Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kọ́ríńtì 12:1-31

12  Wàyí o, ní ti àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí,+ ẹ̀yin ará, èmi kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀.  Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ jẹ́ ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè,+ a ń ṣamọ̀nà yín lọ sọ́dọ̀ òrìṣà+ wọnnì tí kò lè fọhùn+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ pé a ṣamọ̀nà yín.  Nítorí náà, èmi yóò mú kí ẹ mọ̀ pé kò sí ẹnì kankan nígbà tí ó bá ń fi ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ tí ń wí pé: “Ẹni ègún ni Jésù!”+ kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè wí pé: “Jésù ni Olúwa!” bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+  Wàyí o, onírúurú ẹ̀bùn ní ń bẹ,+ ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan náà ni ó wà;+  onírúurú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ní ń bẹ,+ síbẹ̀ Olúwa kan náà ni ó wà;+  onírúurú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ sì ní ń bẹ,+ síbẹ̀ Ọlọ́run kan náà+ ni ẹni tí ń mú gbogbo ọ̀nà ìṣiṣẹ́ náà ṣe nínú gbogbo ènìyàn.+  Ṣùgbọ́n ìfihàn ẹ̀mí ni a fún olúkúlùkù fún ète tí ó ṣàǹfààní.+  Fún àpẹẹrẹ, a fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n+ fún ẹnì kan nípasẹ̀ ẹ̀mí, a fún òmíràn ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀+ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí kan náà ti fúnni,  a fún òmíràn ní ìgbàgbọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, a fún òmíràn ní àwọn ẹ̀bùn ìmúniláradá+ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan ṣoṣo náà, 10  síbẹ̀, a fún òmíràn ní ọ̀nà ìṣiṣẹ́ àwọn iṣẹ́ agbára,+ a fún òmíràn ní ìsọtẹ́lẹ̀,+ a fún òmíràn ní fífi òye mọ+ àwọn àsọjáde onímìísí,+ a fún òmíràn ní onírúurú ahọ́n àjèjì,+ a sì fún òmíràn ní ìtúmọ̀+ àwọn ahọ́n àjèjì. 11  Ṣùgbọ́n gbogbo ọ̀nà ìṣiṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀mí kan ṣoṣo náà ń mú ṣe,+ ó ń ṣe ìpínfúnni+ fún olúkúlùkù lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́.+ 12  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí ara ti jẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí ó ní ẹ̀yà ara púpọ̀, tí gbogbo ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara yẹn, bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀, sì jẹ́ ara kan ṣoṣo,+ bẹ́ẹ̀ náà ni Kristi.+ 13  Nítorí lóòótọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan ni a batisí+ gbogbo wa sínú ara kan ṣoṣo, yálà Júù tàbí Gíríìkì, yálà ẹrú tàbí òmìnira, a sì mú gbogbo wa mu+ ẹ̀mí kan. 14  Nítorí ara, ní tòótọ́, kì í ṣe ẹ̀yà ara kan ṣoṣo, bí kò ṣe púpọ̀.+ 15  Bí ẹsẹ̀ bá sọ pé: “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe apá kan ara,” kò tìtorí èyí ṣàìjẹ́ apá kan ara.+ 16  Àti bí etí bá sọ pé: “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” kò tìtorí èyí ṣàìjẹ́ apá kan ara.+ 17  Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, ibo ni agbára ìgbọ́ràn yóò wà? Bí gbogbo rẹ̀ bá jẹ́ ìgbọ́ràn, ibo ni ìgbóòórùn yóò wà? 18  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí Ọlọ́run ti gbé àwọn ẹ̀yà ara kalẹ̀ sínú ara, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wù ú.+ 19  Bí gbogbo wọ́n bá jẹ́ ẹ̀yà ara kan ṣoṣo,+ ibo ni ara yóò wà? 20  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ara púpọ̀,+ síbẹ̀ ara kan ṣoṣo. 21  Ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé: “Èmi kò nílò rẹ”; tàbí, ẹ̀wẹ̀, orí kò lè sọ fún ẹsẹ̀ pé: “Èmi kò nílò rẹ.” 22  Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, bí ọ̀ràn ti rí ni pé àwọn ẹ̀yà ara tí ó dà bí ẹni pé ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera+ jẹ́ kò-ṣeé-má-nìí, 23  àti àwọn apá kan ara tí a rò pé ó rẹlẹ̀ ní ọlá, ìwọ̀nyí ni a fi ọlá+ tí ó pọ̀ jù lọ yí ká, àti nípa bẹ́ẹ̀ àwọn apá kan ara wa aláìlẹ́wà ni ó ní ìdára rèǹtè-rente tí ó pọ jù lọ, 24  nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn apá kan ara wa dídára rèǹtè-rente kò nílò ohunkóhun. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run pá ara pọ̀ ṣọ̀kan, ní fífi ọlá tí ó pọ̀ jù lọ fún apá kan ara tí ó ṣaláìní, 25  kí ó má bàa sí ìpínyà kankan nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ lè ní aájò kan náà fún ara wọn.+ 26  Bí ẹ̀yà ara kan bá sì ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà;+ tàbí bí a bá ṣe ẹ̀yà ara kan lógo,+ gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a yọ̀.+ 27  Wàyí o, ara Kristi ni yín, àti àwọn ẹ̀yà ara lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.+ 28  Ọlọ́run sì ti gbé oníkálùkù kalẹ̀ nínú ìjọ,+ èkíní, àwọn àpọ́sítélì;+ èkejì, àwọn wòlíì;+ ẹ̀kẹta, àwọn olùkọ́;+ lẹ́yìn náà, àwọn iṣẹ́ agbára;+ lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀bùn ìmúniláradá;+ àwọn iṣẹ́ ìsìn tí ń ranni lọ́wọ́,+ àwọn agbára láti darí,+ onírúurú ahọ́n àjèjì.+ 29  Kì í ṣe gbogbo wọn ni àpọ́sítélì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wòlíì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni olùkọ́, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára, àbí gbogbo wọn ni? 30  Kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n ní àwọn ẹ̀bùn ìmúniláradá, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì,+ àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ olùtúmọ̀,+ àbí gbogbo wọn ni? 31  Ṣùgbọ́n ẹ máa fi tìtara-tìtara wá àwọn ẹ̀bùn títóbi jù.+ Síbẹ̀, èmi fi ọ̀nà títayọ ré kọjá hàn yín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé