Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kíróníkà 9:1-44

9  Ní ti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a kọrúkọ wọn sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé;+ ibẹ̀ sì ni a kọ wọ́n sí nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì. Júdà tìkára rẹ̀ ni a sì kó lọ sí ìgbèkùn+ ní Bábílónì nítorí ìwà àìṣòótọ́ wọn.  Àwọn olùgbé tí ó kọ́kọ́ wà lórí ohun ìní wọn nínú àwọn ìlú ńlá wọn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ àwọn àlùfáà,+ àwọn ọmọ Léfì+ àti àwọn Nétínímù.+  Jerúsálẹ́mù+ sì ni àwọn kan nínú àwọn ọmọ Júdà+ ń gbé àti àwọn kan nínú àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ àti àwọn kan nínú àwọn ọmọ Éfúráímù àti ti Mánásè:  Útáì ọmọkùnrin Ámíhúdù ọmọkùnrin Ómírì ọmọkùnrin Ímúrì ọmọkùnrin Bánì, lára àwọn ọmọ Pérésì+ ọmọkùnrin Júdà.+  Àti lára àwọn ọmọ Ṣílò,+ Ásáyà àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀.  Àti lára àwọn ọmọ Síírà,+ Júẹ́lì, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá tí ó jẹ́ àwọn arákùnrin wọn.  Àti lára àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì, Sáálù ọmọkùnrin Méṣúlámù ọmọkùnrin Hodafáyà ọmọkùnrin Hásénúà,  àti Ibineáyà ọmọkùnrin Jéróhámù, àti Éláhì ọmọkùnrin Úsáì ọmọkùnrin Míkírì, àti Méṣúlámù ọmọkùnrin Ṣẹfatáyà ọmọkùnrin Réúẹ́lì ọmọkùnrin Ibiníjà.  Àwọn arákùnrin wọn nípa àwọn ọmọ ìran wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn ọkùnrin tí í ṣe olórí àwọn baba nípa ilé àwọn baba ńlá wọn. 10  Àti lára àwọn àlùfáà ni Jedáyà àti Jèhóáríbù àti Jákínì,+ 11  àti Asaráyà+ ọmọkùnrin Hilikáyà ọmọkùnrin Méṣúlámù ọmọkùnrin Sádókù ọmọkùnrin Méráótì ọmọkùnrin Áhítúbù, aṣáájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, 12  àti Ádáyà ọmọkùnrin Jéróhámù ọmọkùnrin Páṣúrì ọmọkùnrin Málíkíjà, àti Máásáì ọmọkùnrin Ádíélì ọmọkùnrin Jásérà ọmọkùnrin Méṣúlámù ọmọkùnrin Méṣílẹ́mítì+ ọmọkùnrin Ímérì, 13  àti àwọn arákùnrin wọn, àwọn olórí ilé àwọn baba ńlá wọn, ọ̀tà-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, àwọn ọkùnrin alágbára ńlá tí wọ́n ní agbára+ láti ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́. 14  Àti lára àwọn ọmọ Léfì ni Ṣemáyà ọmọkùnrin Háṣúbù ọmọkùnrin Ásíríkámù ọmọkùnrin Haṣabáyà+ láti inú àwọn ọmọ Mérárì; 15  àti Bakibákárì, Héréṣì àti Gálálì, àti Matanáyà+ ọmọkùnrin Máíkà+ ọmọkùnrin Síkírì+ ọmọkùnrin Ásáfù,+ 16  àti Ọbadáyà ọmọkùnrin Ṣemáyà+ ọmọkùnrin Gálálì ọmọkùnrin Jédútúnì,+ àti Berekáyà ọmọkùnrin Ásà ọmọkùnrin Ẹlikénà, ẹni tí ń gbé ní àwọn ibi ìtẹ̀dó àwọn ará Nétófà.+ 17  Àwọn aṣọ́bodè+ sì ni Ṣálúmù+ àti Ákúbù àti Tálímónì àti Áhímánì, arákùnrin wọn Ṣálúmù sì ni olórí, 18  àti títí di ìgbà náà, ó wà ní ẹnubodè ọba+ níhà ìlà-oòrùn. Àwọn wọ̀nyí ni aṣọ́bodè àwọn ibùdó ọmọ Léfì.+ 19  Àti Ṣálúmù ọmọkùnrin Kórè ọmọkùnrin Ébíásáfù+ ọmọkùnrin+ Kórà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ti ilé baba rẹ̀ tí í ṣe àwọn ọmọ Kórà,+ lórí iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn náà, àwọn olùṣọ́nà+ àgọ́, àti àwọn baba wọn lórí ibùdó Jèhófà, àwọn olùṣọ́ ọ̀nà àbáwọlé. 20  Fíníhásì+ ọmọkùnrin Élíásárì+ sì ni aṣáájú wọn tẹ́lẹ̀ rí. Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 21  Sekaráyà+ ọmọkùnrin Meṣelemáyà ni aṣọ́bodè ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 22  Gbogbo wọn tí a yàn ṣe aṣọ́bodè ní àwọn ibi àbáwọlé jẹ́ igba ó lé méjìlá. Wọ́n wà ní ibi ìtẹ̀dó+ wọn nípa àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé.+ Àwọn wọ̀nyí ni Dáfídì+ àti Sámúẹ́lì aríran+ fàṣẹ yàn sí ipò iṣẹ́ ìfọkàntánni wọn.+ 23  Àwọn àti àwọn ọmọ wọn sì ni wọ́n ń bójú tó àwọn ẹnubòdè ilé Jèhófà, àní ilé àgọ́, fún iṣẹ́ ìsìn ìṣọ́.+ 24  Ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni àwọn aṣọ́bodè wà, níhà ìlà-oòrùn,+ níhà ìwọ̀-oòrùn,+ níhà àríwá+ àti níhà gúúsù.+ 25  Kí àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn sì máa wọlé wá fún ọjọ́ méje,+ láti ìgbà dé ìgbà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn wọ̀nyí. 26  Nítorí àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́rin ni wọ́n wà ní ipò iṣẹ́ ìfọkàntánni lára àwọn aṣọ́bodè. Wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, àwọn sì ni ó wà ní àbójútó àwọn yàrá ìjẹun+ àti àwọn ìṣúra+ ilé Ọlọ́run tòótọ́. 27  Gbogbo àyíká ilé Ọlọ́run tòótọ́ sì ni wọ́n máa ń wà ní òru; nítorí iṣẹ́ ìsìn ìṣọ́+ wà lórí wọn, wọ́n sì ń bójú tó kọ́kọ́rọ́, àní láti máa ṣílẹ̀kùn ní òròòwúrọ̀.+ 28  Àwọn kan lára wọ́n sì ń bójú tó àwọn nǹkan èlò+ iṣẹ́ ìsìn, nítorí ní iye-iye ni wọ́n fi ń kó wọn wọlé, ní iye-iye sì ni wọ́n fi ń kó wọn jáde. 29  Àwọn kan lára wọn sì jẹ́ àwọn tí a yàn sípò lórí àwọn nǹkan èlò àti lórí gbogbo àwọn nǹkan èlò mímọ́+ àti lórí ìyẹ̀fun kíkúnná+ àti wáìnì+ àti òróró+ àti oje igi tùràrí+ àti òróró básámù.+ 30  Àwọn kan lára àwọn ọmọ àlùfáà sì jẹ́ olùṣe àdàlù òróró ìkunra+ básámù. 31  Matitáyà láti inú àwọn ọmọ Léfì, ẹni tí í ṣe àkọ́bí Ṣálúmù+ ọmọ Kórà, sì ni ó wà ní ipò iṣẹ́ ìfọkàntánni lórí àwọn ohun tí a yan nínú páànù.+ 32  Àwọn kan láti inú àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Kóhátì, arákùnrin wọn, sì ni ó ń bójú tó búrẹ́dì onípele,+ láti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ ní sábáàtì kọ̀ọ̀kan.+ 33  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn akọrin,+ olórí baba àwọn ọmọ Léfì nínú àwọn yàrá ìjẹun,+ àwọn tí a yọ̀ǹda kúrò lẹ́nu iṣẹ́;+ nítorí pé tọ̀sán-tòru, ó jẹ́ ẹrù iṣẹ́ wọn láti wà lẹ́nu iṣẹ́ náà.+ 34  Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn baba àwọn ọmọ Léfì nípa àwọn ọmọ ìran wọn, àwọn onípò orí. Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù.+ 35  Gíbéónì+ sì ni ibi tí baba Gíbéónì, Jéélì, ń gbé. Orúkọ aya rẹ̀ sì ni Máákà. 36  Ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí, sì ni Ábídónì, àti Súúrì àti Kíṣì àti Báálì àti Nérì àti Nádábù, 37  àti Gédórì àti Áhíò àti Sekaráyà+ àti Míkílótì. 38  Ní ti Míkílótì, ó bí Ṣíméámù. Àwọn ní ti tòótọ́ sì ni wọ́n ń gbé ní iwájú àwọn arákùnrin wọn ní Jerúsálẹ́mù pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn. 39  Ní ti Nérì,+ ó bí Kíṣì;+ Kíṣì, ẹ̀wẹ̀, bí Sọ́ọ̀lù;+ Sọ́ọ̀lù, ẹ̀wẹ̀, bí Jónátánì+ àti Maliki-ṣúà+ àti Ábínádábù+ àti Eṣibáálì.+ 40  Ọmọkùnrin Jónátánì sì ni Meribu-báálì.+ Ní ti Meribu-báálì, ó bí Míkà.+ 41  Àwọn ọmọkùnrin Míkà sì ni Pítónì àti Mélékì àti Táréà àti Áhásì.+ 42  Ní ti Áhásì, ó bí Járà; Járà, ẹ̀wẹ̀, bí Álémétì àti Ásímáfẹ́tì àti Símírì. Símírì, ẹ̀wẹ̀, bí Mósà. 43  Ní ti Mósà, ó bí Bínéà àti Refáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Éléásà ọmọkùnrin rẹ̀, Ásélì ọmọkùnrin rẹ̀. 44  Ásélì sì ní ọmọkùnrin mẹ́fà, ìwọ̀nyí sì ni orúkọ wọn: Ásíríkámù, Bókérù àti Íṣímáẹ́lì àti Ṣearáyà àti Ọbadáyà àti Hánánì. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Ásélì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé