Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

1 Kíróníkà 7:1-40

7  Wàyí o, àwọn ọmọkùnrin Ísákárì ni Tólà+ àti Púà,+ Jáṣúbù àti Ṣímúrónì,+ mẹ́rin.  Àwọn ọmọkùnrin Tólà sì ni Úsáì àti Refáyà àti Jéríélì àti Jámáì àti Íbísámù àti Ṣẹ́múẹ́lì, olórí ilé àwọn baba ńlá wọn. Àwọn ti Tólà jẹ́ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin, nípa ọmọ ìran wọn. Iye wọn ní àwọn ọjọ́ Dáfídì+ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀tàlá.  Àwọn ọmọkùnrin Úsáì sì ni Isiráháyà; àwọn ọmọkùnrin Isiráháyà sì ni Máíkẹ́lì àti Ọbadáyà àti Jóẹ́lì, Isiṣáyà, , márùn-ún, gbogbo wọn jẹ́ olórí.  Àti pẹ̀lú wọn nípa àwọn ọmọ ìran wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba ńlá wọn, ni ọ̀wọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wà fún ogun, ẹgbàá méjìdínlógún, nítorí tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ aya àti ọmọ.+  Àwọn arákùnrin wọn ti gbogbo ìdílé Ísákárì sì jẹ́ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin,+ ọ̀kẹ́ mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin nípa àkọsílẹ̀ orúkọ gbogbo wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé.+  Àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì+ ni Bélà+ àti Békérì+ àti Jédáélì,+ mẹ́ta.  Àwọn ọmọkùnrin Bélà+ sì ni Ésíbónì àti Úsáì àti Úsíélì àti Jérímótì àti Íráì, márùn-ún, olórí ilé àwọn baba ńlá wọn, àwọn akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin; àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé+ sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n.  Àwọn ọmọkùnrin Békérì sì ni Sémírà àti Jóáṣì àti Élíésérì àti Élíóénáì àti Ómírì àti Jérémótì àti Ábíjà àti Ánátótì àti Álémétì, gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọmọkùnrin Békérì.  Àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé+ nípa àwọn ọmọ ìran wọn ní ti àwọn olórí ilé baba ńlá wọn, àwọn akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin, sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan lérúgba. 10  Àwọn ọmọkùnrin Jédáélì+ sì ni Bílíhánì; àwọn ọmọkùnrin Bílíhánì sì ni Jéúṣì àti Bẹ́ńjámínì àti Éhúdù àti Kénáánà àti Sẹ́tánì àti Táṣíṣì àti Áhíṣáhárì. 11  Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọkùnrin Jédáélì, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn olórí baba ńlá wọn, àwọn akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé igba tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun fún ogun. 12  Àwọn Ṣúpímù+ àti Húpímù+ sì ni ọmọ Írì;+ àwọn Húṣímù ni ọmọ Áhérì. 13  Àwọn ọmọkùnrin Náfútálì+ ni Jásíélì+ àti Gúnì+ àti Jésérì àti Ṣálúmù,+ àwọn ọmọkùnrin Bílíhà.+ 14  Àwọn ọmọkùnrin Mánásè+ ni Ásíríélì, ẹni tí wáhàrì rẹ̀ ará Síríà bí. (Ó bí Mákírù+ baba Gílíádì. 15  Mákírù fúnra rẹ̀ sì fẹ́ aya fún Húpímù àti fún Ṣúpímù, orúkọ arábìnrin rẹ̀ sì ni Máákà.) Orúkọ èkejì sì ni Sélóféhádì,+ ṣùgbọ́n Sélóféhádì wá ní àwọn ọmọbìnrin.+ 16  Nígbà tí ó ṣe, Máákà, aya Mákírù, bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Péréṣì; orúkọ arákùnrin rẹ̀ sì ni Ṣéréṣì; àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ni Úlámù àti Rékémù. 17  Àwọn ọmọkùnrin Úlámù sì ni Bédánì. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Gílíádì ọmọkùnrin Mákírù ọmọkùnrin Mánásè. 18  Arábìnrin rẹ̀ sì ni Hámólékétì. Ó bí Íṣíhódù àti Abi-ésérì+ àti Málà. 19  Àwọn ọmọkùnrin Ṣẹ́mídà sì wá jẹ́ Áhíánì àti Ṣékémù àti Líkíhì àti Áníámù. 20  Àwọn ọmọkùnrin Éfúráímù+ sì ni Ṣútélà+ àti Bérédì ọmọkùnrin rẹ̀ àti Táhátì ọmọkùnrin rẹ̀ àti Éléádà ọmọkùnrin rẹ̀ àti Táhátì ọmọkùnrin rẹ̀, 21  àti Sábádì ọmọkùnrin rẹ̀ àti Ṣútélà ọmọkùnrin rẹ̀ àti Ésérì àti Éléádì. Àwọn ọkùnrin Gátì+ tí a bí ní ilẹ̀ náà sì pa wọ́n nítorí pé wọ́n sọ̀ kalẹ̀ wá kó ohun ọ̀sìn wọn. 22  Éfúráímù baba wọ́n sì ń bá a lọ ní ṣíṣọ̀fọ̀ fún ọjọ́ púpọ̀,+ àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń wọlé wá láti tù ú nínú. 23  Lẹ́yìn ìgbà náà, ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀, tí ó fi wá lóyún,+ ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ṣùgbọ́n ó pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹráyà, nítorí ó ṣẹlẹ̀ pé pẹ̀lú ìyọnu àjálù+ ni obìnrin náà fi wà nínú ilé rẹ̀. 24  Ọmọbìnrin rẹ̀ sì ni Ṣéérà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ Bẹti-hórónì+ dó, ìsàlẹ̀+ àti òkè,+ àti Useni-ṣéérà. 25  Ọmọkùnrin rẹ̀ sì ni Réfà, àti Réṣéfù, àti Télà ọmọkùnrin rẹ̀, àti Táhánì ọmọkùnrin rẹ̀, 26  Ládánì ọmọkùnrin rẹ̀, Ámíhúdù ọmọkùnrin rẹ̀, Élíṣámà ọmọkùnrin rẹ̀, 27  Núnì+ ọmọkùnrin rẹ̀, Jèhóṣúà+ ọmọkùnrin rẹ̀. 28  Ohun ìní wọn àti àwọn ibi gbígbé wọn sì ni Bẹ́tẹ́lì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti, síhà ìlà-oòrùn, Nááránì+ àti, síhà ìwọ̀-oòrùn, Gésérì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àti Ṣékémù+ àti àwọn àrọko rẹ̀ títí lọ dé Gásà àti àwọn àrọko rẹ̀; 29  àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Mánásè, Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Mẹ́gídò+ àti àwọn àrọko rẹ̀, Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀. Inú ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jósẹ́fù+ ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ń gbé. 30  Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì+ ni Ímúnà+ àti Íṣífà àti Íṣífì+ àti Bẹráyà;+ Sérà sì ni arábìnrin wọn. 31  Àwọn ọmọkùnrin Bẹráyà sì ni Hébà àti Málíkíélì, ẹni tí í ṣe baba Bísáítì. 32  Ní ti Hébà, ó bí Jáfílétì àti Ṣómérì àti Hótámù, àti Ṣúà arábìnrin wọn. 33  Àwọn ọmọkùnrin Jáfílétì sì ni Pásákì àti Bímíhálì àti Áṣífátì. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọmọkùnrin Jáfílétì. 34  Àwọn ọmọkùnrin Ṣémérì sì ni Áhì àti Rógà, Jéhúbà àti Árámù. 35  Àwọn ọmọkùnrin Hélémù arákùnrin rẹ̀ sì ni Sófà àti Ímínà àti Ṣéléṣì àti Ámálì. 36  Àwọn ọmọkùnrin Sófà ni Súà àti Hánéfà àti Ṣúálì àti Bérì àti Ímúrà, 37  Bésérì àti Hódì àti Ṣáámà àti Ṣílíṣà àti Ítíránì àti Béérà. 38  Àwọn ọmọkùnrin Jétà sì ni Jéfúnè àti Písípà àti Árà. 39  Àwọn ọmọkùnrin Úlà sì ni Áráhì àti Háníélì àti Rísíà. 40  Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọkùnrin Áṣérì, àwọn olórí+ ilé àwọn baba ńlá, àwọn àṣàyàn ọkùnrin, akíkanjú,+ alágbára ńlá, àwọn olórí ìjòyè; àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé+ sì wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun nínú ogun. Iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlá ọkùnrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé