Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kọ́ríńtì 3:1-23

3  Àti nítorí náà, ẹ̀yin ará, èmi kò lè bá yín sọ̀rọ̀ bí ẹní ń bá àwọn ènìyàn ti ẹ̀mí+ sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n bí ẹní ń bá àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara sọ̀rọ̀, bí ẹní ń bá àwọn ìkókó+ nínú Kristi sọ̀rọ̀.  Wàrà ni mo fi bọ́ yín, kì í ṣe nǹkan láti jẹ,+ nítorí ní àkókò yẹn, ẹ kò tíì lókun tó. Ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò lókun tó nísinsìnyí,+  nítorí tí ẹ jẹ́ ẹlẹ́ran ara síbẹ̀.+ Nítorí nígbà tí ó jẹ́ pé owú àti gbọ́nmi-si omi-ò-to wà láàárín yín,+ ẹ kò ha jẹ́ ẹlẹ́ran ara, ẹ kò ha sì ń rìn bí ènìyàn?+  Nítorí nígbà tí ẹnì kan wí pé: “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” ṣùgbọ́n òmíràn wí pé: “Èmi ti Àpólò,”+ ẹ kì í ha wulẹ̀ ṣe ènìyàn bí?  Kí wá ni Àpólò+ jẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, kí ni Pọ́ọ̀lù jẹ́? Àwọn òjíṣẹ́+ tí ẹ tipasẹ̀ wọn di onígbàgbọ́, àní gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti yọ̀ǹda fún olúkúlùkù.  Èmi gbìn,+ Àpólò bomi rin,+ ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà;+  tí ó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tí ń gbìn+ ni ó jẹ́ nǹkan kan tàbí ẹni tí ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń mú kí ó dàgbà.+  Wàyí o, ẹni tí ń gbìn àti ẹni tí ń bomi rin jẹ́ ọ̀kan,+ ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò gba èrè tirẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òpò tirẹ̀.+  Nítorí àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.+ Ẹ̀yin jẹ́ pápá Ọlọ́run tí a ń ro lọ́wọ́,+ ilé Ọlọ́run.+ 10  Ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n olùdarí àwọn iṣẹ́, èmi fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ń kọ́lé sórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù máa ṣọ́ bí ó ti ń kọ́lé sórí rẹ̀.+ 11  Nítorí kò sí ènìyàn kankan tí ó lè fi ìpìlẹ̀+ èyíkéyìí mìíràn lélẹ̀ ju ohun tí a ti fi lélẹ̀ lọ, èyí tí í ṣe Jésù Kristi.+ 12  Wàyí o, bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ wúrà, fàdákà, àwọn òkúta ṣíṣeyebíye, àwọn ohun èlò igi, koríko gbígbẹ, àgékù pòròpórò sórí ìpìlẹ̀ náà, 13  iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò fara hàn kedere, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí a óò ṣí i payá nípasẹ̀ iná;+ iná náà fúnra rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀rí irú ohun tí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ hàn. 14  Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó ti kọ́ sórí rẹ̀ bá wà síbẹ̀,+ òun yóò gba èrè;+ 15  bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni a ó gbà là;+ síbẹ̀, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹní la iná já.+ 16  Ṣé ẹ kò mọ̀ pé tẹ́ńpìlì Ọlọ́run+ ni yín, àti pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín?+ 17  Bí ẹnikẹ́ni bá pa tẹ́ńpìlì Ọlọ́run run, Ọlọ́run yóò pa á run;+ nítorí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run jẹ́ mímọ́,+ tẹ́ńpìlì+ tí ẹ̀yin jẹ́.+ 18  Kí ẹnì kankan má ṣe máa sún ara rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀: Bí ẹnikẹ́ni láàárín yín bá rò pé òun jẹ́ ọlọ́gbọ́n+ nínú ètò àwọn nǹkan yìí, kí ó di òmùgọ̀, kí ó bàa lè di ọlọ́gbọ́n.+ 19  Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run;+ nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àlùmọ̀kọ́rọ́yí àwọn fúnra wọn.”+ 20  Àti pẹ̀lú: “Jèhófà mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”+ 21  Nítorí bẹ́ẹ̀, kí ẹnì kankan má ṣe máa ṣògo nínú ènìyàn; nítorí ohun gbogbo jẹ́ tiyín,+ 22  yálà Pọ́ọ̀lù tàbí Àpólò+ tàbí Kéfà tàbí ayé tàbí ìyè tàbí ikú tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀,+ ohun gbogbo jẹ́ tiyín; 23  ẹ̀yin náà, ẹ̀wẹ̀, jẹ́ ti Kristi;+ Kristi, ẹ̀wẹ̀, jẹ́ ti Ọlọ́run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé