìkì pé, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti fi ìpín+ fún olúkúlùkù, kí olúkúlùkù máa rìn bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pè é.+ Báyìí ni mo sì fàṣẹ lélẹ̀+ nínú gbogbo ìjọ. 18  A ha pe ọkùnrin èyíkéyìí nígbà tí ó ti dádọ̀dọ́?+ Kí ó má di aláìdádọ̀dọ́. A ha ti pe ọkùnrin èyíkéyìí nínú àìdádọ̀dọ́?+ Kí ó má ṣe dádọ̀dọ́.+ 19  Ìdádọ̀dọ́+ kò túmọ̀ sí nǹkan kan, àìdádọ̀dọ́+ kò sì túmọ̀ sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ṣe bẹ́ẹ̀.+ 20  Nínú ipò yòówù tí a bá ti pe olúkúlùkù,+ kí ó dúró nínú rẹ̀.+ 21  A ha pè ọ́ nígbà tí o jẹ́ ẹrú? Má ṣe jẹ́ kí ó kó ìdààmú-ọkàn bá ọ;+ ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sì tún lè di òmìnira, kúkú yára mú àǹfààní náà lò. 22  Nítorí ẹnikẹ́ni nínú Olúwa tí a pè nígbà tí ó jẹ́ ẹrú jẹ́ ẹni àsọdòmìnira Olúwa;+ bákan náà, ẹni tí a pè nígbà tí ó jẹ́ òmìnira+ jẹ́ ẹrú+ Kristi. 23  A rà yín ní iye kan;+ ẹ dẹ́kun dídi ẹrú+ ènìyàn. 24  Ní ipò+ yòówù tí a bá ti pe olúkúlùkù, ẹ̀yin ará, kí ó dúró nínú rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. 25  Wàyí o, ní ti àwọn wúńdíá, èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo sọ èrò+ mi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí Olúwa+ ti fi àánú hàn sí láti jẹ́ olùṣòtítọ́.+ 26  Nítorí náà, mo rò pé èyí dára nítorí ipò ìṣòro tí ń bẹ níhìn-ín pẹ̀lú wa, pé ó dára fún ènìyàn láti máa bá a lọ bí ó ti wà.+ 27  A ha dè ọ́ mọ́ aya bí?+ Dẹ́kun wíwá ìtúsílẹ̀.+ A ha tú ọ kúrò lọ́dọ̀ aya bí? Dẹ́kun wíwá aya. 28  Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá tilẹ̀ gbéyàwó, ìwọ kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.+ Bí wúńdíá ènìyàn kan bá sì gbéyàwó, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.+ Ṣùgbọ́n èmi ń dá yín sí. 29  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí ni mo sọ, ẹ̀yin ará, pé àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.+ Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní,+ 30  àti pẹ̀lú kí àwọn tí ń sunkún dà bí àwọn tí kò sunkún, àti àwọn tí ń yọ̀ bí àwọn tí kò yọ̀, àti àwọn tí ń rà bí àwọn tí kò ní, 31  àti àwọn tí ń lo ayé+ bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.+ 32  Ní tòótọ́, mo fẹ́ kí ẹ wà láìní àníyàn.+ Ọkùnrin tí kò gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà Olúwa. 33  Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó gbéyàwó ń ṣàníyàn+ fún àwọn ohun ti ayé, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀,+ 34  ó sì pínyà lọ́kàn. Síwájú sí i, obìnrin tí kò lọ́kọ, àti wúńdíá, ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa,+ pé kí òun lè jẹ́ mímọ́ nínú ara rẹ̀ àti nínú ẹ̀mí rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, obìnrin tí a gbé níyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ọkọ rẹ̀.+ 35  Ṣùgbọ́n èyí ni èmi ń sọ fún àǹfààní ara yín, kì í ṣe kí n lè dẹ ojóbó mú yín, ṣùgbọ́n láti sún yín sí ohun tí ó yẹ+ àti èyí tí ó túmọ̀ sí ṣíṣiṣẹ́sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn.+ 36  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń hùwà lọ́nà àìbẹ́tọ̀ọ́mu sí ipò wúńdíá òun,+ bí onítọ̀hún bá ti ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe, tí èyí sì jẹ́ ọ̀nà tí ó yẹ kí ó gbà ṣẹlẹ̀, kí ó ṣe ohun tí ó fẹ́; kò dẹ́ṣẹ̀. Kí wọ́n gbéyàwó.+ 37  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu tán nínú ọkàn-àyà rẹ̀, tí kò ní àìgbọ́dọ̀máṣe kankan, ṣùgbọ́n tí ó ní ọlá àṣẹ lórí ohun tí ó fẹ́, tí ó sì ti ṣe ìpinnu yìí nínú ọkàn-àyà ara rẹ̀, láti pa ipò wúńdíá tirẹ̀ mọ́, òun yóò ṣe dáadáa.+ 38  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹni náà tí ó fi ipò wúńdíá rẹ̀ fúnni nínú ìgbéyàwó ṣe dáadáa,+ ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi í fúnni nínú ìgbéyàwó yóò ṣe dáadáa jù.+ 39  Aya ni a dè ní gbogbo àkókò tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè.+ Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá sùn nínú ikú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹni tí ó bá fẹ́, kìkì nínú Olúwa.+ 40  Ṣùgbọ́n ó láyọ̀ jù bí ó bá dúró bí ó ti wà,+ gẹ́gẹ́ bí èrò mi. Dájúdájú, mo rò pé èmi náà ní ẹ̀mí Ọlọ́run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé