Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 13:1-13

13  Bí mo bá ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n+ ènìyàn àti ti áńgẹ́lì ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, mo ti di abala idẹ kan tí ń dún tàbí aro aláriwo gooro.+  Bí mo bá sì ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀,+ tí mo sì di ojúlùmọ̀ gbogbo àṣírí ọlọ́wọ̀+ àti gbogbo ìmọ̀,+ bí mo bá sì ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè ńláńlá nípò padà,+ ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.+  Bí mo bá sì yọ̀ǹda gbogbo nǹkan ìní mi láti fi bọ́ àwọn ẹlòmíràn,+ tí mo sì fi ara mi léni lọ́wọ́,+ kí èmi bàa lè ṣògo, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́,+ èmi kò ní èrè rárá.  Ìfẹ́+ a máa ní ìpamọ́ra+ àti inú rere.+ Ìfẹ́ kì í jowú,+ kì í fọ́nnu,+ kì í wú fùkẹ̀,+  kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu,+ kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan,+ a kì í tán an ní sùúrù.+ Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.+  Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo,+ ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.+  A máa mú ohun gbogbo mọ́ra,+ a máa gba ohun gbogbo gbọ́,+ a máa retí ohun gbogbo,+ a máa fara da ohun gbogbo.+  Ìfẹ́ kì í kùnà láé.+ Ṣùgbọ́n yálà àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ wà, a óò mú wọn wá sí òpin; yálà àwọn ahọ́n àjèjì wà, wọn yóò ṣíwọ́; yálà ìmọ̀ wà, a óò mú un wá sí òpin.+  Nítorí àwa ní ìmọ̀ lápá kan,+ a sì ń sọ tẹ́lẹ̀ lápá kan;+ 10  ṣùgbọ́n nígbà tí èyíinì tí ó pé pérépéré bá dé,+ èyíinì tí ó jẹ́ ti apá kan ni a óò mú wá sí òpin. 11  Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin,+ mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó. 12  Nítorí pé nísinsìnyí àwa ń ríran nínú àwòrán fírífírí nípasẹ̀ dígí tí a fi irin ṣe,+ ṣùgbọ́n nígbà náà yóò jẹ́ ní ojúkojú.+ Nísinsìnyí, mo mọ̀ lápá kan, ṣùgbọ́n nígbà náà èmi yóò mọ̀ lọ́nà pípéye àní bí a ti mọ̀ mí lọ́nà pípéye.+ 13  Nísinsìnyí, bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àwọn mẹ́ta wọ̀nyí; ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé