Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 15:1-58

15  Wàyí o, ẹ̀yin ará, mo sọ ìhìn rere+ náà di mímọ̀ fún yín, èyí tí mo polongo fún yín,+ tí ẹ̀yin pẹ̀lú gbà, nínú èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú dúró,+  nípasẹ̀ èyí tí a tún ń gbà yín là,+ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí mo fi polongo ìhìn rere fún yín, bí ẹ bá ń dì í mú ṣinṣin, àyàfi bí ó bá jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, ẹ di onígbàgbọ́ lásán.+  Nítorí mo fi lé yín lọ́wọ́, lára àwọn ohun àkọ́kọ́, èyíinì tí èmi pẹ̀lú gbà,+ pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́+ ti wí;  àti pé a sin ín,+ bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde+ ní ọjọ́ kẹta+ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́+ ti wí;  àti pé ó fara han Kéfà,+ lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà.+  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, púpọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n ṣì wà títí di ìsinsìnyí,+ ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú.  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jákọ́bù,+ lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì;+  ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn gbogbo rẹ̀, ó fara han èmi+ pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.  Nítorí èmi ni mo kéré jù lọ+ nínú àwọn àpọ́sítélì, èmi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní àpọ́sítélì, nítorí mo ṣe inúnibíni+ sí ìjọ Ọlọ́run. 10  Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run,+ mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ tí ó sì wà fún mi kò já sí asán,+ ṣùgbọ́n mo ṣe òpò púpọ̀ ju gbogbo wọn lọ,+ síbẹ̀ kì í ṣe èmi bí kò ṣe inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi.+ 11  Bí ó ti wù kí ó rí, yálà èmi ni tàbí àwọn, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń wàásù bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ ti gbà gbọ́.+ 12  Wàyí o, bí a bá ń wàásù Kristi pé a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú,+ èé ti rí tí àwọn kan láàárín yín fi ń sọ pé kò sí àjíǹde àwọn òkú?+ 13  Ní tòótọ́, bí kò bá sí àjíǹde àwọn òkú, a jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde.+ 14  Ṣùgbọ́n bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, dájúdájú, asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa.+ 15  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a rí wa pẹ̀lú ní ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run,+ nítorí a ti jẹ́rìí+ lòdì sí Ọlọ́run pé ó gbé Kristi dìde,+ ṣùgbọ́n ẹni tí òun kò gbé dìde bí a kò bá ní gbé àwọn òkú dìde+ ní ti tòótọ́. 16  Nítorí bí a kò bá ní gbé àwọn òkú dìde, a jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde. 17  Síwájú sí i, bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, ìgbàgbọ́ yín jẹ́ aláìwúlò; ẹ ṣì wà nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.+ 18  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní ti tòótọ́, àwọn tí ó sùn nínú ikú ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Kristi ṣègbé.+ 19  Bí ó bá jẹ́ pé nínú ìgbésí ayé yìí nìkan ni a ti ní ìrètí nínú Kristi,+ àwa ni ó yẹ láti káàánú jù lọ nínú gbogbo ènìyàn. 20  Àmọ́ ṣá o, nísinsìnyí a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú,+ àkọ́so+ nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.+ 21  Nítorí níwọ̀n bí ikú+ ti wá nípasẹ̀ ènìyàn kan, àjíǹde+ òkú pẹ̀lú wá nípasẹ̀ ènìyàn kan. 22  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù,+ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.+ 23  Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so,+ lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.+ 24  Lẹ́yìn náà, ni òpin, nígbà tí ó bá fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, nígbà tí ó bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán.+ 25  Nítorí òun gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 26  Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.+ 27  Nítorí Ọlọ́run “fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”+ Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé ‘a ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,’+ ó hàn gbangba pé ó yọ ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.+ 28  Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán,+ nígbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni+ tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.+ 29  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ni àwọn tí a ń batisí fún ète jíjẹ́ òkú yóò ṣe?+ Bí a kò bá ní gbé àwọn òkú dìde rárá,+ èé ṣe tí a fi ń batisí+ wọn pẹ̀lú fún ète jíjẹ́ bẹ́ẹ̀? 30  Èé ṣe tí àwa pẹ̀lú fi ń wà nínú ewu ní gbogbo wákàtí?+ 31  Lójoojúmọ́ ni mo ń dojú kọ ikú.+ Èyí ni èmi ń kín lẹ́yìn nípasẹ̀ ayọ̀ ńláǹlà+ lórí yín, ẹ̀yin ará, èyí tí mo ní nínú Kristi Jésù Olúwa wa. 32  Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, bí mo bá ti bá àwọn ẹranko ẹhànnà jà ní Éfésù,+ ire kí ni ó jẹ́ fún mi? Bí a kò bá ní gbé àwọn òkú dìde, “ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.”+ 33  Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.+ 34  Ẹ jí sí orí pípé+ lọ́nà òdodo, ẹ má sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, nítorí àwọn kan wà láìní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run.+ Mo ń sọ̀rọ̀ láti sún yín sí ìtìjú.+ 35  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹnì kan yóò wí pé: “Báwo ni a ó ṣe gbé àwọn òkú dìde? Bẹ́ẹ̀ ni, irú ara wo ni wọ́n ń gbé bọ̀?”+ 36  Ìwọ aláìlọ́gbọ́n-nínú! Ohun tí o gbìn ni a kò sọ di ààyè láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ kú;+ 37  àti ní ti ohun tí ìwọ gbìn, kì í ṣe ara tí yóò gbèrú ni ìwọ gbìn, bí kò ṣe èkìdá hóró,+ ó lè jẹ́, ti àlìkámà tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ìyókù; 38  ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún un ni ara+ gẹ́gẹ́ bí ó ti wù ú,+ àti fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ara tirẹ̀. 39  Kì í ṣe gbogbo ẹran ara ni ó jẹ́ ẹran ara kan náà, ṣùgbọ́n ọ̀kan wà tí ó jẹ́ ti aráyé, ẹran ara mìíràn sì wà tí ó jẹ́ ti ẹran ọ̀sìn, àti ẹran ara mìíràn ti àwọn ẹyẹ, àti òmíràn ti ẹja.+ 40  Àwọn ara ti ọ̀run+ sì wà, àti àwọn ara ti ilẹ̀ ayé;+ ṣùgbọ́n ògo+ àwọn ara ti ọ̀run jẹ́ oríṣi kan, ti àwọn ara ti ilẹ̀ ayé sì jẹ́ oríṣi ọ̀tọ̀. 41  Ògo ti oòrùn+ jẹ́ oríṣi kan, ògo ti òṣùpá+ sì jẹ́ òmíràn, ògo ti àwọn ìràwọ̀+ sì jẹ́ òmíràn; ní ti tòótọ́, ìràwọ̀ yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ní ògo. 42  Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni àjíǹde àwọn òkú.+ A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́, a sì gbé e dìde ní àìdíbàjẹ́.+ 43  A gbìn ín ní àbùkù,+ a gbé e dìde ní ògo.+ A gbìn ín ní àìlera,+ a gbé e dìde ní agbára.+ 44  A gbìn ín ní ara ìyára,+ a gbé e dìde ní ara ti ẹ̀mí.+ Bí ara ìyára bá wà, èyí ti ẹ̀mí wà pẹ̀lú. 45  A tilẹ̀ ti kọ̀wé rẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé: “Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè ọkàn.”+ Ádámù ìkẹyìn di ẹ̀mí+ tí ń fúnni ní ìyè.+ 46  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ti àkọ́kọ́, kì í ṣe èyí tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ ti ara, lẹ́yìn náà ni èyí tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí.+ 47  Ọkùnrin àkọ́kọ́ jẹ́ láti inú ilẹ̀, ekuru ni a sì fi dá a;+ ọkùnrin kejì jẹ́ láti ọ̀run.+ 48  Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi ekuru+ dá ti jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí a fi ekuru dá jẹ́ pẹ̀lú; àti pé gẹ́gẹ́ bí ẹni ti ọ̀run+ náà ti jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ọ̀run jẹ́ pẹ̀lú.+ 49  Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa sì ti gbé àwòrán+ ẹni tí a fi ekuru dá wọ̀, àwa yóò gbé àwòrán+ ẹni ti ọ̀run wọ̀ pẹ̀lú. 50  Bí ó ti wù kí ó rí, èyí ni mo wí, ẹ̀yin ará, pé ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run,+ bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kì í jogún àìdíbàjẹ́.+ 51  Wò ó! Àṣírí ọlọ́wọ̀ ni mo ń sọ fún yín: Kì í ṣe gbogbo wa ni yóò sùn nínú ikú, ṣùgbọ́n a óò yí gbogbo wa padà,+ 52  ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí+ ìkẹyìn. Nítorí kàkàkí yóò dún, a ó sì gbé àwọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́, a ó sì yí wa padà. 53  Nítorí èyí tí ó lè díbàjẹ́ yìí gbọ́dọ̀ gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀,+ àti èyí tí ó jẹ́ kíkú+ yìí gbọ́dọ̀ gbé àìkú wọ̀. 54  Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí tí ó lè díbàjẹ́ yìí bá gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, tí èyí tí ó jẹ́ kíkú yìí sì gbé àìkú wọ̀, nígbà náà ni àsọjáde náà yóò ṣẹ, èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “A ti gbé ikú+ mì títí láé.”+ 55  “Ikú, ìjagunmólú rẹ dà? Ikú, ìtani rẹ dà?”+ 56  Ìtani+ tí ń mú ikú jáde ni ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n agbára fún ẹ̀ṣẹ̀ ni Òfin.+ 57  Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, nítorí ó ń fún wa ní ìjagunmólú nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi!+ 58  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,+ ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa,+ ní mímọ̀ pé aápọn yín kì í ṣe asán+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé