Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 5:1-13

5  Ní ti gidi, àgbèrè+ ni a ròyìn láàárín yín, irúfẹ́ àgbèrè tí kò tilẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé ọkùnrin kan ní aya kan tí ó jẹ́ ti baba rẹ̀.+  Ẹ̀yin ha sì ń wú fùkẹ̀,+ ẹ kò ha sì kúkú ṣọ̀fọ̀,+ kí a lè mú ọkùnrin tí ó ṣe iṣẹ́ yìí kúrò ní àárín yín?+  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò sí lọ́dọ̀ yín nípa ti ara ṣùgbọ́n tí mo wà lọ́dọ̀ yín nípa ti ẹ̀mí, èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan dájúdájú ti ṣèdájọ́+ ọkùnrin tí ó ti ṣiṣẹ́ ní irúfẹ́ ọ̀nà yìí, bí ẹni pé mo wà lọ́dọ̀ yín,  pé ní orúkọ Olúwa wa Jésù, nígbà tí ẹ bá kóra jọpọ̀, àti ẹ̀mí mi pẹ̀lú agbára Olúwa wa Jésù,+  ẹ fi irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ lé Sátánì+ lọ́wọ́ fún ìparun ẹran ara, kí a bàa lè gba ẹ̀mí+ là ní ọjọ́ Olúwa.+  Ìdí fún ìṣògo+ yín kò dára rárá. Ẹ kò ha mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìṣùpọ̀+ di wíwú?+  Ẹ mú ògbólógbòó ìwúkàrà kúrò, kí ẹ lè jẹ́ ìṣùpọ̀ tuntun,+ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ aláìní amóhunwú. Nítorí, ní tòótọ́, a ti fi Kristi+ ìrékọjá+ wa rúbọ.+  Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a pa àjọyọ̀+ mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ògbólógbòó ìwúkàrà,+ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà+ ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú,+ ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà aláìwú ti òtítọ́ inú àti òtítọ́.+  Nínú lẹ́tà mi, mo kọ̀wé sí yín pé kí ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbèrè, 10  kò túmọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àgbèrè+ ayé yìí+ pátápátá tàbí àwọn oníwọra ènìyàn àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà tàbí àwọn abọ̀rìṣà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ní ti gidi yóò ní láti jáde kúrò nínú ayé.+ 11  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, èmi ń kọ̀wé sí yín pé kí ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀+ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra+ tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara+ tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun. 12  Nítorí kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣèdájọ́ àwọn tí ń bẹ lóde?+ Ẹ kò ha ń ṣèdájọ́ àwọn tí ń bẹ ní inú,+ 13  nígbà tí Ọlọ́run ń ṣèdájọ́ àwọn tí ń bẹ lóde?+ “Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé