Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 8:1-40

8  Ní ti Bẹ́ńjámínì,+ ó bí Bélà+ àkọ́bí rẹ̀, Áṣíbélì+ ìkejì àti Áhárà+ ìkẹta,  Nóhà+ ìkẹrin àti Ráfà ìkarùn-ún.  Bélà sì wá ní àwọn ọmọkùnrin, Ádáárì àti Gérà+ àti Ábíhúdù,  àti Ábíṣúà àti Náámánì àti Áhóà,  àti Gérà àti Ṣéfúfánì+ àti Húrámù.+  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Éhúdù. Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn ilé baba ńlá tí ó jẹ́ ti àwọn olùgbé Gébà,+ wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní Mánáhátì.  Àti Náámánì àti Áhíjà; àti Gérà—òun ni ẹni tí ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn, ó sì bí Úúsà àti Áhíhúdù.  Ní ti Ṣáháráímù, ó bí àwọn ọmọ ní pápá+ Móábù lẹ́yìn tí ó rán wọn lọ. Húṣímù àti Báárà ni àwọn aya rẹ̀.  Àti pé nípasẹ̀ Hódéṣì aya rẹ̀, ó wá bí Jóbábù àti Síbíà àti Méṣà àti Málíkámù, 10  àti Jéúsì àti Sákíà àti Mírímà. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí ilé àwọn baba ńlá. 11  Nípasẹ̀ Húṣímù ó sì bí Ábítúbù àti Élípáálì. 12  Àwọn ọmọkùnrin Élípáálì sì ni Ébérì àti Míṣámù àti Ṣémédì, tí ó tẹ Ónò+ àti Lódì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ dó, 13  àti Bẹráyà àti Ṣémà. Àwọn wọ̀nyí ni olórí ilé àwọn baba ńlá, tí ó jẹ́ ti àwọn olùgbé Áíjálónì.+ Àwọn wọ̀nyí ni ó lé àwọn olùgbé Gátì lọ. 14  Áhíò sì ń bẹ, Ṣáṣákì àti Jérémótì, 15  àti Sebadáyà àti Árádì àti Édérì, 16  àti Máíkẹ́lì àti Íṣípà àti Jóhà, àwọn ọmọkùnrin Bẹráyà,+ 17  àti Sebadáyà àti Méṣúlámù àti Hísíkì àti Hébà, 18  àti Íṣíméráì àti Isiláyà àti Jóbábù, àwọn ọmọkùnrin Élípáálì, 19  àti Jákímù àti Síkírì àti Sábídì, 20  àti Élíénáì àti Sílétáì àti Élíélì, 21  àti Ádáyà àti Bẹráyà àti Ṣímúrátì, àwọn ọmọkùnrin Ṣíméì,+ 22  àti Íṣípánì àti Ébérì àti Élíélì, 23  àti Ábídónì àti Síkírì àti Hánánì, 24  àti Hananáyà àti Élámù àti Áńtótíjà, 25  àti Ifidéáyà àti Pénúélì, àwọn ọmọkùnrin Ṣáṣákì, 26  àti Ṣámúṣéráì àti Ṣẹharáyà àti Ataláyà, 27  àti Jaareṣáyà àti Èlíjà àti Síkírì, àwọn ọmọkùnrin Jéróhámù. 28  Àwọn wọ̀nyí ni àwọn olórí ilé àwọn baba ńlá nípa àwọn ọmọ ìran wọn, àwọn onípò orí. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù.+ 29  Gíbéónì sì ni ibi tí baba Gíbéónì,+ Jéélì, ń gbé, orúkọ aya rẹ̀ sì ni Máákà.+ 30  Ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí, sì ni Ábídónì, àti Súúrì àti Kíṣì àti Báálì àti Nádábù,+ 31  àti Gédórì àti Áhíò àti Sékà.+ 32  Ní ti Míkílótì, ó bí Ṣímẹ́à.+ Àwọn wọ̀nyí ní ti tòótọ́ sì ni wọ́n ń gbé ní iwájú àwọn arákùnrin wọn ní Jerúsálẹ́mù pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn. 33  Ní ti Nérì,+ ó bí Kíṣì;+ Kíṣì, ẹ̀wẹ̀, bí Sọ́ọ̀lù;+ Sọ́ọ̀lù, ẹ̀wẹ̀, bí Jónátánì+ àti Maliki-ṣúà+ àti Ábínádábù+ àti Eṣibáálì.+ 34  Ọmọkùnrin Jónátánì sì ni Meribu-báálì.+ Ní ti Meribu-báálì, ó bí Míkà.+ 35  Àwọn ọmọkùnrin Míkà sì ni Pítónì àti Mélékì àti Táréà+ àti Áhásì. 36  Ní ti Áhásì, ó bí Jẹ̀hóádà; Jẹ̀hóádà, ẹ̀wẹ̀, bí Álémétì àti Ásímáfẹ́tì àti Símírì. Símírì, ẹ̀wẹ̀, bí Mósà; 37  Mósà, ẹ̀wẹ̀, bí Bínéà, Ráfáhì+ ọmọkùnrin rẹ̀, Éléásà ọmọkùnrin rẹ̀, Ásélì ọmọkùnrin rẹ̀. 38  Ásélì sì ní ọmọkùnrin mẹ́fà, ìwọ̀nyí sì ni orúkọ wọn: Ásíríkámù, Bókérù àti Íṣímáẹ́lì àti Ṣearáyà àti Ọbadáyà àti Hánánì. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọkùnrin Ásélì. 39  Àwọn ọmọkùnrin Éṣékì arákùnrin rẹ̀ sì ni Úlámù àkọ́bí rẹ̀, Jéúṣì ìkejì àti Élífélétì ìkẹta. 40  Àwọn ọmọkùnrin Úlámù sì wá jẹ́ akíkanjú,+ alágbára ńlá ọkùnrin, àwọn tí ń fa ọrun,+ wọ́n sì ní ọ̀pọ̀ ọmọ+ àti àwọn ọmọ-ọmọ, àádọ́jọ. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ láti inú àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé