Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kọ́ríńtì 6:1-20

6  Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó ní ẹjọ́+ lòdì sí ẹnì kejì ha gbójúgbóyà láti lọ sí kóòtù níwájú àwọn aláìṣòdodo,+ tí kì í sì í ṣe níwájú àwọn ẹni mímọ́?+  Tàbí ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣèdájọ́+ ayé?+ Bí ó bá sì jẹ́ pé ẹ̀yin ni yóò ṣèdájọ́ ayé, ẹ ha jẹ́ aláìyẹ láti ṣe ìgbẹ́jọ́ àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan rárá?+  Ẹ kò ha mọ̀ pé àwa ni yóò ṣèdájọ́ àwọn áńgẹ́lì?+ Èé ṣe tí kò fi wá rí bẹ́ẹ̀ nípa àwọn ọ̀ràn ti ìgbésí ayé yìí?  Nígbà náà, bí ẹ bá ní àwọn ọ̀ràn ti ìgbésí ayé yìí fún ìgbẹ́jọ́,+ ó ha jẹ́ àwọn ọkùnrin tí a ń fojú tẹ́ńbẹ́lú nínú ìjọ ni ẹ ń fi ṣe onídàájọ́?+  Mo ń sọ̀rọ̀ láti sún yín sí ìtìjú.+ Òótọ́ ha ni pé kò sí ẹyọ ọlọ́gbọ́n+ kan láàárín yín tí ó lè ṣèdájọ́ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀,  ṣùgbọ́n arákùnrin ń mú arákùnrin lọ sí kóòtù, ìyẹn sì jẹ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́?+  Ní ti gidi, nígbà náà, gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀, ó túmọ̀ sí ìpaláyò fún yín pé ẹ ń pe ara yín lẹ́jọ́.+ Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a ṣe àìtọ́ sí ẹ̀yin fúnra yín?+ Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a lu ẹ̀yin fúnra yín ní jìbìtì?+  Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ ń ṣe àìtọ́, ẹ sì ń lu jìbìtì, ó tún wá jẹ́ sí àwọn arákùnrin yín.+  Kínla! Ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run?+ Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè,+ tàbí àwọn abọ̀rìṣà,+ tàbí àwọn panṣágà,+ tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá,+ tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀,+ 10  tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra,+ tàbí àwọn ọ̀mùtípara,+ tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.+ 11  Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn.+ Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́,+ ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́,+ ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo+ ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi+ àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.+ 12  Ohun gbogbo ni ó bófin mu fún mi; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní àǹfààní.+ Ohun gbogbo ni ó bófin mu+ fún mi; ṣùgbọ́n dájúdájú èmi kì yóò jẹ́ kí ohunkóhun mú mi wá sábẹ́ ọlá àṣẹ.+ 13  Àwọn oúnjẹ fún ikùn, àti ikùn fún àwọn oúnjẹ;+ ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò sọ àti òun àti àwọn di asán.+ Wàyí o, ara kò wà fún àgbèrè, bí kò ṣe fún Olúwa;+ àti Olúwa fún ara.+ 14  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbé Olúwa dìde,+ yóò sì gbé wa dìde kúrò nínú ikú+ nípasẹ̀ agbára rẹ̀.+ 15  Ẹ kò ha mọ̀ pé ẹ̀yà ara+ Kristi+ ni ara yín? Nígbà náà, ṣé kí n mú ẹ̀yà ara Kristi kúrò, kí n sì sọ ọ́ di ẹ̀yà ara aṣẹ́wó?+ Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! 16  Kínla! Ẹ kò ha mọ̀ pé ẹni tí ó bá dà pọ̀ mọ́ aṣẹ́wó jẹ́ ara kan? Nítorí, “Àwọn méjèèjì,” ni òun wí, “yóò di ara kan.”+ 17  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá dà pọ̀ mọ́ Olúwa jẹ́ ẹ̀mí+ kan.+ 18  Ẹ máa sá fún àgbèrè.+ Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tí ènìyàn lè dá wà lóde ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.+ 19  Kínla! Ẹ kò ha mọ̀ pé ara yín ni tẹ́ńpìlì+ ẹ̀mí mímọ́ tí ń bẹ nínú yín,+ èyí tí ẹ gbà láti ọwọ́ Ọlọ́run? Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ kì í ṣe ti ara yín,+ 20  nítorí a ti rà yín ní iye kan.+ Láìkùnà, ẹ yin Ọlọ́run lógo+ nínú ara+ yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé