Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kọ́ríńtì 10:1-33

10  Wàyí o, èmi kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀, ẹ̀yin ará, pé gbogbo àwọn baba ńlá wa wà lábẹ́ àwọsánmà,+ gbogbo wọ́n sì gba inú òkun+ kọjá,  a sì batisí gbogbo wọn sínú Mósè+ nípasẹ̀ àwọsánmà àti òkun;  gbogbo wọ́n sì jẹ oúnjẹ ti ẹ̀mí+ kan náà,  gbogbo wọ́n sì mu ohun mímu ti ẹ̀mí+ kan náà. Nítorí wọ́n ti máa ń mu láti inú àpáta ràbàtà ti ẹ̀mí+ tí ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, àpáta ràbàtà+ yẹn sì túmọ̀ sí Kristi.+  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gbà+ púpọ̀ jù lọ nínú wọn, nítorí a ṣá wọn balẹ̀+ nínú aginjù.  Wàyí o, nǹkan wọ̀nyí di àpẹẹrẹ fún wa, kí àwa má bàa jẹ́ ẹni tí ń ní ìfẹ́-ọkàn sí àwọn ohun tí ń ṣeni léṣe,+ àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe ní ìfẹ́-ọkàn sí wọn.  Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe;+ gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.”+  Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣe ìwà hù, bí àwọn kan nínú wọ́n ti ṣe àgbèrè,+ kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+  Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe dán Jèhófà+ wò, bí àwọn kan nínú wọ́n ti dán an wò,+ kìkì láti ṣègbé nípasẹ̀ àwọn ejò.+ 10  Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe jẹ́ oníkùnsínú, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn kan nínú wọ́n ti kùn,+ kìkì láti ṣègbé láti ọwọ́ apanirun.+ 11  Wàyí o, nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀+ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan+ dé bá. 12  Nítorí náà, kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.+ 13  Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn.+ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́,+ kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra,+ ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde+ kí ẹ lè fara dà á. 14  Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ sá+ fún ìbọ̀rìṣà.+ 15  Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ẹni tí ń bá àwọn ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sọ̀rọ̀;+ ẹ fúnra yín ṣèdájọ́ ohun tí mo sọ. 16  Ife+ ìbùkún tí àwa ń súre sí, kì í ha ṣe àjọpín kan nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí? Ìṣù búrẹ́dì tí àwa ń bù,+ kì í ha ṣe àjọpín kan nínú ara Kristi bí?+ 17  Nítorí pé ìṣù búrẹ́dì kan ni ó wà, àwa, bí a tilẹ̀ pọ̀,+ jẹ́ ara kan,+ nítorí pé gbogbo wa ń ṣalábàápín ìṣù búrẹ́dì+ kan yẹn. 18  Ẹ wo èyíinì tí í ṣe Ísírẹ́lì nípa ti ara:+ Ǹjẹ́ àwọn tí ń jẹ àwọn ohun ẹbọ kì í ha ṣe alájọpín pẹ̀lú pẹpẹ?+ 19  Kí wá ni kí n sọ? Pé ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan ni bí, tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan ni bí?+ 20  Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n èmi wí pé àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ, wọ́n fi ń rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù,+ kì í sì í ṣe sí Ọlọ́run; èmi kò sì fẹ́ kí ẹ di alájọpín pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù.+ 21  Ẹ kò lè máa mu ife Jèhófà+ àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù; ẹ kò lè máa ṣalábàápín “tábìlì Jèhófà”+ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù. 22  Àbí “àwa ha ń ru Jèhófà lọ́kàn sókè sí owú ni bí”?+ Àwa kò lágbára jù+ ú lọ, àbí a ní in? 23  Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ṣàǹfààní.+ Ohun gbogbo ni ó bófin mu;+ ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró.+ 24  Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀,+ bí kò ṣe ti ẹnì kejì.+ 25  Ohun gbogbo tí a ń tà ní ọjà ẹran ni kí ẹ máa jẹ,+ láìṣe ìwádìí kankan ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín;+ 26  nítorí pé “ti Jèhófà+ ni ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ̀.”+ 27  Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ bá ké sí yín, tí ẹ sì fẹ́ láti lọ, ẹ tẹ̀ síwájú láti jẹ ohun gbogbo tí a bá gbé kalẹ̀ níwájú yín,+ láìṣe ìwádìí kankan ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín.+ 28  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá wí fún yín pé: “Èyí jẹ́ ohun kan tí a fi rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ ẹ́ ní tìtorí ẹni tí ó sọ ọ́ di mímọ̀ àti ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn.+ 29  “Ẹ̀rí-ọkàn,” ni mo wí, kì í ṣe tiyín, bí kò ṣe ti ẹnì kejì náà. Nítorí èé ṣe tí ó fi ní láti jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn+ ẹlòmíràn ní ń ṣèdájọ́ òmìnira mi? 30  Bí mo bá ń fi ọpẹ́ ṣalábàápín, èé ṣe tí a ó fi máa sọ̀rọ̀ mi tèébútèébú lórí èyíinì tí mo ti dúpẹ́ fún?+ 31  Nítorí náà, yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.+ 32  Ẹ máa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídi okùnfà ìkọ̀sẹ̀+ fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì pẹ̀lú àti fún ìjọ Ọlọ́run, 33  àní gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wu gbogbo ènìyàn nínú ohun gbogbo,+ láìmáa wá àǹfààní+ ti ara mi bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ ènìyàn, kí a bàa lè gbà wọ́n là.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé