Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

1 Kíróníkà 6:1-81

6  Àwọn ọmọkùnrin Léfì+ ni Gẹ́ṣónì,+ Kóhátì+ àti Mérárì.+  Àwọn ọmọkùnrin Kóhátì sì ni Ámúrámù,+ Ísárì+ àti Hébúrónì+ àti Úsíélì.+  Àwọn ọmọkùnrin Ámúrámù+ sì ni Áárónì+ àti Mósè,+ Míríámù+ sì ń bẹ pẹ̀lú. Àwọn ọmọkùnrin Áárónì sì ni Nádábù+ àti Ábíhù,+ Élíásárì+ àti Ítámárì.+  Ní ti Élíásárì,+ ó bí Fíníhásì.+ Fíníhásì fúnra rẹ̀ bí Ábíṣúà.+  Ábíṣúà, ẹ̀wẹ̀, bí Búkì; Búkì, ẹ̀wẹ̀, bí Úsáì.+  Úsáì, ẹ̀wẹ̀, bí Seraháyà; Seraháyà, ẹ̀wẹ̀, bí Méráótì.+  Méráótì fúnra rẹ̀ bí Amaráyà; Amaráyà, ẹ̀wẹ̀, bí Áhítúbù.+  Áhítúbù, ẹ̀wẹ̀, bí Sádókù; Sádókù,+ ẹ̀wẹ̀, bí Áhímáásì.+  Áhímáásì, ẹ̀wẹ̀, bí Asaráyà. Asaráyà, ẹ̀wẹ̀, bí Jóhánánì. 10  Jóhánánì, ẹ̀wẹ̀, bí Asaráyà.+ Òun ni ẹni tí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ilé tí Sólómọ́nì kọ́ sí Jerúsálẹ́mù. 11  Asaráyà sì wá bí Amaráyà.+ Amaráyà, ẹ̀wẹ̀, bí Áhítúbù.+ 12  Áhítúbù, ẹ̀wẹ̀, bí Sádókù.+ Sádókù, ẹ̀wẹ̀, bí Ṣálúmù. 13  Ṣálúmù, ẹ̀wẹ̀, bí Hilikáyà. Hilikáyà,+ ẹ̀wẹ̀, bí Asaráyà. 14  Asaráyà, ẹ̀wẹ̀, bí Seráyà.+ Seráyà, ẹ̀wẹ̀, bí Jèhósádákì.+ 15  Jèhósádákì sì ni ó lọ nígbà tí Jèhófà kó Júdà àti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn nípa ọwọ́ Nebukadinésárì. 16  Àwọn ọmọkùnrin Léfì+ ni Gẹ́ṣómù, Kóhátì àti Mérárì. 17  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Gẹ́ṣómù: Líbínì+ àti Ṣíméì.+ 18  Àwọn ọmọkùnrin Kóhátì+ sì ni Ámúrámù+ àti Ísárì àti Hébúrónì àti Úsíélì.+ 19  Àwọn ọmọkùnrin Mérárì ni Máhílì àti Múṣì.+ Ìwọ̀nyí sì ni ìdílé àwọn ọmọ Léfì nípa àwọn baba ńlá wọn:+ 20  Ti Gẹ́ṣómù, Líbínì+ ọmọkùnrin rẹ̀, Jáhátì ọmọkùnrin rẹ̀, Símà ọmọkùnrin rẹ̀, 21  Jóà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Ídò ọmọkùnrin rẹ̀, Síírà ọmọkùnrin rẹ̀, Jéátéráì ọmọkùnrin rẹ̀. 22  Àwọn ọmọkùnrin Kóhátì ni Ámínádábù ọmọkùnrin rẹ̀, Kórà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Ásírì ọmọkùnrin rẹ̀, 23  Ẹlikénà ọmọkùnrin rẹ̀ àti Ébíásáfù+ ọmọkùnrin rẹ̀ àti Ásírì ọmọkùnrin rẹ̀; 24  Táhátì ọmọkùnrin rẹ̀, Úríélì ọmọkùnrin rẹ̀, Ùsáyà ọmọkùnrin rẹ̀, àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọkùnrin rẹ̀. 25  Àwọn ọmọkùnrin Ẹlikénà+ sì ni Ámásáì àti Áhímótì. 26  Ní ti Ẹlikénà, àwọn ọmọkùnrin Ẹlikénà ni Sófáì+ ọmọkùnrin rẹ̀ àti Náhátì ọmọkùnrin rẹ̀, 27  Élíábù+ ọmọkùnrin rẹ̀, Jéróhámù ọmọkùnrin rẹ̀, Ẹlikénà+ ọmọkùnrin rẹ̀. 28  Àwọn ọmọkùnrin Sámúẹ́lì+ sì ni Jóẹ́lì àkọ́bí àti èkejì Ábíjà.+ 29  Àwọn ọmọkùnrin Mérárì ni Máhílì,+ Líbínì ọmọkùnrin rẹ̀, Ṣíméì ọmọkùnrin rẹ̀, Úsà ọmọkùnrin rẹ̀, 30  Ṣíméà ọmọkùnrin rẹ̀, Hagáyà ọmọkùnrin rẹ̀, Ásáyà ọmọkùnrin rẹ̀. 31  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí Dáfídì+ fún ní ipò láti máa darí orin kíkọ ní ilé Jèhófà lẹ́yìn tí Àpótí ní ibi ìsinmi.+ 32  Wọ́n sì wá jẹ́ òjíṣẹ́+ nínú orin kíkọ+ níwájú àgọ́ ìjọsìn àgọ́ ìpàdé títí di ìgbà tí Sólómọ́nì kọ́ ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù;+ wọ́n sì ń bá a nìṣó ní bíbójútó iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí a gbé lé wọn lọ́wọ́.+ 33  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ àbójútó àti àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú: Láti inú àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Kóhátì, Hémánì+ akọrin, ọmọkùnrin Jóẹ́lì,+ ọmọkùnrin Sámúẹ́lì,+ 34  ọmọkùnrin Ẹlikénà,+ ọmọkùnrin Jéróhámù, ọmọkùnrin Élíélì,+ ọmọkùnrin Tóà, 35  ọmọkùnrin Súfì,+ ọmọkùnrin Ẹlikénà, ọmọkùnrin Máhátì, ọmọkùnrin Ámásáì, 36  ọmọkùnrin Ẹlikénà, ọmọkùnrin Jóẹ́lì, ọmọkùnrin Asaráyà, ọmọkùnrin Sefanáyà, 37  ọmọkùnrin Táhátì, ọmọkùnrin Ásírì, ọmọkùnrin Ébíásáfù,+ ọmọkùnrin Kórà,+ 38  ọmọkùnrin Ísárì,+ ọmọkùnrin Kóhátì, ọmọkùnrin Léfì, ọmọkùnrin Ísírẹ́lì. 39  Ní ti arákùnrin rẹ̀ Ásáfù,+ tí ń ṣe ìránṣẹ́ ní ọ̀tún rẹ̀, Ásáfù jẹ́ ọmọkùnrin Berekáyà,+ ọmọkùnrin Ṣíméà, 40  ọmọkùnrin Máíkẹ́lì, ọmọkùnrin Baaseáyà, ọmọkùnrin Málíkíjà, 41  ọmọkùnrin Étínì, ọmọkùnrin Síírà, ọmọkùnrin Ádáyà, 42  ọmọkùnrin Étánì, ọmọkùnrin Símà, ọmọkùnrin Ṣíméì, 43  ọmọkùnrin Jáhátì,+ ọmọkùnrin Gẹ́ṣómù,+ ọmọkùnrin Léfì. 44  Ní ti àwọn ọmọ Mérárì,+ àwọn arákùnrin wọn ní ọwọ́ òsì, àwọn ni Étánì+ ọmọkùnrin Kííṣì,+ ọmọkùnrin Ábídì, ọmọkùnrin Málúkù, 45  ọmọkùnrin Haṣabáyà, ọmọkùnrin Amasááyà, ọmọkùnrin Hilikáyà, 46  ọmọkùnrin Ámísì, ọmọkùnrin Bánì, ọmọkùnrin Ṣémérì, 47  ọmọkùnrin Máhílì, ọmọkùnrin Múṣì,+ ọmọkùnrin Mérárì,+ ọmọkùnrin Léfì. 48  Àwọn arákùnrin wọn ọmọ Léfì+ sì ni àwọn tí a fi fúnni fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn+ àgọ́ ìjọsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́. 49  Áárónì+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì ń rú èéfín ẹbọ+ lórí pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun+ àti lórí pẹpẹ tùràrí+ fún gbogbo iṣẹ́ àwọn ohun mímọ́ jù lọ àti láti ṣe ètùtù+ fún Ísírẹ́lì,+ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ. 50  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Áárónì:+ Élíásárì+ ọmọkùnrin rẹ̀, Fíníhásì+ ọmọkùnrin rẹ̀, Ábíṣúà+ ọmọkùnrin rẹ̀, 51  Búkì ọmọkùnrin rẹ̀, Úsáì ọmọkùnrin rẹ̀, Seraháyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, 52  Méráótì+ ọmọkùnrin rẹ̀, Amaráyà ọmọkùnrin rẹ̀, Áhítúbù+ ọmọkùnrin rẹ̀, 53  Sádókù+ ọmọkùnrin rẹ̀, Áhímáásì+ ọmọkùnrin rẹ̀. 54  Ìwọ̀nyí sì ni ibi gbígbé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ibùdó wọn tí a mọ ògiri yí ká ní ìpínlẹ̀ wọn,+ fún àwọn ọmọ Áárónì tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì,+ nítorí ìpín náà ti wá jẹ́ tiwọn. 55  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n fún wọn ní Hébúrónì+ ní ilẹ̀ Júdà, pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ tí ó wà ní gbogbo àyíká rẹ̀. 56  Pápá ìlú ńlá náà àti àwọn ibi ìtẹ̀dó rẹ̀+ ni wọ́n sì fi fún Kálébù+ ọmọkùnrin Jéfúnè.+ 57  Àwọn ọmọ Áárónì ni wọ́n sì fún ní àwọn ìlú ńlá ìsádi,+ Hébúrónì,+ àti Líbínà+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Játírì+ àti Éṣítémóà+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 58  àti Hílénì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Débírì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 59  àti Áṣánì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; 60  àti láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Gébà+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Álémétì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Ánátótì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀. Gbogbo ìlú ńlá wọn jẹ́ ìlú ńlá mẹ́tàlá+ láàárín àwọn ìdílé wọn. 61  Àwọn ọmọ Kóhátì tí ó ṣẹ́ kù nínú ìdílé ẹ̀yà náà ni wọ́n sì fún ní ìlú ńlá mẹ́wàá+ nípa kèké láti inú ààbọ̀ ẹ̀yà náà, ààbọ̀ Mánásè. 62  Àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù+ nípa ìdílé wọn ni wọ́n sì fún ní ìlú ńlá mẹ́tàlá láti inú ẹ̀yà Ísákárì+ àti láti inú ẹ̀yà Áṣérì+ àti láti inú ẹ̀yà Náfútálì+ àti láti inú ẹ̀yà Mánásè+ ní Báṣánì. 63  Àwọn ọmọ Mérárì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni wọ́n fún ní ìlú ńlá méjìlá nípa kèké láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì+ àti láti inú ẹ̀yà Gádì+ àti láti inú ẹ̀yà Sébúlúnì.+ 64  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tipa báyìí fún àwọn ọmọ Léfì+ ní àwọn ìlú ńlá pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko wọn.+ 65  Síwájú sí i, wọ́n fúnni ní ìlú ńlá wọ̀nyí nípa kèké, èyí tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pè ní orúkọ, láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Júdà+ àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì+ àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì.+ 66  Àwọn kan nínú àwọn ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì sì wá ní àwọn ìlú ńlá tí ó jẹ́ ìpínlẹ̀ wọn láti inú ẹ̀yà Éfúráímù.+ 67  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú ńlá ìsádi, Ṣékémù+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Éfúráímù, àti Gésérì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 68  àti Jókíméámù+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Bẹti-hórónì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 69  àti Áíjálónì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Gati-rímónì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; 70  àti láti inú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, Ánérì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Bíléámù+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, fún ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì tí ó ṣẹ́ kù.+ 71  Àwọn ọmọ Gẹ́ṣómù+ ni wọ́n sì fi Gólánì+ ní Báṣánì pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Áṣítárótì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ fún láti inú ìdílé ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè; 72  àti láti inú ẹ̀yà Ísákárì, Kédéṣì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Dábérátì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 73  àti Rámótì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Ánémù+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; 74  àti láti inú ẹ̀yà Áṣérì, Máṣálì pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Ábídónì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 75  àti Húkọ́kù+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Réhóbù+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; 76  àti láti inú ẹ̀yà Náfútálì,+ Kédéṣì+ ní Gálílì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Hámónì pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Kíríátáímù+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀. 77  Àwọn ọmọ Mérárì tí ó ṣẹ́ kù láti inú ẹ̀yà Sébúlúnì+ ni wọ́n fún ní Rímónò+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Tábórì pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 78  àti ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò síhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì, láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì,+ Bésérì+ ní aginjù pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Jáhásì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 79  àti Kédémótì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Mẹ́fáátì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; 80  àti láti inú ẹ̀yà Gádì,+ Rámótì+ ní Gílíádì pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Máhánáímù+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 81  àti Hẹ́ṣíbónì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti Jásérì+ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé