Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 14:1-40

14  Ẹ máa lépa ìfẹ́, síbẹ̀ ẹ máa fi tìtara-tìtara wá àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí,+ ṣùgbọ́n kí ẹ lè máa sọ tẹ́lẹ̀ ni ó sàn jù.+  Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀, bí kò ṣe Ọlọ́run, nítorí kò sí ẹnì kankan tí ń fetí sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n ó ń sọ àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀+ nípasẹ̀ ẹ̀mí.  Àmọ́ ṣá o, ẹni tí ń sọ tẹ́lẹ̀ ń gbéni ró,+ ó sì ń fúnni ní ìṣírí, ó sì ń tu àwọn ènìyàn nínú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀.  Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì ń gbé ara rẹ̀ ró, ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọ tẹ́lẹ̀ ń gbé ìjọ ró.  Wàyí o, èmi ì bá fẹ́ kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì,+ ṣùgbọ́n kí ẹ máa sọ tẹ́lẹ̀ ni ó wù mí jù.+ Ní tòótọ́, ẹni tí ń sọ tẹ́lẹ̀ tóbi ju ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì,+ àyàfi, bí ó bá jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, ó ń ṣe ìtúmọ̀, kí ìjọ lè rí ìgbéniró gbà.  Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, ẹ̀yin ará, bí mo bá ní láti wá máa bá yín sọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì, rere wo ni èmi yóò ṣe fún yín láìjẹ́ pé mo bá yín sọ̀rọ̀ yálà pẹ̀lú ìṣípayá+ tàbí pẹ̀lú ìmọ̀+ tàbí pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tàbí pẹ̀lú ẹ̀kọ́?  Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, àwọn ohun aláìlẹ́mìí ń mú ìró jáde,+ yálà fèrè tàbí háàpù; láìjẹ́ pé ó fi ìyàtọ̀ sí ìró ohùn, báwo ni a ó ṣe mọ ohun tí a ń fi fèrè tàbí háàpù kọ?  Nítorí lóòótọ́, bí kàkàkí bá mú ìpè tí kò dún ketekete jáde, ta ni yóò gbára dì fún ìjà ogun?+  Lọ́nà kan náà pẹ̀lú, láìjẹ́ pé ẹ sọ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn láti lóye+ jáde nípasẹ̀ ahọ́n, báwo ni a ó ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Ní ti tòótọ́, ẹ óò máa sọ̀rọ̀ sínú afẹ́fẹ́.+ 10  Ó lè jẹ́ pé ọ̀pọ̀ onírúurú ìró ọ̀rọ̀ ní ń bẹ ní ayé, síbẹ̀síbẹ̀, kò sí irú kankan tí kò ní ìtúmọ̀. 11  Nígbà náà, bí èmi kò bá lóye ipá tí ìró ọ̀rọ̀ náà ní, èmi yóò jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè+ sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè sí mi. 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin fúnra yín, níwọ̀n bí ẹ ti fi tìtara-tìtara ní ìfẹ́-ọkàn sí àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí,+ ẹ wá ọ̀nà láti pọ̀ gidigidi nínú wọn fún gbígbé ìjọ ró.+ 13  Nítorí náà, kí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì gbàdúrà kí òun lè ṣe ìtúmọ̀.+ 14  Nítorí bí èmi bá ń gbàdúrà ní ahọ́n àjèjì, ẹ̀bùn ẹ̀mí mi ní ń gbàdúrà,+ ṣùgbọ́n èrò inú mi jẹ́ aláìléso. 15  Kí wá ní ṣíṣe? Ṣe ni èmi yóò fi ẹ̀bùn ẹ̀mí gbàdúrà, ṣùgbọ́n èmi yóò fi èrò inú mi gbàdúrà pẹ̀lú. Ṣe ni èmi yóò fi ẹ̀bùn ẹ̀mí kọrin ìyìn,+ ṣùgbọ́n èmi yóò fi èrò inú+ mi kọrin ìyìn pẹ̀lú. 16  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá fi ẹ̀bùn ẹ̀mí mú ìyìn wá, báwo ni ọkùnrin tí ó wà ní ìjókòó gbáàtúù ènìyàn yóò ṣe sọ pé “Àmín”+ sí ìdúpẹ́ rẹ, níwọ̀n bí kò ti mọ ohun tí ìwọ ń sọ? 17  Ní tòótọ́, ìwọ ń dúpẹ́ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n a kò gbé ẹnì kejì ró.+ 18  Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, èmi ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì púpọ̀ ju gbogbo yín lọ.+ 19  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nínú ìjọ, èmi yóò kúkú fi èrò inú mi sọ̀rọ̀ márùn-ún, kí n lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu fún àwọn ẹlòmíràn ní ìtọ́ni, ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì.+ 20  Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe di ọmọ kéékèèké nínú agbára òye,+ ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ìkókó ní ti ìwà búburú;+ síbẹ̀, ẹ dàgbà di géńdé nínú agbára òye.+ 21  Nínú Òfin, a kọ̀wé rẹ̀ pé: “‘Àwọn ahọ́n àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ètè àjèjì+ ni èmi yóò fi bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀,+ síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò tilẹ̀ ní kọbi ara sí mi,’ ni Jèhófà wí.”+ 22  Nítorí náà, àwọn ahọ́n àjèjì wà fún iṣẹ́ àmì,+ kì í ṣe fún àwọn onígbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́,+ nígbà tí ìsọtẹ́lẹ̀ kò wà fún àwọn aláìgbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn onígbàgbọ́.+ 23  Nítorí náà, bí gbogbo ìjọ bá kóra jọpọ̀ sí ibì kan, tí gbogbo wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì,+ ṣùgbọ́n tí àwọn gbáàtúù ènìyàn tàbí àwọn aláìgbàgbọ́ wọlé wá, wọn kì yóò ha sọ pé orí yín ti dà rú? 24  Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọ tẹ́lẹ̀, tí aláìgbàgbọ́ tàbí gbáàtúù ènìyàn èyíkéyìí sì wọlé wá, gbogbo wọn ni yóò fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà,+ gbogbo wọn ni yóò wádìí rẹ̀ wò fínnífínní; 25  àwọn àṣírí ọkàn-àyà rẹ̀ a di èyí tí ó fara hàn kedere,+ tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi dojú bolẹ̀, tí yóò sì jọ́sìn Ọlọ́run, ní pípolongo pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.”+ 26  Kí wá ní ṣíṣe, ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ bá kóra jọpọ̀, ẹnì kan ní sáàmù, ẹlòmíràn ní ẹ̀kọ́, ẹlòmíràn ní ìṣípayá, ẹlòmíràn ní ahọ́n àjèjì, ẹlòmíràn ní ìtúmọ̀.+ Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ fún ìgbéniró.+ 27  Bí ẹnì kan bá sì ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì, kí a fi mọ sí méjì tàbí mẹ́ta, ó pọ̀ jù lọ, kí ó sì jẹ́ ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé; kí ẹnì kan sì máa ṣe ìtúmọ̀.+ 28  Ṣùgbọ́n bí kò bá sí olùtúmọ̀, kí ó dákẹ́ nínú ìjọ, kí ó sì máa bá ara rẹ̀+ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀. 29  Síwájú sí i, kí wòlíì+ méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, kí àwọn yòókù fi òye mọ ìtúmọ̀ rẹ̀.+ 30  Ṣùgbọ́n bí a bá fi ìṣípayá fún ẹlòmíràn+ nígbà tí ó jókòó níbẹ̀, kí ẹni àkọ́kọ́ dákẹ́. 31  Nítorí gbogbo yín lè sọ tẹ́lẹ̀+ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè kẹ́kọ̀ọ́, kí a sì fún gbogbo yín ní ìṣírí.+ 32  Àwọn wòlíì sì níláti ṣàkóso àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí àwọn wòlíì. 33  Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu,+ bí kò ṣe ti àlàáfíà.+ Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú gbogbo ìjọ àwọn ẹni mímọ́, 34  kí àwọn obìnrin máa dákẹ́+ nínú àwọn ìjọ, nítorí a kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n kí wọ́n wà ní ìtẹríba,+ àní gẹ́gẹ́ bí Òfin+ ti wí. 35  Bí ó bá wá jẹ́ pé wọ́n fẹ́ kọ́ nǹkan kan, kí wọ́n bi àwọn ọkọ tiwọn léèrè ní ilé, nítorí ohun ìtìjú+ ni kí obìnrin máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ. 36  Kínla? Ṣé láti ọ̀dọ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde wá ni,+ tàbí ọ̀dọ̀ yín nìkan ni ó dé? 37  Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ wòlíì tàbí pé òun ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, kí ó jẹ́wọ́ pé àwọn ohun tí mo ń kọ̀wé sí yín jẹ́ òtítọ́, nítorí àṣẹ Olúwa ni wọ́n.+ 38  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ aláìmọ̀kan, ó ń bá a lọ ní jíjẹ́ aláìmọ̀kan. 39  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa fi tìtara-tìtara wá ìsọtẹ́lẹ̀,+ síbẹ̀ kí ẹ má ṣe ka sísọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì+ léèwọ̀. 40  Ṣùgbọ́n kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé