Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kọ́ríńtì 11:1-34

11  Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.+  Wàyí o, mo gbóríyìn fún yín nítorí nínú ohun gbogbo ẹ ní mi lọ́kàn, ẹ sì ń di àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́+ mú ṣinṣin gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.  Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi;+ ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin;+ ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.+  Olúkúlùkù ọkùnrin tí ń gbàdúrà tàbí tí ń sọ tẹ́lẹ̀ tí ó ní ohun kan ní orí rẹ̀ dójú ti orí rẹ̀;+  ṣùgbọ́n olúkúlùkù obìnrin tí ń gbàdúrà tàbí tí ń sọ tẹ́lẹ̀+ láìbo orí rẹ̀ dójú ti orí rẹ̀,+ nítorí bákan náà ni ó rí pẹ̀lú bí ó bá jẹ́ obìnrin tí ó fárí.+  Nítorí bí obìnrin kò bá borí, kí ó gé irun rẹ̀ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ohun ìtìjú fún obìnrin láti gé irun tàbí kí ó fárí,+ kí ó borí.+  Nítorí kò yẹ kí ọkùnrin borí, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ àwòrán+ àti ògo+ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n obìnrin jẹ́ ògo ọkùnrin.+  Nítorí ọkùnrin kò ti ara obìnrin jáde, ṣùgbọ́n obìnrin ti ara ọkùnrin jáde;+  àti pé, jù bẹ́ẹ̀ lọ, a kò dá ọkùnrin nítorí obìnrin, ṣùgbọ́n obìnrin nítorí ọkùnrin.+ 10  Ìdí nìyẹn tí ó fi yẹ kí obìnrin ní àmì ọlá àṣẹ ní orí+ rẹ̀ nítorí àwọn áńgẹ́lì.+ 11  Yàtọ̀ sí èyí, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa, kò sí obìnrin láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọkùnrin láìsí obìnrin.+ 12  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí obìnrin ti ti ara ọkùnrin jáde,+ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọkùnrin tipasẹ̀ obìnrin wá;+ ṣùgbọ́n ohun gbogbo ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde.+ 13  Ẹ ṣèdájọ́ rẹ̀ fúnra yín: Ó ha yẹ kí obìnrin gbàdúrà sí Ọlọ́run láìborí? 14  Ìwà ẹ̀dá tìkára rẹ̀ kò ha kọ́ yín pé bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un; 15  ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígùn, ògo+ ni ó jẹ́ fún un? Nítorí irun rẹ̀ ni a fi fún un dípò ìwérí.+ 16  Àmọ́ ṣá o, bí ó bá dà bí ẹni pé ẹnikẹ́ni ń ṣe awuyewuye+ fún àṣà+ mìíràn kan, àwa kò ní òmíràn, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ Ọlọ́run kò ní. 17  Ṣùgbọ́n, bí mo ti ń fúnni ní ìtọ́ni wọ̀nyí, èmi kò gbóríyìn fún yín, nítorí ẹ kò pàdé pọ̀ fún dídára sí i, bí kò ṣe fún bíburú sí i.+ 18  Nítorí lákọ̀ọ́kọ́ ná, nígbà tí ẹ bá kóra jọpọ̀ nínú ìjọ, mo gbọ́ pé ìpínyà máa ń wà láàárín yín;+ mo sì gbà á gbọ́ dé ìwọ̀n kan. 19  Nítorí àwọn ẹ̀ya ìsìn+ gbọ́dọ̀ wà láàárín yín pẹ̀lú, kí àwọn tí a tẹ́wọ́ gbà pẹ̀lú lè fara hàn kedere láàárín yín.+ 20  Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá kóra jọpọ̀ sí ibì kan, kì í ṣeé ṣe láti jẹ oúnjẹ alẹ́ Olúwa.+ 21  Nítorí, nígbà tí ẹ bá ń jẹ ẹ́, olúkúlùkù ń jẹ oúnjẹ alẹ́ tirẹ̀ ṣáájú àkókò, tí ó fi jẹ́ pé ebi ń pa ọ̀kan ṣùgbọ́n ọtí ń pa òmíràn. 22  Dájúdájú, ẹ ní ilé fún jíjẹ àti mímu, àbí ẹ kò ní?+ Àbí ẹ ń tẹ́ńbẹ́lú ìjọ Ọlọ́run ni, tí ẹ sì ń dójú ti àwọn tí kò ní nǹkan kan?+ Kí ni èmi yóò sọ fún yín? Èmi yóò ha gbóríyìn fún yín bí? Nínú èyí, èmi kò gbóríyìn fún yín. 23  Nítorí lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti gba èyíinì tí èmi pẹ̀lú fi lé yín lọ́wọ́, pé Jésù Olúwa mú ìṣù búrẹ́dì ní òru+ tí a ó fi í léni lọ́wọ́, 24  àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó bù ú,+ ó sì wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ara+ mi tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí+ mi.” 25  Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ti ife+ náà pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ó ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó wí pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi.+ Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí+ mi.” 26  Nítorí nígbàkúùgbà+ tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ ń pòkìkí ikú+ Olúwa, títí yóò fi dé.+ 27  Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá jẹ ìṣù búrẹ́dì náà tàbí tí ó bá mu ife Olúwa láìyẹ yóò jẹ̀bi+ nípa ara àti ẹ̀jẹ̀+ Olúwa. 28  Lákọ̀ọ́kọ́, kí ènìyàn kan tẹ́wọ́ gba ara rẹ̀ lẹ́yìn ìyẹ̀wò fínnífínní,+ kí ó sì tipa báyìí jẹ nínú ìṣù búrẹ́dì náà, kí ó sì mu nínú ife náà. 29  Nítorí ẹni tí ó bá ń jẹ, tí ó sì ń mu, ó ń jẹ, ó sì ń mu ìdájọ́+ lòdì sí ara rẹ̀ bí kò bá fi òye mọ ara náà. 30  Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ láàárín yín fi jẹ́ aláìlera àti aláìsàn, tí àwọn púpọ̀ díẹ̀ sì ń sùn+ nínú ikú. 31  Ṣùgbọ́n bí àwa yóò bá fi òye mọ ohun tí àwa fúnra wa jẹ́, a kì yóò dá wa lẹ́jọ́.+ 32  Àmọ́ ṣá o, nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́,+ Jèhófà ni ó ń bá wa wí,+ kí a má bàa dá wa lẹ́bi+ pẹ̀lú ayé.+ 33  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá kóra jọpọ̀ láti jẹ ẹ́,+ ẹ dúró de ara yín. 34  Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun ní ilé,+ kí ẹ má bàa kóra jọpọ̀ fún ìdájọ́.+ Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀ràn yòókù ni èmi yóò mú tọ́ nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé