Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kọ́ríńtì 16:1-24

16  Wàyí o, ní ti àkójọ+ tí ó wà fún àwọn ẹni mímọ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àṣẹ ìtọ́ni fún àwọn ìjọ Gálátíà,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin tìkára yín ṣe pẹ̀lú.  Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gédégbé ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lè máa láásìkí, kí ó lè jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé, àkójọ kì yóò wáyé nígbà náà.  Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá dé, àwọn ọkùnrin yòówù tí ẹ bá tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà,+ àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò rán láti gbé ẹ̀bùn inú rere yín lọ sí Jerúsálẹ́mù.  Àmọ́ ṣá o, bí ó bá yẹ fún mi láti lọ sí ibẹ̀ pẹ̀lú, wọn yóò pẹ̀lú mi lọ sí ibẹ̀.  Ṣùgbọ́n èmi yóò wá sọ́dọ̀ yín nígbà tí mo bá ti la Makedóníà kọjá, nítorí èmi yóò la Makedóníà+ kọjá;  bóyá èmi yóò sì dúró tàbí kí n tilẹ̀ lo ìgbà òtútù pẹ̀lú yín, kí ẹ lè sìn+ mí díẹ̀ lọ́nà ibi tí mo bá ń lọ.  Nítorí èmi kò fẹ́ rí yín báyìí-báyìí nígbà kíkọjá lọ mi, nítorí mo ní ìrètí láti wà lọ́dọ̀ yín+ fún ìgbà díẹ̀, bí Jèhófà+ bá yọ̀ǹda.+  Ṣùgbọ́n èmi yóò wà ní Éfésù+ títí di ìgbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì;  nítorí ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ni a ti ṣí sílẹ̀ fún mi,+ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ alátakò ní ń bẹ. 10  Bí ó ti wù kí ó rí, bí Tímótì+ bá dé, ẹ rí i pé kò sí ìbẹ̀rù kankan fún un láàárín yín, nítorí ó ń ṣe iṣẹ́ Jèhófà,+ àní gẹ́gẹ́ bí èmi. 11  Nítorí náà, kí ẹnì kankan má ṣe fojú tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀.+ Ẹ sìn ín díẹ̀ dé ọ̀nà ní àlàáfíà, kí ó lè dé ọ̀dọ̀ mi níhìn-ín, nítorí mo ń dúró dè é pẹ̀lú àwọn ará. 12  Wàyí o, ní ti Àpólò+ arákùnrin wa, mo pàrọwà fún un gidigidi láti wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú àwọn ará, síbẹ̀ kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wá nísinsìnyí; ṣùgbọ́n yóò wá nígbà tí àyè bá ṣí sílẹ̀ fún un. 13  Ẹ wà lójúfò,+ ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,+ ẹ máa bá a nìṣó bí ọkùnrin,+ ẹ di alágbára ńlá.+ 14  Kí gbogbo àlámọ̀rí yín máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́.+ 15  Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará: ẹ mọ̀ pé agbo ilé Sítéfánásì ni àkọ́so+ Ákáyà àti pé wọ́n ṣètò ara wọn láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́.+ 16  Kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa tẹrí ba fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ àti fún gbogbo ẹni tí ó bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí ó sì ń ṣe òpò.+ 17  Ṣùgbọ́n mo yọ̀ lórí wíwàníhìn-ín Sítéfánásì+ àti Fọ́túnátù àti Ákáíkọ́sì, nítorí pé wọ́n ti dí àlàfo àìsí níhìn-ín yín. 18  Nítorí wọ́n ti tu ẹ̀mí+ mi àti tiyín lára. Nítorí náà, ẹ máa mọyì irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀.+ 19  Àwọn ìjọ Éṣíà kí yín.+ Ákúílà àti Pírísíkà pa pọ̀ pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ní ilé+ wọn kí yín tinútinú nínú Olúwa. 20  Gbogbo àwọn ará kí yín. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+ 21  Ìkíni ti èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, ní ọwọ́ ara mi.+ 22  Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ni fún Olúwa, kí ó di ẹni ègún.+ Ìwọ Olúwa wa, máa bọ̀!+ 23  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa wà pẹ̀lú yín. 24  Kí ìfẹ́ mi wà pẹ̀lú gbogbo yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé