Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 2:1-16

2  Àti nítorí náà, nígbà tí mo wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ̀yin ará, èmi kò wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọrégèé+ tàbí ọgbọ́n ní pípolongo àṣírí ọlọ́wọ̀+ Ọlọ́run fún yín.  Nítorí mo pinnu láti má ṣe mọ ohunkóhun láàárín yín àyàfi Jésù Kristi,+ ẹni tí a sì kàn mọ́gi.  Mo sì wá sí ọ̀dọ̀ yín nínú àìlera àti nínú ìbẹ̀rù àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìwárìrì;+  àti ọ̀rọ̀ mi àti ohun tí mo ń wàásù kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ń yíni lérò padà bí kò ṣe pẹ̀lú ìfihàn ẹ̀mí àti agbára,+  kí ìgbàgbọ́ yín má bàa wà nínú ọgbọ́n ènìyàn,+ bí kò ṣe nínú agbára Ọlọ́run.+  Wàyí o, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàárín àwọn tí ó dàgbà dénú,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n+ ti ètò àwọn nǹkan yìí tàbí ti àwọn olùṣàkóso ètò àwọn nǹkan yìí,+ àwọn ẹni tí yóò di asán.+  Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọ́run nínú àṣírí ọlọ́wọ̀ kan,+ ọgbọ́n tí a fi pa mọ́, èyí tí Ọlọ́run ti yàn ṣáájú àwọn ètò+ àwọn nǹkan fún ògo wa.  Kò sí ọ̀kan nínú àwọn olùṣàkóso+ ètò àwọn nǹkan yìí tí ó wá mọ ọgbọ́n yìí,+ nítorí bí wọ́n bá ti mọ̀ ọ́n ni, wọn kì bá kan Olúwa ológo mọ́gi.+  Ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ojú kò tíì rí, etí kò sì tíì gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò tíì rò nínú ọkàn-àyà ènìyàn àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”+ 10  Nítorí àwa ni Ọlọ́run ti ṣí wọn payá+ fún nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀,+ nítorí ẹ̀mí+ ń wá inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀+ Ọlọ́run. 11  Nítorí ta ni láàárín àwọn ènìyàn tí ó mọ àwọn nǹkan ènìyàn bí kò ṣe ẹ̀mí+ ènìyàn, èyí tí ń bẹ nínú rẹ̀? Bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, kò sí ẹni tí ó ti wá mọ àwọn nǹkan ti Ọlọ́run, bí kò ṣe ẹ̀mí+ Ọlọ́run. 12  Wàyí o, kì í ṣe ẹ̀mí+ ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí+ tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí àwa bàa lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere.+ 13  Nǹkan wọ̀nyí ni àwa pẹ̀lú ń sọ, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ọgbọ́n ẹ̀dá ènìyàn,+ bí kò ṣe pẹ̀lú àwọn tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ẹ̀mí,+ bí àwa ti ń mú àwọn nǹkan ti ẹ̀mí pa pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí.+ 14  Ṣùgbọ́n ènìyàn ti ara kì í gba àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run, nítorí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni wọ́n jẹ́ lójú rẹ̀; kò sì lè mọ̀ wọ́n,+ nítorí nípa ti ẹ̀mí ni a ń wádìí wọn wò. 15  Àmọ́ ṣá o, ènìyàn ti ẹ̀mí+ ní tòótọ́ a máa wádìí ohun gbogbo wò, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni ènìyàn èyíkéyìí kì í wádìí wò.+ 16  Nítorí “ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà,+ kí ó lè fún un ní ìtọ́ni?”+ Ṣùgbọ́n àwa ní èrò inú+ ti Kristi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé